WAEC tọrọ àforíjìn lórí báwọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣe kọ ìdánwò nínú òkùnkùn, ilé aṣojú-ṣòfin ké sí WAEC láti sọ tẹnu rẹ̀

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń kọ ìdánwò nínú òkùnkùn

Oríṣun àwòrán, screenshot

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Ajọ WAEC ti tọrọ aforijin lọwọ awọn obi ati akẹkọọ lori bi wọn kuna lati tete bẹrẹ idanwo asejade, paapa ti ede Gẹẹsi lọjọ kejindinlọgbọn oṣu karun un ọdun 2025.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ajọ naa, Moyosola Adesina fi lede fawọn akọrinyin, o ni ajọ naa gba pe asise wa lati ọwọ wọn lasiko naa.

WAEC ṣalaye pe igbiyanju lati dabo bo idanwo naa ko mase lu sita fun awọn akẹkọọ naa lo ṣokunfa eyi.

"Pẹlu gbogbo igbiyanju wa, a koju awọn kudiẹkudiẹ kan to fẹ da gbogbo ohun ti a peelo nu.

Lati ma jẹ ke eyi waye, a ti n sisẹ pọ pẹlu awọn agbofinro lati ri pe eyi ko waye.

"A mọ pataki mimu adehun sẹ nipa idanwo ati pe igbesẹ wa yii mu inilara bawọn akẹkọọ, ile ẹkọ ati awọn obi, a tọrọ aforijin fun gbogbo inira ti a mu wa."

Wayi o, igbimọ to n risi eto ẹkọ alabọde ati idanwo sise nile igbimọ aṣoju-ṣofin orilẹede Naijiria, ti ke si ajọ WAEC lati yọju siwaju oun.

Igbimọ naa ni WAEC gbọdọ wa dahun ibeere to jẹmọ ohun to ṣokunfa bi idanwo to yẹ ko bẹrẹ lago mẹsan an owurọ, ṣe bẹrẹ ni ago mẹta abọ lọsan.

Igbimọ naa ni ki WAEC yọju si ile igbimọ aṣofin ni Ọjọ Ẹti, Ọgbọnjọ oṣu Karun un ọdun 2025.

Bẹẹ ba gbagbe, Ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹrin ni idanwo WAEC ti bẹrẹ, ti yoo si pari ni ni Ogunjọ oṣu kẹfa ọdun 2025.

Idanwo Ede Gẹẹsi ni o yẹ ki awọn akẹkọọ ṣe ni Ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Karun un, ti idaduro ti a ko le sọ ohun pato to fa, si waye.

Ọpọ awọn akẹkọọ kaakiri orilẹede Naijiria si ni lati duro fun ọpọ wakati ki wọn to bẹrẹ idanwo naa.

Oboku Abonsizibe Oforji, alaga ẹka ile igbimọ aṣofin-sofin fun WAEC ni wakati mẹrinleogun lati wa wi tẹnu wọn lori ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ yii.

Oforji ni awọn fẹ ki WAEC wa ṣalaye ohun to ṣẹlẹ ni pato lasiko idanwo ọhun.

O tẹsiwaju pe ohun itiju gba ni iṣẹlẹ ati ti oun ko si nifẹẹ si bi WAEC ṣe kọ lati farahan lasiko ti ile igbimọ aṣofin kọkọ ransẹ pe wọn lori ọrọ idanwo naa.

"Ohun to yẹlẹ yii ni ko bojumu rara, a gba ipe pe awọn akẹkọọ n ṣe idanwo ni ooru ọganjọ ni awọn apa ibikan lorilẹede Naijiria."

Ajọ WAEC tọrọ aforijin lori bi idanwo ṣe pẹ ko to bẹrẹ

"Aago mẹ́ta àbọ̀ ọ̀sán la bẹ̀rẹ̀ ìdánwò tó yẹ ká bẹ̀rẹ̀ láago mẹ́sàn-án àárọ̀, ọ̀pọ̀ wa ló ti rẹ̀ sára, a kò tún parí ìdanwò wa"

Ní alẹ́ ọjọ́rú, ọjọ́ Kejìdínlọ́gbọ̀n, oṣù Karùn-ún, ọdún 2025 ni ariwo bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ lórí ayélujára pàápàá lórí ìkànnì X fún bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń ṣe ìdánwò WAEC lọ́wọ́ ṣe ṣe ìdánwò náà nínú òkùnkùn.

Aago mẹ́jọ ààbọ̀ òwúrọ̀ ló yẹ kí ìdánwò èdè Gẹ̀ẹ́sì, táwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ní lọ́jọ́rú, yẹ kó bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àtẹ ètò ìdánwò tí WAEC gbé jáde ṣe sọ àmọ́ ìdánwò náà kò bẹ̀rẹ̀ ní àkókò náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpínlẹ̀ káàkiri Nàìjíríà.

Ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́, Mistura Tunrayo, tó ṣe ìdánwò rẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ girama Oke-Oyi Community Secondary School, ìpínlẹ̀ Kwara bá BBC News Yoruba sọ̀rọ̀ nípa ìdánwò náà.

Mistura ní pé aago mẹ́sàn-án òwúrọ̀ ló yẹ kí ìdánwò náà bẹ̀rẹ̀ ṣùgbọ́n ó tó aago mẹ́ta ọ̀sán káwọn tó bẹ̀rẹ̀.

O salaye pé ọ̀pọ̀ àwọn ni àwọn ti wà ní ilé ẹ̀kọ́, táwọn ti jòkòó ní yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ìdánwò àmọ́ tí wọn kò gbé ìwé tí àwọn fi máa ṣe ìdánwò wá fáwọn.

"Àwọn olùkọ́ tó dúró ti wà ló ń kánjú nígbà tí ọjọ́ ti lọ, tí wọn kò sì fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ míì láàyè láti parí ìdánwò wọn, tí wọn fi gba ìwé lọ́wọ́ wọn"

Mistura Tunrayo tẹ̀síwájú pé nígbà tí àwọn ti jòkòó fún ọ̀pọ̀ wákàtí ni àwọn olùkọ́ sọ fáwọn pé láti ọ́fíìsì WAEC ni ìdádúrò náà ti wáyé.

"Nígbà tó di nǹkan bíi aago méjì a ò tún rí wọn, ìgbà tó ti bíi aago mẹ́ta ń lọ lù ni wọ́n tó gbé ìwé ìdánwò dé.

"Aago mẹ́ta ni a bẹ̀rẹ̀ ìdánwò. Essay ni a kọ́kọ́ ṣe, lẹ́yìn náà ni a ṣe "oral", tí a sì ṣe "objectives" ní ìparí. Nǹkan bíi aago mẹ́fà àbọ̀ ìrọ̀lẹ́ ni a parí."

Mistura sọ pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣàkóbá fún ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ nítorí ọ̀pọ̀ àwọn ló ti rẹ̀ sára kó tó di pé ìdánwò náà bẹ̀rẹ̀ rárá.

Bákan náà ló fi kun pé àwọn olùkọ́ tó dúró ti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ni wọ́n ń kánjú nígbà tí ọjọ́ ti lọ tí wọn kò sì fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ míì láàyè láti parí ìdánwò wọn tí wọn fi gba ìwé lọ́wọ́ wọn.

Gẹ́gẹ́ bí àtẹ ètò ìdánwò tí WAEC fi síta, wákàtí mẹ́ta àti ìṣẹ́jú márùndínláàádọ́ta ló yẹ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fi ṣe ìdánwò náà.

A ò mọ ohun tó mú kí ìwé ìdánwò pẹ́ kó tó dé, a ò tíì gbọ́ nńkankan láti WAEC - Olùkọ́

Ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ Oke-Oyi Community Secondary School, Salami Yusuf sọ pé títí di òwúrọ̀ ọjọ́bọ̀ tí òun ń bá BBC News Yorùbá sọ̀rọ̀, àwọn kò ì tíì mọ ìdí tàbí gbọ́ nǹkankan láti àjọ WAEC lórí ìdí tí ìdánwò náà fi pẹ́.

Ó ní nǹkan bíi aago mẹ́sàn-án àbọ̀ òwúrọ̀ ọjọ́rú tó yẹ kí ìdánwò náà bẹ̀rẹ̀ ni wọ́n sọ fún àwọn pé ìweé ìdánwò máa tó aago mẹ́wàá àbọ̀ kó tó dé.

"A jókòó sínú yàrá tí ìdánwò ti máa wáyé fún wákàtí méjì, mẹ́ta tí à ń rétí ìwé ìdánwò àmọ́ tí kò dé.

"Nǹkan bíi aago kan àbọ̀ ni wọ́n tó gbé ìbéèrè tí a sì bẹ̀rẹ̀ ìdánwò nígbà náà.

"Ohun tí mo ṣàkíyèsí ni pé aago mẹ́fà àbọ̀ tí àwa ń parí ìdánwò ni àwọn ilé ẹ̀kọ́ míì ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bẹ̀rẹ̀, ìdánwò náà kò lọ lásìkò kan náà bó ṣe máa ń rí tẹ́lẹ̀.

"Títí di àsìkò yìí, a ò tíì gbọ́ ohunkóhun láti WAEC ìdí tí ọ̀rọ̀ fi rí báyìí."

Àkọlé fídíò, “Kò sí ẹni tó mọ bí bàbá mi, Remilekun Amos, ṣe di àwátì, àhesọ lásán ni pé ó jóná mọ́ inú ọkọ̀ tàbí pé wọ́n fi ṣe ètùtù ni”
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń ṣe ìdánwò nínú òkùnkùn

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kọ ìdánwò WAEC, tó yẹ kó bẹ̀rẹ̀ ní aago mẹ́jọ àbọ̀ àárọ̀, nínú òkùnkùn, ariwo sọ

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Saájú la ti mú ìròyìn wá fún yín pé ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún àwọn èèyàn nígbà tí wọ́n rí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ girama tí wọ́n ń ṣe ìdánwò àṣekágbá ìyẹn 2025 West African Secondary Schools Certificate Examination (WASSCE) èyí tó ń lọ lọ́wọ́ nínú òkùnkùn.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó wà lọ́wọ́, ìdánwò èdè Gẹ̀ẹ́sì ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe nínú òkùnkùn lọ́jọ́rú.

Ohun tí a gbọ́ ni pé nǹkan bíi aago mẹ́rin ìrọ̀lẹ́ sí aago méje ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bẹ̀rẹ̀ ìdánwò náà tí wọ́n sì parí ní nǹkan bíi aago méje sí aago mẹ́sàn-án alẹ́.

Àwọn kan ń sọ pé àwọn ìbéèrè náà lu síta ṣáájú ìgbà tó yẹ kí ìdánwò náà bẹ̀rẹ̀ ló ṣokùnfà ìdí tí ìdánwò ọ̀hún fi pẹ́ bẹ̀rẹ̀ àmọ́ a ò le fìdí èyí múlẹ̀.

Ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ló ṣe ìdánwò wọn nínú òkùnkùn látàrí àìsí iná ọba láwọn ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti ń ṣe ìdánwò náà.

Iná fóònù àti àtùpà ni wọ́n tàn fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ láwọn ibùdó ìdánwò náà.

Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn lórí ìkànnì X ló ti ń bu ẹnu àtẹ́ lu àjọ tó ń rí sí ètò ìdánwò WAEC ní Nàìjíríà fún bí wọ́n ṣe fi ìdánwò náà sí alẹ́ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́.

Ohun tí wọ́n ń sọ ni pé kò yẹ kí àjọ náà fi ìdánwò ọ̀hún sí alẹ́ rárá nítorí àwọn ọmọ tí wọ́n ń ṣe ìdánwò náà ni ọjọ́ orí wọn kéré àti pé ètò ààbò orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti mẹ́hẹ kọjá irú ìgbésẹ̀ báyìí.

"Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní Nàìjíríà ń ṣe ìdánwò lọ́wọ́ lábẹ́ ètò tí kò dára rárá. Lónìí, tí wọ́n ní ìdánwò èdè Gẹ̀ẹ́sì tó bẹ̀rẹ̀ ní aago mẹ́jọ alẹ́ ni wọ́n ń ṣe lọ́wọ́. Wọ́n ní káwọn akẹ́kọ̀ọ́ mú àtùpà lọ́wọ́ láti ṣe ìdánwò. Ìdánwò náà ṣì ń lọ lọ́wọ́ ní aago mẹ́sàn-án àbọ̀ alẹ́."

"Ó ṣeni láàánú pé àbúrò mi ṣẹ̀ṣẹ̀ ń wọlé ní aago mẹ́sàn-án ku ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún láti ibi tó ti lọ ṣe ìdánwò èdè Gẹ̀ẹ́sì WAEC. Ó ní ó pẹ́ kí ìdánwò náà tó bẹ̀rẹ̀ àti pé torchlight ni òun lò láti fi parí ìdánwò náà. Ṣé kìí ṣe ohun ìdójútì pé WAEC kò ní ẹ̀rí ọkàn àti pé wọ́n ò létò rárá?

Ẹ̀gbọ́n akẹ́kọ̀ọ́ kan ní agbègbè Adewole ní ìlú Ilorin sọ fún àwọn akọ̀ròyìn pé ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún òun nígbà tí òun bá àwọn àbúrò òun níbi tí wọ́n ti ń ṣe ìdánwò ní aago méje ìrọ̀lẹ́.

Ó ní inú òkùnkùn ni ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ti ń kọ ìdánwò, tó sì jẹ́ pé iná ara fóònù ni ọ̀pọ̀ wọn fí ń ṣiṣẹ́.

"Mo dé ilé ẹ̀kọ́, mo bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń fi iná fóònù kọ ìdánwò. Kò sí iná mọ̀nàmọ́ná tó mọ́lẹ̀ dáadáa fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà láti fi ṣe ìdánwò wọn."

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpínlẹ̀ ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti wáyé.

Títí ti ìgbà tí à ń kó ìròyìn yìí jọ, àjọ tó ń rí sí ìdánwò náà ní Nàìjíríà, WAEC kò ì tíì sọ ohunkóhun lórí ìdí tí ìdánwò tó yẹ kó bẹ̀rẹ̀ ní aago mẹ́jọ òwúrọ̀ fi pẹ́ kó tó bẹ̀rẹ̀, tó fi wá di alẹ́.

Ọ̀pọ̀ àwọn òbí sọ pé nígbà tí àwọn kò rí ọmọ àwọn lásìkò tó yẹ ni àwọn tọpinpin wọn lọ sí ilé ẹ̀kọ́ tó sì jẹ́ pé àwọn bá wọn tí wọ́n ń ṣe ìdánwò lọ́wọ́.

Wọ́n ní níṣe ló yẹ kí WAEC sún ìdánwò náà sí ọjọ́ míì nígbà tí kùdìẹ̀kudiẹ ti fẹ́ wáyé àti pé wọ́n nílò láti tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn.

Bákan náà ni wọ́n rọ ìjọba láti ri dájú pé wọ́n fojú àwọn tó ṣokùnfà bí ìdánwò náà ṣe pẹ́ jófin, kí wọ́n sì ri dájú pé irú rẹ̀ kò wáyé mọ́ lọ́jọ́ iwájú.

Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ rèé tí ọ̀rọ̀ ìdánwò fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń fa awuyewuye ní Nàìjíríà.

Ní oṣù tó kọjá ni ọ̀rọ̀ ìdánwò UTME fa awuyewuye nígbà tí ọ̀gá àgbà JAMB sọ pé kùdìẹ̀kudiẹ kan wáyé sáwọn ẹ̀rọ kọ̀mpútà tí wọ́n fi ṣe ìdánwò náà, tó sì mú kí ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ fìdí rẹmi.