"Bí Tinubu kò bá wá nǹkan ṣe lórí ètò ààbò àti ọrọ̀ ajé tó mẹ́hẹ, kò sí àṣeyọ̀rí kankan tó ṣe"

Oríṣun àwòrán, @Bat official
Ọjọ Kọkandinlọgbọn osu Karun ọdun 2023 ni wn bura fun aarẹ Bola Tinubu gẹgẹ bii aarẹ orilẹede Naijiria.
Abẹ asia ẹgbẹ oselu APC si ni aarẹ Tinubu ba wọle sipo aarẹ.
Ọpọlọpọ ileri si ni Tinubu ati ẹgbẹ oselu rẹ se fun awọn ọmọ Naijiria pe awọn yoo se tawọn ba gba ijọba.
Loni yii too pe ọdun meji ti aarẹ Bola Tinubu gori aleefa bii aarẹ Naijiria, awọn ileri ipolongo ibo rẹ wo lo ti se amusẹ rẹ ati awọn agbọn to ti kuna?
BBC Yoruba kan si onwoye awujọ kan, Ọjọgbọn Gbade Ojo, to jẹ Ọjọgbọn agba ni Fasiti Ilorin ati onimọ nipa ọrọ oselu lati se agbeyẹwo isejọba Tinubu lati ọdun meji to ti gori aleefa.
Eto Aabo:
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori agbeyẹwo ijba Tinubu ni ẹka eto aabo, Ọjọgbọn Gbade Ojo ni eto aabo Naijiria tun mẹhẹ tori ko tii si iyatọ gboogi ni ẹka naa.
O ni si ipa ijọba ko ka awọn agbebọn, agbesunmọmi, awọn ajinigbe atawọn eeyan miran to n huwa ọdaran tabi dunkooko mọ alaafia orilẹede yii.
"Inu fu, aya fu ni awọn ọmọ Naijiria n rin, awọn araalu ko le rin pẹlu irọrun mọ, ka to wa sọ irin alẹ.
Ojoojumọ ni gbọnmọ-gbọmọ awọn agbesunmọmi lapa oke ọya, bẹẹ ni ipa ijọba ko tii ka awọn ajinigbe-gbowo nisalẹ ọya pẹlu.
Ti a ko ba ni fi epo bọyọ, ipa ijọba ko ti ka eto aabo to mẹhẹ ni Naijiria.
Eto Oselu:
Ni agbọn oselu, Ọjọgbọn Gbade Ojo ni ipa Bola Tinubu ka ẹgbẹ oselu rẹ to wa ni ijọba, bi o tilẹ jẹ pe rogbodiyan n waye ninu awọn ẹgbẹ oselu yoku.
"Gbogbo eeyan gbori duro ninu ẹgbẹ APC, ti wọn si n tẹriba fun olori wọn, boya tori pe alaga ẹgbẹ APC, Ganduje fọwọ sowọpọ pẹlu ijọba Tinubu ni.
Mo ri pe sise akoso Tinubu ran lọwọ lati mojuto ẹgbẹ oselu APC, ti ko si tii ya pẹrẹpẹrẹ bii tawọn ẹgbẹ oselu alatako yoku.
Gbogbo awọn ẹgbẹ alatako yoku ni wn n ni iporogan, ti ẹnu wn ko si ka ara wọn"
Ọrọ aje:
Nigba to n se agbeyẹwo ijọba Tinubu ni ẹka eto ọrọ aje, Gbade Ojo ni awọn ọmọ Naijiria ko tii ri iyatọ kan dabi alara ni ẹka eto ọrọ aje.
"Bi o tilẹ jẹ pe ijọba n kede awọn aseyọri rẹ ni ẹka eto ọrọ aje, to si ni oun n san awọn gbese ti Naijiria jẹ sọrun.
Amọ bi ijọba Tinubu se n san gbese, naa lo tun n ya owo gbese tuntun, tori naa, a ko le e ri gbese sisan bii aseyọri tori se ni gbese Naijiria tun n pọ si.
Ti araalu yoo ba ri iyatọ nipa ọrọ aje, wọn yoo beere pe elo ni apo simẹnti, ẹwa ati apo irẹsi ki Tinubu to gba ijọba, elo si ni iye owo awọn eroja naa lonii?
Koda, owo iranwọ ti Tinubu yọ lori owo epo bẹntrolu, ti da wahala gidi silẹ ni ẹka eto ọrọ aje, eyi ti ko le jẹ ki awọn araalu riran ri awọn aseyọri miran ti ijọba Tinubu se."
Eto Ẹkọ:
Lasiko to n se agbeyẹwo ijọba Tinubu ni ẹka eto ẹkọ, Ọjọgbọn Ojo, tii se olukọ agba ni fasiti salaye pe ọpọ kudiẹ-kudiẹ lo n waye ni agbọn eto ẹkọ naa, a si n reti ọwọ ijọba.
"Ọpọ asise lo n waye ni ẹka eto ẹkọ tori awọn ajọ to n se akoso idanwo n da awọn ọmọ wa laamu.
Ni ẹnu ọjọ mẹta yii, a ri kudiẹkudiẹ ti ajọ JAMB se nidi idanwo asewọle sile ẹkọ fasiti nilẹ wa eyi to n fa awuyewuye.
Koda, ajọ to n se kokari idanwo asejade fawọn akẹkọọ agba nile ẹkọ girama gan tun se asemase tiẹ.
Inu okunkun ni awọn akẹkọ se idanwo ede oyinbo, wọn n tan abẹla ati lanta lati se idanwo, eyi ti ko yẹ ko ri bẹẹ.
Awọn olukọ ni fasiti ko da isẹ silẹ lasiko ijọba Tinubu tori isọnu ni, kii se pe inu wọn dun.
Gbogbo ileri ti ijọba n se atawọn iwe adehun ti wọn n ti ọwọ bọ fawọn olukọ fasiti, ko si eyi ti wọn tii mu sẹ ninu rẹ, ori ileri naa ni wọn wa.
Koda, ọpọ awwọn ile ẹkọ ti ko to fasiti, ni wọn ti gbe soke si fasiti, ti wọn si n da tuntun silẹ, ti aleebu rẹ si pọ.
Ibasepọ Naijiria si awọn orilẹede to wa nilẹ okeere:
Ni ti ibasepọ ijọba Naijiria si ti awọn orilẹede yoku ni agbaye, onimọ nipa eto iselu naa ni ijọba Tinubu n gbiyanju.
"Naijiria wa ni alaafia pẹlu awọn orilẹede miran nilẹ okeere amọ ohun kan to fẹ fọn Naijiria nikun ni ti ajọ ECOWAS.
Awọn ologun n gbakoso awọn orilẹede to n sọ ede Faranse labẹ ajọ ECOWAS, ti wọn si ri Naijiria bii agba ti ipa rẹ ko ka awọn olori to wa labẹ rẹ."
Ki lo yẹ ki ijọba Tinubu se lati se atunse ni ọdun meji to ku ki saa akọkọ rẹ pari?
Ọjọgbọn Gbade Ojo wa rọ ijọba Tinubu lati seto aabo to peye ni Naijiria tori ko si aseyọri kankan ti ijọba rẹ le se lai si eto aabo to peye.
Bakan naa lo tun n fẹ ki ijọba Tinubu mojuto ayipada eto ọrọ aje, ko le gbera soke, ki iye owo bẹntirolu wa silẹ, ko si se atunse awọn oju popo.
Ọjọgbọn Ojo tun mẹnuba pe lai si ipese alaafia yika orilẹede yii, yoo nira fawọn agbẹ lati lọ da oko, ki ounjẹ le sun wa bọ ni Naijiria.
Ọpọ awọn agbẹ lo ti fi oko wọn silẹ tori eto aabo to mẹhẹ, ti awọn oko to yẹ ki ounjẹ ti maa jade ni ọpọ yanturu si ti di igbo kiji-kiji.
Kókó ohun tí Ààrẹ Tinubu bá ọmọ Naijiria sọ lónìí àyájọ́ ọdún kejì ìjọba rẹ̀
Oni ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun un, ọdun 2025 lo pe ọdun meji gbako ti Aarẹ Bola Ahmed Tinubu gori alefa gẹgẹ bii Aarẹ Naijiria.
Ọdun 2023 ni wọn burawọle fun Tinubu gẹgẹ bii Aarẹ Naijiria ni gbagede Eagles Square to wa niluu Abuja.
Adajọ agba Olukayode Ariwoola lo burawọle fun un gẹgẹ bii Aarẹ Naijiria kẹrindinlogun.
Oniruru nnkan lo ti waye lẹyin iburawọle Tinubu, ninu eyii ti ero pupọ ọmo Naijiria ti ṣe ọtotọ.
Bi awọn ṣe n ṣo pe kii ṣe Tinubu ni Aarẹ ti awọn dibo yan lọdun naa lọhun lawọn mii n sọ pe Jagaban lawọn n fẹ, yoo si lo ọdun mẹjọ pe lori oye.
Wa yi o, Tinubu ti ba awọn araalu sọrọ lonii ayajọ ọdun keji rẹ lori oye gẹgẹ bii Aarẹ, awọn koko ohun to sọ ree.

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu
Kókó ọ̀rọ̀ mẹ́tàdínlógún tí Bola Tinubu sọ ní àyájọ́ ọdún kejì rẹ̀:
- Gbogbo awọn igbesẹ ti ijọba apapọ n gbe lori eto ọrọ aje Naijiria ti n so eso rere
- Labẹ eto Renewed Hope Agenda wa, a ṣelẹri lati mu atunṣe ba eto ọrọ aje, eto abo, fifi opin si iwa ajẹbanu, ki a si mu awọn eeyan kuro ninu iṣẹ
- A mọ pe nkan ko rọrun fun awọn eeyan ati pe ọwọngogo gori ọpọ nnkan, sibẹsibẹ itẹsiwaju n ba orilẹede wa
- Ọwọngogo to wa lode ti n dinku, fun apẹrẹ, owo apo irẹsi atawọn ounjẹ mii ti n pada walẹ
- A ti n ṣe aṣeyọri ni ẹka epo rọbi wa ni ida 400%, eto ọrọ aje ko fi si ọtun tabi osi mọ, a ti n ni idagbasoke
- Lati ibẹrẹ ọdun 2025, iye owo ti ijọba wa n pa wọle ti pọ ju iye owo ti a n na lọ
- Ninu oṣu kẹrin akọkọ ọdun yii iye owo ti a pa wọle le ni tiriliọnu mẹfa naira
- Kaka ki NNPC maa san owo iranwọ ori epo bẹntiro, niṣe ni oun funra rẹ n pa owo wọle fun ijọba
- Ko si ọwọngogo epo bẹntiro mọ, bẹẹ ni awọn ileeṣẹ ifọpo abẹle n gberu si
- Iye gbese ti ijọba wa jẹ ti dinku, bẹẹni iye owo ti a ni si ipamọ ti pọ ju ti tẹlẹ lọ
- A ti san gbese ti a jẹ ajọ IMF
- Biliọnu mẹrin dọla ni owo ti a ni si ipamọ lọdun 2023, ni bayii o ti le ni biliọnu mẹtalelogun dọla
- Aṣeyọri mii ti a tun ṣe ni atunṣe ofin owo ori, atunṣe naa ti n so eso rere bayii
- Ọpọ aṣeyọri ni a ti ṣe nipa idagbasoke awọn ọdọ
- Kaakiri Naijiria, o le ni ẹgbẹrun kan ile iwosan alabọde ti a n ṣe atunṣe si, bẹẹ ni a n ra isinṣẹ si ile iwosan alabode to le ni ẹgbẹrun marun un
- Bo tilẹ jẹ ọpọ idojukọ ni a ni lẹka eto abo, a n ṣe ọpọ aṣeyọri
- Ni ti ohun amayedẹrun, ọpọlọpọ oju ọna ni a n ṣe kaakiri Naijiria, bi a ṣe ṣe ọna tuntun, a tun n ṣatunsẹ awọn ọna to ti bajẹ
















