Àwọn ológun Nàìjíríà pa agbébọn mọ́kànlélógún ní Katsina

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army/X
Mọkanlelogun (21), ninu awọn agbebọn ti wọn fi igbo Shawu, nijọba ibilẹ Faskari, ipinlẹ Katsina ṣe ibugbe ni wọn ti pade iku ojiji bayii.
Atẹjade kan ti ileeṣẹ ologun Naijiria, fi si oju opo X wọn lo fidi iku awọn agbesunmọmi naa mulẹ.
Ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria ṣalaye pe ikọ to n wọde labẹ orukọ 'Operation Fansan Yamma', yabo ibuba awọn agbebọn naa lọjọ kẹtalelogun, oṣu Karun-un ọdun 2025.
Wọn fi kun un pe ninu ikọlu naa ni awọn ologun ti yinbọn pa mọkanlelogun ninu awọn agbebọn ọhun.
Atẹjade naa tẹsiwaju pe ogun gidi ni awọn ologun ati awọn agbesunmọmi naa ba ara wọn fa, ko too di pe awọn to ba ogun lọ pọ to bẹẹ.
Bakan naa ni omi gbe awọn kan lọ ninu awọn ẹlẹgiri naa lasiko ti wọn n gbiyanju lati sa lọ, gẹgẹ bi ileeṣẹ ologun ṣe wi.
Ṣugbọn, atẹjade naa ko fidi iku ọmọ ogun kankan mulẹ ninu ija naa.
Awọn nnkan ija ogun to pọ, pẹlu ọkada ogoji ati awọn maaluu ti awọn agbebọn ọhun ti ji lọwọ awọn eeyan ni awọn ṣọja ri gba lọwọ wọn.
Ologun ilẹ wa fi kun un pe awọn agbesunmọmi naa fi ibuba wọn silẹ lẹyin ikọlu, wọn fọnka wọ igbo lọ kiri.
Ẹ o ranti pe nnkan ko fararọ ni awọn ipinlẹ apa Ariwa Naijiria fun igba pipẹ, pẹlu bi ikọlu awọn agbebọn, ajinigbe ati agbesunmọmi naa ṣe n waye leralera.
Eyi ti mu ọpọ eeyan fi ilu silẹ lawọn ipinlẹ bii Maiduguri, Yobe, Plateau, Katsina ati bẹẹ bẹẹ lọ.














