Iléẹjọ́ gba ẹ̀rí fọ́nrán 'Radio Biafra' wọlé tako Kanu, àwọn agbẹjọ́rò rẹ̀ takú pé ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ lòdì sófin

Aworan Nnamdi Kanu
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ileẹjọ giga ijọba apapọ niluu Abuja ti gba ẹri fọnran mẹta ti ọkan lara wọn ṣafihan bi olori ẹgbẹ IPOB, Nnamdi Kanu, ṣe n ṣayẹwo irinṣẹ igbohusafẹfẹ ileeṣẹ redio ti wọn fẹsun kan an pe o ko wọ Naijiria lọna aitọ.

Eyi jẹ nnkan pataki to ṣẹlẹ nibi igbẹjọ Kanu lori ẹsun igbesunmọmi ti ijọba fi kan an.

Irinṣẹ igbohusafẹfẹ ileeṣẹ redio naa, ''Tram 50L,'' ni a gbọ pe o wa ni ilu Ubuluisiuzor nijọba ibilẹ Ihiala nipinlẹ Anambra nibi ti wọn ni Kanu ti ṣayẹwo irinṣẹ naa.

DSS ni irọ ni Kanu pa pe DSS dunkoko mọ oun lati jẹwọọ nnkan ti oun ko ṣe

Ẹlerii kẹta ti wọn pe orukọ rẹ ni Ọgbeni CCC, to jẹ oṣiṣẹ ajọ DSS sọ fun ile ẹjọ wi pe irọ to jinna si ootọ ni ọrọ ti Kanu sọ pe DSS dunkoko mọ oun lati jẹwọọ nnkan toun o ṣe.‎‎

Ẹlẹrii tun sọ fun ile ẹjọ wi pe orukọ awọn oṣiṣẹ DSS to ṣe ifọrọwanilẹnuwo pẹlu Kanu ni Ọgbẹni James, Ọgbẹni Ibrahim ati Ọgbẹni Collins.

Ẹlẹrii kẹta fidi rẹ mulẹ pe ajọ DSS tọju Kanu daadaa lasiko to wa lakata wọn, o ni ko si ohun to jọ wi pe wọn fipa mu un lati jẹwọ nnkan ti ko ṣe.

Ohun ti a gbọ ni pe Kanu ni ajọ DSS lo fipa moun lati pe Aarẹ tẹrẹri Goodluck Jonothan ati Muhammadu Buhari ni orukọ ti ko ṣe e gbọ leti, ti o si tun ni Sẹnẹtọ Rochas Okorocha lo sọ awọn eeyan rẹ di musulumi.

Ẹlẹrii ajọ DSS fikun ọrọ rẹ pe lasiko ifọrọwanilẹnu ti Kanu ṣe lo ti pe orilẹede Naijiria ni ọgba ẹranko.

Akọsilẹ awọn ọrọ yii ati awọn fọnran ọrọ ti Kanu ni wọn ko wa siwaju ile ẹjọ gẹgẹ bii ẹri.

Adajọ James Omotosho sọ ninu ọrọ rẹ wi pe ohun ti ofin sọ pe ti olujẹjọ ba fẹsun kan awọn olupẹjọ wi pe wọn fipa mu oun lati jẹwọ nnkan toun ko ṣe, ile ẹjọ gbọdọ fidi rẹ mulẹ bo ya loootọ ni ọrọ naa tabi ko ri bẹẹ.

Lori ẹri fọnran mẹta ti igbimọ olupẹjọ ko wa si ile ẹjọ, Kanu gba wi pe oun loun ṣe idasilẹ Redio Biafra.

Kanu sọ ninu ọkan lara awọn fidio naa wi pe ọpọ eeyan to gbagbo ninu ki ẹya Igbo ni orilẹede Biafra lo n ṣeranwọ owo fun ileeṣẹ redio Biafra.

‎‎Lẹyin o rẹyin, Adajọ Omotosho, sun igbẹjọ si Ọjọbọ ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Karun un yii.

Igbẹjọ Nnamdi Kanu lodin sofin Naijiria ati ofin agbaye – Agbẹjọro Kanu

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Igbimọ agbọjọro to n ṣoju Kanu nile ẹjọ ti sọ pe igbẹjọ olori ẹgbẹ IPOB to n lọ lọwọ ko lẹsẹ nlẹ, bakan naa ni o lodi si ofin Naijiria ati ofin agbaye.

Ninu atẹjade to Onyekachi Ifedi buwọlu lorukọ igbimọ ẹgbẹ IPOB to n ri si ọrọ, awọn agbẹjọro naa sọ pe bi igbẹjọ ọhun ṣe n waye niwaju Adajọ Omosho ko bofin mu rara.

Igbimọ olujẹjọ Kanu sọ pe ẹka 76(1) ofin to da lori igbesunmọmi ọdun 2022 fidi rẹ mulẹ pe ẹnikẹni ti wọn ba fẹsun igbesunmọmi kan ko le jẹjọ lori ẹsun naa, ayafi ti igbẹjọ rẹ ba ti kọkọ waye ni orilẹede ilẹ okeere ti wọn ti mu un wale loku.

Awọn agbẹjọro Kanu ni igbẹjọ igbesumọmi rẹ ko tii waye ni Kenya ti wọn ti gbe e wa si Naijiria, eyi to tumọ si pe igbẹjọ to n waye ni Naijiria bayii lodi sofin.

Igbimọ olujẹjọ Kanu tun sọ pe bi wọn ṣe gbe Kanu pada si Naijiria lati orilẹede Kenya gan an lodi sofin.

Awọn agbẹjọro Kanu tun sọ pe ẹka 45 ofin ile ẹjọ giga ijọba apapọ fidi rẹ mulẹ pe igbẹjọ ẹsun igbesunmọmi gbọdọ waye nibi ti ẹni ti wọn ba fẹsun kan ti ṣẹ.

Wọn ni orilẹede UK ati Kenya ti ijọba apapọ sọ pe ẹsun igbesunmọmi ti wọn fi kan Kanu ti waye.

Igbimọ agbẹjọro Kanu sọ pe ko yẹ ki igbẹjọ naa ko maa waye niluu Abuja rara labẹ ofin.

Awọn agbẹjọro naa wa kepe ijọba apapọ lati fopin si igbẹjọ naa tori o lodi sofin.

Wọn ni oju ti ko sunwọn lawọn amofin yoo fi maa wo orilẹede Naijiria ti ijọba ko ba fopin si igbẹjọ naa niluu Abuja.