Àlàyé rèé nípa afurasí Babaláwo t'ọwọ́ àṣọ́bodè tẹ̀ lẹ́nu bodè Sẹ̀mẹ̀ fún ẹ̀sùn pé ó n ri àwọn èèyàn mọ́lẹ̀, tó sì ń náwó bíi ẹlẹ́dà

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ileeṣẹ to n ri si iwọle-wọde ero ati ẹru ni Naijiria, Nigeria Immigration Service (NIS), ti kede pe oun ti mu afurasi kan lori ẹsun pe o n fi awọn eeyan ṣe oogun owo.
Bakan naa lo ni afurasi naa tun n ri wọn mọlẹ ni ipinlẹ Enugu.
Onyeka Nwaobu ni wọn pe orukọ rẹ, inagijẹ rẹ si ni Ozor Ezeani.
Aaye ni wọn ni Nwaobu maa n ri eeyan mọlẹ nile rẹ to wa ni Ndiagu, ipinlẹ Enugu.
Alaye osisẹ ajọ to nawọ gan-an naa ni pe lasiko ti afurasi yii fẹ sa kuro ni Naijiria lawọn mu un ni ẹnu ibode Naijiria ati Ilẹ Olominira Benin.
Agbẹnusọ ajọ to n rin si iwọle-jade ero lorilẹede yii, AS Akinlabi, fidi eyi mulẹ ninu atẹjade to fi sita.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Wọn gbe mi sinu iho kan, wọn da ewe bo mi, ṣugbọn mi o dakẹ, awọn fijilante to n kọja lo gbe mi jade - Ọmọ ti wọn ji gbe
Ọmọdebinrin kan ti wọn ni Onyeka Nwaobu ji gbe lọna oko lo jẹ ki aṣiri ikọkọ nipa ọkunrin naa tu.
Ninu fidio kan to gba ori ayekujara kan ni ọmọdebinrin naa ti ṣalaye pe oun ati baba oun lọ ṣẹgi loko lọjọ naa ni.
O ni Nwaobu si wa bẹ baba oun fun iranlọwọ lori alupupu rẹ to ni o bajẹ.
Ọmọbinrin yii sọ pe ṣugbọn Nwaobu ati awọn eeyan rẹ pada fi ajulọ han baba oun, wọn si gbe oun, wọn fi okun so oun lẹsẹ, wọn tun di ẹnu oun pa.
" Wọn gbe mi sinu iho kan, wọn si da ewe bo mi mọbẹ. Ṣugbọn mi o dakẹ, eyi si jẹ ki awọn fijilante to n kọja wa ran mi lọwọ, wọn gbe mi jade."
Bẹe ni ọmọde naa sọ ninu fidio ọhun.
Awọn ara Abule Umumba Ndiagu ti iṣẹlẹ yii ti waye, sọ fun BBC pe ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Karun-un ọdun 2025 yii lo ṣẹlẹ.
Lẹyin ti wọn gba ọmọde naa lọwọ ijinigbe ni awọn ara abule yabo ile Nwaobu pẹlu ibinu, wọn si jo o kanlẹ raurau.
Afurasi yii ti sa lọ nigba naa bi wọn ṣe ṣalaye.
Ara abule naa kan, Ambrose Obieze, ṣalaye fun BBC pe ọpọ iho ni awọn ri nilee Nwaoba.
O ni awọn eeyan lo n ri mọlẹ sinu awọn iho naa laaye.
Awọn fidio ati fọto lati ile Babalawo yii ṣafihan oogun rẹpẹtẹ nile rẹ, eyi ti awọn ara abule lawọn ba nibẹ.
"Nwaobu wa sile lati Togo bi awọn ọdọ yoku, ti wọn ni awọn fẹ gbe iṣẹ awọn baba nla awọn larugẹ amọ ẹjẹ lo fẹ maa mu"
Gẹgẹ bi ohun ti awọn ara abule sọ fun BBC , Babalawo ti awọn eeyan bẹru gan-an ni Onyeka Nwobu lagbegbe naa.
Orukọ rẹ bii Babalawo ni Ozor Ezeani, wọn ni awọn tun maa n pe e ni 'ichie million', eyi to tumọ si oloye to ni miliọnu lọwọ.
Awọn ara abule sọ pe bi ẹlẹ́dà lo maa n nawo lode ariya ni awọn ṣe n pe e bẹẹ.
Orilẹede Togo ni wọn ni Nwaobi n gbe tẹlẹ, ko too pada waa maa yiwọ pada labule.
Ikechukwu Chime, pasitọ kan labule naa, sọ fun BBC pe Nwaobu wale bi awọn ọdọ yoku, ti wọn maa n sọ pe awọn fẹ maa gbe iṣẹ awọn baba nla awọn larugẹ ni.
Ṣugbọn bayii, o ni o ti han si awọn pe ẹjẹ ni Nwaobi fẹ maa mu.
Kí ni àwọn ẹbi Nwaobu wi?
Ọkan lara awọn mọlẹbi afurasi yii, ṣalaye fun BBC pe Togo ni ẹgbọn awọn, Nwaobu, ti de.
O ni ko pẹ to de si abule naa lo bẹrẹ si i kọle.
"Awa tiẹ ro pe o ti di olowo nla ni, ṣugbọn ni bayii, a ti mọ pe o gbe oogun wale lati ọhun to maa n beere ori eeyan.
" Ohun ti a mọ ni pe Babalawo ni, o si maa n yinbọn ṣakabula laaarin oru. A o mọ pe o n pa eeyan."
Ara abule kan naa sọ fun BBC pe oogun ika ni Nwaobu maa n ṣe gẹgẹ bii Babalawo.
Awọn ara abule yii sọ pe niṣe lo fipa gba ilẹ to kọle si naa lọwọ obinrin kan ti ọkọ rẹ ku.
Ṣugbọn Nwaobu funra rẹ sọ pe irọ ni wọn n pa mọ oun. O ni oun ki i ṣe Babalawo, aloku aṣọ ti a mọ si Okrika loun n ta.
Bakan naa lo ni awọn ọta ti ko fẹ koun jọba ti ko ni i pẹ kan oun, lo wa nidi awọn iho ti wọn ba nile oun.
Ìgbésẹ̀ ìjọba àti ọlọ́pàá Enugu

Gomina ipinlẹ Enugu, Peter Mba, ti paṣẹ pe ki wọn wo ile afurasi yii, wọn si ti ṣe bẹẹ.
Ofin ipinlẹ naa ni pe ijọba yoo ba ile ẹni to ba n ji eeyan gbe jẹ, wọn yoo si gba ilẹ to kọ ile naa si.
Ninu ọrọ Kọmiṣanna ọlọpaa Enugu, Mamman Bitrus Giwa, o gboriyin fun awọn fijilante agbegbe to ṣiṣẹ ti wọn fi ri ọmọdebinrin naa gba silẹ lọwọ ijinigbe.
Bakan naa ni Agbẹnusọ ọlọpaa Enugu,Daniel Ndukwe, fi orukọ awọn eeyan mẹta ti wọn ti mu lede.
O fidi ẹ mulẹ pe awọn ri oku awọn eeyan to ti n jẹra , ọkunrin ati obinrin kan ninu awọn iho ti afurasi Babalawo naa gbẹ si ile rẹ.














