Àṣírí àjẹbánu owó ìrànwọ́ epo rọ̀bí tú, ọmọ alága tẹ́lẹ̀ fẹ́gbẹ́ PDP rí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rìnlá he lórí ẹ̀sùn kíkó N2.2b jẹ

Oríṣun àwòrán, @chronicle_ng
Mamman Ali, ọmọ alaga ẹgbẹ oṣelu PDP telẹ, Ahmadu Ali, ti ri ẹwọn ọdun mẹrinla he lẹyin to jẹbi ẹsun lilu ijọba ni jibiti owo to le ni biliọnu meji naira.
Mamman ati ẹnikeji rẹ, Christian Taylor, ni wọn jọ ri ẹwọn naa he fun lilu owo ọhun, to jẹ owo iranwọ epo bẹntiro ni ponpo.
Ile ẹjọ kan lagbegbe Ikeja, nipinlẹ Eko lo gbe idajọ naa kalẹ lẹyin ti awọn olujẹjọ mejeji jẹbi ẹsun mẹtadinlọgọta to rọ mọ iditẹ, gbigba owo lọna aitọ ati iwe yiyi.
Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ni Naijiria, EFCC lo pe awọn olujẹjọọ mejeji lẹjọ.
Yatọ si awọn ọdaran yii, ile ẹjọ tun sọ pe ileeṣe kan, Nasaman Oil Services Ltd, jẹbi fifi ọna ẹburu gba owo ti iye rẹ le ni biliọnu meji naira lọwọ ijọba apapọ.
Wọn ni owo naa wa fun iranwọ ori epo bẹntiro ti lita rẹ jẹ 20,492,982.50 ti wọn ko wọle lati oke okun si Naijiria.
EFCC ni awọn ọdaran ọhun so pe ọwọ ileeṣẹ SEATAC Petroleum Ltd, to wa ni British Virgin Islands ni awọn ti ra epo ọhun.
Ninu iwadii EFCC, wọn ni awọn ṣawari rẹ pe irọ ni wọn pa, ati pe ayederu ni awon iwe ti wọn fa kalẹ nipa rira epo bẹntiro naa.
Lasiko ti igbẹjọ naa n waye, awọn afurasi ọhun sọ pe awọn ko jẹbi ẹsun naa rara.
Ikọ agbẹjọro EFCC, ti Seiduh Atteh dari wọn ko oniruru ẹri sile niwaju adajọ to fi han pe loootọ ni awọn afurasi naa lu obitibiti owo ni ponpo.
Ninu idajọ rẹ, adajọ Mojisola Dada sọ pe awọn ẹri ti EFCC ko wa siwaju oun fi han pe lootọ ni awọn ọdaran ọhun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn.
Adajọ ọhun ni yatọ si pe awọn eeyan naa lo gbajuẹ fun ijọba apapọ, wọn tun ti ṣe akoba fun eto iranwọn epo bẹntiro ijọba apapọ.
Lẹyinorẹyin, ile ẹjọ sọ awọn ọdaran mejeji si ẹwọn ọdun mẹrinla lori gbogbo ẹsun ti wọn jẹjọ rẹ.
Ile ẹjọ tun ni ki ijọba gbẹsẹle gbogbo dukia ti wọn fi owo jibiti naa ko jọ.
Lẹyin naa lo ni ki awọn agbofinro tẹsiwaju lati maa wa awọn afurasi meji mii, Oluwaseun Ogunbambo ati Olabisi Abdulafeez, lẹyin ti wọn ti na papa bora.















