Regina Chukwu sọ ìdí tí ọkọ rẹ̀ ṣe ní kò gún òun ní abẹ́rẹ́ ikú lẹ́yìn ọdún mẹ́tà ìgbéyàwó àti oṣù mẹ́rin tó bímọ

Aworan Regina Chwkwu

Oríṣun àwòrán, Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Regina Chukwu, gbajugbaja oṣere tiata ni orukọ rẹ gba ori ayelujara lọwọ lọwọ bayii.

Idi ni pe Regina sọrọ lori ohun to sọ di opo ọsan gangan ati bi o ṣe padanu ọkọ rẹ lẹyin ọdun mẹta ti wọn ṣe igbeyawo ati oṣu mẹrin ti wọn bi ọmọ.

Arun ikọ ife ni Regina Chukwu sọ pe o mu ọkọ oun, eyi to dede ran si ọrun ọan gangan.

Oṣerebinrin naa tẹnu bọrọ lasiko to n ba akẹgbẹ rẹ Biola Bayo sọrọ, o ni oun tete ṣe igbeyawo gẹgẹ bii obinrin, paapa oun lọkọ nigba ti oun si wa ni ile ẹkọ.

Chukwu sọ pe ni kete ti oun pari ile ẹkọ girama ni oun pade ọkọ oun to jẹ ẹya Igbo nipinlẹ Anambra.

O ni ọkọ oun ni arun ikọ ife lẹyin to ṣagbako awọn ijamba kan.

"Ọjọ keji ni mo ji lẹyin ti mo daku nigba ti ọkọ mi ku, n ko ni anfani lati sọ pe o dabọ fun ọkọ mi"

Gẹgẹ bii Regina Chukwu ti ṣalaye, ilera ọkọ oun di nnkan to le ju ẹmi rẹ lọ ni kete ti oun bi ọmọ keji.

Oṣere naa, ẹni ọdun marundinlọgọta ni gbogbo igbiyanju ni oun sa lati doola ẹmi ọkọ rẹ, koda o ni oun tẹle lọ si abule rẹ nipinlẹ Anambra nibi ti wọn ti n tọju rẹ ni ilana ibilẹ.

Chukwu ni inira de ba ọkọ oun debi pe ọkọ rẹ bẹẹ pe ko fun ni abẹrẹ iku nitori inira ọhun pọju.

Lẹyin ọpọlọpọ akitiyan, Regina padanu ọkọ rẹ lẹni ọdun mejidinlọgbọn.

"Mo ri bi baba ọkọ mi ṣe n fa, to n fa pẹlu ọwọ mejeeji.

O ni o ti ku. Inu bi mi. Ọjọ keji ni mo ji lẹyin ti mo daku. N ko ni anfani lati sọ pe o dabọ fun ọkọ mi," o ṣalaye.

"Lẹyin ti a sin, ti a pari gbogbo eto, awọn ẹgbọn rẹ lobinrin ni ki n maa pada si ilu Eko.

Wọn ni pe awọn yoo gba ile ati sọọbu fun mi ni ilu Enugu."

'Iyawo si ni mi si awọn mọlẹbi ọkọ mi to di oloogbe'

Chukwu tẹsiwaju pe ni ilana aṣa idile ọkọ oun, iyawo wọn ni oun si jẹ ayafi ti awọn ẹbi mi ba da owo ori ti wọn san pada fun wọn.

O fikun pe idile ọkọ oun gba akọbi ọmọ oun kuro ni akata oun nitori ilana aṣa wọn.

"Lonii bayii, mo si jẹ iyawo fun wọn. Bẹẹni, n ko kọ ọkọ mi silẹ," o sọrọ.

"Iyawo si ni mi. N ko jawe fun ọkọ mi. Ti mo ba jawe, ti mo ni ọkọ mii, to si da owo ori wọn pada, mi ki n ṣe iyawo wọn nigba naa ."

"Ṣugbọn lonii, Ọlọrun ma jẹ ki aburu sẹlẹ si mi. Aṣa wọn niyẹn."