Obìnrin tó lu ọmọ ara rẹ̀ ní gbànjo rí ẹ̀wọ̀n gbére he

Joshlin Smith

Oríṣun àwòrán, Executive Mayor Andrè Truter/ Facebook

Àkọlé àwòrán, Joshlin Smith, ọmọ to sọnu
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Obinrin ọmọ orilẹede South Africa kan to lu ọmọ bibi inu rẹ ni gbanjo pẹlu awọn meji mii ti ri ẹwọn gbere he.

Ile ẹjọ ni obinrin naa jẹbi ẹsun jiji ọmọ ara rẹ to jẹ ọmọ ọdun mẹfa pere gbe, to si ta ọmọ naa.

Ọdaran ọhun, Racquel "Kelly" Smith, ọrẹkunrin rẹ Jacquen Appollis ati ọrẹ wọn mii Steveno van Rhyn ni wọn jẹbi ẹsun naa lẹyin ọdun kan ti ọmọ kekere ọhun ti di awati.

Bo tilẹ jẹ pe ọpọ araalu lo ke gbajare sita nipa ọmọ naa lẹyin to poora, titi di asiko yii, wọn ko tii mọ ibi to wa.

Awọn agbẹjọro ijọba sọ pe ni ṣe ni wọn ta ọmọ naa si oko ẹru amọ wọn ko mẹnuba koko ọrọ naa ninu awijare wọn.

Iroyin sọ pe o ṣeeṣe ko jẹ pe niṣe ni iya ọmọ naa taa lati fo owo rẹ ra oogun oloro.

Idajọ ọhun lo waye lẹyin igbẹjọ to waye fun odidi ọsẹ mẹjọ gbako, eyii to mi gbogbo South Africa titi.

Adajọ Nathan Erasmus sọ pe oun ko ri iyatọ kankan laarin awọn ọdaran mẹtẹta to gbe idajọ naa kalẹ fun.

Ersamus ni "Lori ẹsun fifi ọmọde ṣowo mo dajọ ẹwọn gbere fun yin, fun ẹsun ijinigbe, mo dajọ ẹwọn ọdun mẹwaa fun yin."

Lẹyin idajọ yii ni gbogbo awọn eyan to wa ninu ile ẹjọ naa fo fun ayọ ti wọn si bẹrẹ si n patẹwọ.

Kelly Smith

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Kelly Smith, iya ọmọ naa

Adajọ ọhun tun ba awọn eeyan ọdaran naa wi, paapaa iya ọmọ ọhun ati ọrẹkunrin rẹ lori iwa aibikita wọn.

O ni "Mi o ri eredi kankan to fi yẹ ki n fun yin ni idajọ ti ko lagbara."

Adajọ naa sọ siwaju si pe yatọ iwa ibi ti wọn wu si ọmọde naa, iṣẹlẹ ọhun tun da ọgbẹ si ọkan awọn eeyan agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Iroyin ni awọn ọdaran naa ko bikita rara, bẹẹ ni wọn ko barajẹ lasiko ti idajọ ọhun n lọ lọwọ.

Wayi o, ileeṣẹ ọlọpaa ti sọ pe oun ko ni dẹkun ati maa wa ọmọde naa bo tilẹ jẹ pe awọn to ta ti gba idajọ to yẹ wọn.