Ẹkún àti ìpòruru ọkàn bí ìyá ṣe ta ọmọ bíbí inú rẹ̀

Àwọn èrò pẹ̀lú àwòrán Joshlin Smith lọ́wọ́ tí wọ́n bèèrè fún ìdájọ́ òdodo lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Gallo Images via Getty Images

    • Author, Khanyisile Ngcobo
    • Role, BBC News, Johannesburg
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Fídíò tó ṣàfihàn bí Joshlin Smith ṣe ń rẹ́rìn-ín, ọmọ tó wà ní ọdún mẹ́fà nígbà tó di àwátì ní nǹkan bíi ọdún kan sẹ́yìn ní South Africa, mú kí ilé ẹjọ́ kan bóbó.

Níbi ìgbẹ́jọ́ tó ń lọ ní Saldanha Bay, lẹ́bàá Cape Town, kí wọ́n tó ṣe ìdájọ́ ìyá Joshlin - ẹni tó máa ń lo egbògi olóró, tí ìgbàgbọ́ wà pé ó ta ọmọ rẹ̀ nítorí owó.

Racquel Smith, tí wọ́n tún mọ̀ sí Kelly Smit,h ni wọ́n dájọ́ ìjínigbé àti fífi ọmọ rẹ̀ ṣọfà fún ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yìí.

Ilé ẹjọ́ ní Racquel àti ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ Jacquen Appolis àti ọ̀rẹ́ wọn kan, Steveno van Rhyn, jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n.

Níṣe ọkàn gbogbo àwọn tó wà nílé ẹjọ́ gbọgbẹ́, kódà, ẹni tó ń tún ọ̀rọ̀ tí ọmọ náà sọ nínú fídíò náà lédè Afrikaans sí èdè Gẹ̀ẹ́sì náà bú sẹ́kún.

Òṣìṣẹ́ ilé ẹjọ́ ló kọ́kọ́ ka ọ̀rọ̀ náà jáde ní èdè Afrikaans, èdè táwọn èèyàn tó wà Middelpos ní Saldahanha Bay tí Joshlin ń gbé tẹ́lẹ̀ ń sọ.

Nínú ọ̀rọ̀ wọn ìyáìyá Joshlin, ọ̀rẹ́ ẹbí wọn kan tó ti fẹ́ gba Joshlin tọ́ ṣáájú àti olùkọ́ rẹ̀ sọ bí ó ṣe jẹ́ ìyàlẹ́nu pé ìyá ọmọ náà ta ọmọ bíbí inú rẹ̀.

Olùjẹ́rìí kan sọ fún ilé ẹjọ́ lásìkò ìgbẹ́jọ́ náà pé oníṣègùn ìbílẹ̀ kan tí wọ́n mọ̀ sí "sangoma" ni wọ́n ta ọmọ náà fún, pé ó ń fẹ́ ojú àti àwọ̀ ara ọmọ náà.

Pásìtọ̀ kan náà tún jẹ́rìí pé òun gbọ́ tí Smith sọ nígbà kan pé 20,000 rand ($1,100; £850) òun fẹ́ ta ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ náà àmọ́ òun le gba $275 lórí ẹni kọ̀ọ̀kan.

"Báwo ló ṣe ń sùn, tí ò ń gbé ayé pẹ̀lú ìwà yìí? Amanda Smith-Daniels, ìyá Racquel, tó ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀ méjì fi ọkàn tó gbọgbẹ́ bèèrè lọ́wọ́ ọmọ rẹ̀.

Smith àtàwọn tí wọ́n jọ fẹ̀sùn kàn kọ̀ láti sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀sùn náà láti oṣù Kẹta tí ìgbẹ́jọ́ náà ti bẹ̀rẹ̀ ní gbọ̀ngàn tó wà nínú ìlú Saldanha láti jẹ́ káwọn aráàlú kópa níbi ìgbẹ́jọ́ ọ̀hún.

Olùkọ́ Joshlin, Edna Maart júwe ọmọ náà bíi ẹni tó máa ń dákẹ́ lọ́pọ̀ ìgbà, tó sì máa ń wà ní tónítóní.

Ó ní ojoojúmọ́ ni àwọn akẹgbẹ́ Joshlin máa ń bèèrè rẹ̀ lọ́wọ́ òun ní kíláàsì.

Ó ní kí àwọn má ba à gbàgbé rẹ̀, orin tró fẹ́ràn jù "God Will Work It Out" ni àwọn máa n kọ ní ilé ẹ̀kọ́ ní àràárọ̀ tí ilé ẹ̀kọ́ bá ti bẹ̀rẹ̀.

Títí di àsìkò yìí, kò sí ẹni tó mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Joshlin.

Ìyá Joshlin Smith jókòó nílé ẹjọ́ tó sì ká ọwọ́ bọnú ara wọn. Àwọn méjéèjì tí wọ́n jọ fẹ̀sùn kàn wọ́n náà wà lórí ìjókòó

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Joshlin Smith's mother and her co-accused refused to testify
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bí ó ṣe di àwátì lọ́jọ́ Kọkàndínlógún, oṣù Kejì ọdún 2024 da ìpayà sílẹ̀ káàkiri orílẹ̀ èdè náà.

Bianca van Aswegen, onímọ̀ nípa ìwà ọ̀daràn àti alákòóso àjọ Missing Children South Africa fi ìṣẹ̀lẹ̀ Joshlin wé Madeleine McCann, ọmọ Britain tó di àwátì ní Portugal lọ́dún 2007.

Van Aswegen sọ fún BBC pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdájọ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ Joshlin tí wáyé, tó sì ti mú ọkàn àwọn èèyàn balẹ̀ díẹ̀, ó ní ìbéèrè tó gba ẹnu àwọn èèyàn ni pé níbo ni Joshlin wà nítorí kò sí ẹnikẹ́ni tó le sọ ibi tí ọmọ náà wà.

Ní oṣù Kẹwàá, ọdún 2017 ni Smith àti ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí, Jose Emke - ẹni tó bú sẹ́kún ní ilé ẹjọ́ lọ́jọ́rú - bí Joshlin.

Joshlin ni ọmọ wọn kejì. Òun àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀, tó ti pé ọdún mọ́kànlá báyìí, ni wọn kò rí ìtọ́jú bó ṣe yẹ gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ àwùjọ kan ṣe sọ nígbà tó ń jẹ́rìí nílé ẹjọ́.

Òṣìṣẹ́ náà sọ pé Racquel Smith gbé ọ̀dọ̀ ìyáìyá rẹ̀ dàgbà, tó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ní lo egbògi olóró láti ìgbà tó ti wà ní ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún.

Ó ní ó máa ń fi ìyà jẹ àwọn ọmọ rẹ̀ tó bá ti yó tán.

Ìyáìyá Smith le síta kúrò ní ilé ẹbí wọn nítorí àwọn egbògi olóró tó máa ń lò àti pé ó ti dúnkokò láti gun ọmọ rẹ̀ ọkùnrin lọ́bẹ rí nígbà náà.

Adájọ́ wòye pé ó gba Smith ní oṣù márùn-ún lẹ́yìn tó bí Joshlin tán láti ṣe àkọsílẹ̀ ìbí ọmọ náà – lábẹ́ òfin, èyí gbọdọ̀ wáyé láàárín ọgbọ̀n ọjọ́ tí èèyàn bá bímọ - tó sì ti gbé ní àwọn ilé tó wà fún àwọn obìnrin tí wọ́n bá fìyà jẹ.

Nígbà tó lọ fún ìtọ́jú, ọ̀rẹ́ ẹbí rẹ̀ kan, Natasha Andrews ló ń ṣe ìtọ́jú Joshlin, òun àti ọkọ rẹ̀ fẹ́ gba ọmọ náà tọ́.

"A lè ṣe ìtọ́jú ọmọ náà ju ìyá rẹ̀ lọ," Andrews sọ lásìkò ìgbẹ́jọ́ náà, àmọ́ tó ní ìgbésẹ̀ náà kò lọ dáadáa nítorí àwọn òbí rẹ̀ kò gbà kí àwọn gbà á tọ́.

Síbẹ̀, Joshlin máa ń lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹbí Andrews lópin ọ̀sẹ̀, tí wọ́n bá ní ìsinmi nílé ẹ̀kọ́, tó sì tún máa ń tẹ̀lé wọn lọ ìrìnàjò.

Fídíò tí wọ́mn fi hàn nílé ẹjọ́ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìrìnàjò tó tẹ̀lé ẹbí Andrews lọ, tó sì wà lára ẹ̀rí tí wọ́n fi lélẹ̀ nílé ẹjọ́.

Ó ṣe àgbékalẹ̀ àwọn àwòrán bí Joshlin ṣe ń ṣeré pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin, tó sì júwe bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe jẹ́ àdánù ńlá àti ohun ìbànújẹ́ fún ẹbí rẹ̀.

Ilé tí wọ́n fi irin kọ́ ní agbègbè Middelpos ni Joshlin gbé pẹ̀lú ìyá rẹ̀, àwọn ẹ̀gbọ́ rẹ̀ àti ọ̀rẹ́kùnrin ìyá rẹ̀.

Òṣìṣẹ́ àwùjọ jùwe ilé náà bíi èyí tí kò ní ààyè tó bẹ́ẹ̀ nítorí bó ṣe kéré.

Ilé tí wọ́n fi irin kọ́ ní Middelpos

Oríṣun àwòrán, Mohammed Allie / BBC

Àkọlé àwòrán, Ibí yìí ni Joshlin àti àwọn ẹbí rẹ̀ ń gbé

Onírúurú iṣẹ́ ìdọ̀tí ni Smith máa ń ṣe láti fi ran ẹbí rẹ̀ lọ́wọ́ tó fi mọ́ ṣíṣe iṣẹ́ ilé fún Kelly Zeegers, ẹni tó ń gbé ní àdúgbò náà pẹ̀lú àwọn ẹbí rẹ̀, tó sì máa ń fún Smith dípò kó san owó fún-un.

Zeegers ní ìdí tí òun fi máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni láti ri dájú pé òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ rí oúnjẹ jẹ.

Àwọn ẹlẹ́rìí míì júwe Smith bíi abiyamọ dáadáa; àbúrò rẹ̀ sọ fún ilé ẹjọ́ pé Joshlin jọ ìyá rẹ̀ gidi gan, pé bí ìyá rẹ̀ ṣe rí ní kékeré ni Joshlin.

Kò sí ẹni tó mọ bí Joshlin ṣe di àwátì àmọ́ nǹkan díẹ̀ tó hàn ni pé ìyá rẹ̀ ní ẹ̀yìn ilé, tó ń fa egbògi olóró pẹ̀lú Appollis àti Van Rhyn.

Olùjẹ́rìí ìjọba, Laurentia Lombaard ṣàlàyé pé Joshlin, ẹni tó ti bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ láti ọ̀sẹ̀ díẹ̀ sẹ́yìn kó tó di àwátì, àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ kò ló sílé ẹ̀kọ́ lọ́jọ́ náà nítorí aṣọ wọn dọ̀tí.

Appollis ló ń ṣe ìtọ́jú àwọn ọmọ náà lọ́jọ́ náà nítorí ìyá ń jáde wọlé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti wá fa egbògi olóró ni.

Kò sí ẹni tó le sọ pé ìgbà báyìí ni ọmọ náà di àwátì àmọ́ ilé ẹjọ́ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọ̀sán ni àmọ́ nǹkan bíi aago mẹ́sàn-án alẹ́ ni wọ́n lọ fi tó ọlọ́pàá létí pé àwọn ń wá Joshlin.

Òṣìṣẹ́ àwùjọ tí wọ́n ní kó kọ ìjábọ̀ lórí àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kí wọ́n tó ṣe ìdájọ́ wón júwe Smith bíi alágàbàǹgebè, tó sì máa parọ́ ojú korojú.

Ó ní kìí ṣe ohun tó le rárá láti gbàgbọ́ pé Smith ló wà nídìí bí wọ́n ṣe ta ọmọ rẹ̀.

Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí wọ́n fẹ̀sùn kàn ń wọ inú gbọ̀ngàn lọ fún ìgbẹ́jọ́ lọ́jọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Karùn-ún, 2025.

Oríṣun àwòrán, Gallo Images via Getty Images

Àkọlé àwòrán, Gbọ̀ngàn kan láàárín ìlú ni wọ́n ti ń ṣe ẹjọ́ náà

Van Aswegen ní òun ní ìrètí pé ilé ẹjọ́ máa fún wọn ní ìdájọ́ tó yẹ èyí tó máa ṣàfihàn ìwà ọ̀daràn lórí bí àwọn èèyàn ṣe ń ta ọmọ tó ń pọ̀ si.

"Ìwà yìí burú ju àkọ́ọ́lẹ̀ tó wà lọ́wọ́ àwọn ọlọ́pàá lọ nítorí ọ̀pọ̀ irú ìwà yìí ló ń lọ lábẹ́lẹ̀ tí kò sí àkọ́ọ́lẹ̀ fún," ó sọ fún BBC.

Ó ní ohun tó yàtọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ Joshlin ni pé gbogbo orílẹ̀ èdè ló dá si.

"Mi ò ì tíì rí kí irú ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí di nǹkan ńlá ní South Africa rí, bẹ́ẹ̀ náà ni mi ò ri kí wíwá ọmọdé di ohun ńlá báyìí. Mo lérò pé ayélujára kó ipa púpọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí àti pé àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú náà dá si."

Gẹ́gẹ́ bí ìkànnì ìròyìn South Africa IOL ṣe sọ ọmọdé 632 ló di àwátì lọ́dún tó kọjá, táwọn 8,743 sì ti dàwátì láàárín ọdún mẹ́wàá sí àsìkò yìí.

Ṣáájú nínú oṣù yìí, agbẹnusọ ọlọ́pàá, Athlenda Mathe sọ pé ọ̀pọ̀ àwọn ọmọdé ni àwọn ṣàwárí tí wọ́n sì darapọ̀ mọ́ àwọn ẹbí wọn.

Van Aswegen ní èyí túmọ̀ sí pé kí àwọn má sọ ìrètí nù àti pé wíwá Joshlin ṣì máa tẹ̀síwájú.

Bákan náà ni àwọn ẹbí Andrews ní àwọn kò sọ ìrètí nù lórí ṣíṣe àwárí Joshlin.

"A fẹ́ dìmọ́ ẹ, ìwọ ni òdòdó wa, ọmọ wa àti olójú àwọ̀ ewé wa," Abílékọ Andrews sọ nínú ọ̀rọ̀ nílé ẹjọ́.