Ọwọ́ ológun Nàìjíríà tẹ ṣọ́ja 18, ọ̀lọ́pàá 15, fẹ̀sùn kan àwọn àjọ òkèèrè tó ń ṣe agbódegbà fáwọn agbésùnmọ̀mí

Oríṣun àwòrán, nigeria Army
Ileeṣẹ ọmọogun Naijiria ni ọwọ awọn ti tẹ awọn ṣọja mejidinlogun ati ọlọpaa marundinlogun kan lori ẹsun pe wọn n ko ibọn ati ọta fun awọn ẹgbẹ agbesunmọmi.
Ikọ amuṣẹya kan ti ileeṣẹ ologun Naijiria gbe kalẹ loju ija lẹkun ila oorun ariwa orilẹede Naijiria loṣu kẹjọ ọdun 2024, eyi ti wọn pe ni Operation Snowball lati gbogun ti karakara ohun ija oloro lagbegbe naa lo mu awọn afurasi ọbayejẹ naa.
Awọn eeyan mejọ ti kii ṣe ologun tabi ọlọpaa pẹlu wa lara awọn afurasi ọdaran naa, ninu eyi ti ọbalaye kan at'awọn mẹjọ miran wa.
Ipinlẹ mọkanla ni ọwọja ikọ amuṣẹya naa de, nibi ti wọn ti fi panpẹ ofin mu awọn kan lara awọn afurasi naa nibi ti wọn ti n hu iwa ọbayejẹ wọn.
Ileeṣẹ ologun ni owo ti iye rẹ n wọ ẹgbẹlẹgbẹ dọla ni wọn ba ninu aṣuwọn ifowopamọ awọn afurasi naa.
Bakan naa ni wọn tun na ika aleebu si awọn ileeṣẹ aṣeranwọ kan pe wọn n gbe ounjẹ lọ s'awọn agbegbe kan to jẹ ibuba awọn agbesunmọmi labẹ iboju pe wọn n ko ounjẹ lọ fun awọn ogunlende.Amọṣa wọn ko darukọ awọn ajọ ti aje ọrọ naa ṣi mọ lori.
Awọn afihan wọnyi jẹyọ pẹlu bi ọgagun agba loju ija igbogunti sunmọmi lẹkun ila oorun ariwa, Ọgagun Abdulsalam Abubakar ṣe n fi ẹsun kan awon ajagunta okeere kan pe wọn n seto idanilẹkọ fawọn ẹgbẹ agbesunmọmi gbogbo ni Naijiria.
Ogagun naa ti ṣalaye ṣaaju lọsẹ yii pe ọwọ ti tẹ awọn ọmọ orilẹede Pakistan mẹrin kan lori ẹsun pe wọn n ṣe idanilẹkọ nipa lilo balu abẹyẹfo jagun drone fun sise alami ati ikọlu. Bakan naa ni wọn ni awọn ọmọ orilẹede Pakistan naa tun n ko nnkan ijagun wọle fun awọn ẹgbẹ agbesunmọmi lẹkun ila oorun ariwa orilẹede Naijiria, ti wọn si tun n ro awọn agbesunmọmi naa bii ISWAP ati Boko Haram, lagbara sii.
Ọgagun Abubakar sọ pe, "Ọwọja awọn ajagunta yii ti n han lara oṣẹ iṣẹ laabi ati ikọlu awọn agbesunmọmi naa eleyi to n ṣokunfa aleku ọṣẹ ati iku awọn ologun ati ohun ija wọn.
Lọsẹ to kọja, Gomina Babangana Zulum pariwo sita pe awọn ologun ati araalu kan n ṣe alami ati agbodegba fun awon ẹgbẹ agbesunmọmi alakatakiti ẹsin Islam kan, lẹyìn ti ọwọja ikọlu awọn agbesunmọmi tun n le sii ni ipinlẹ Borno.














