'Inú yàrá ni mo tẹ́ ọmọ oṣù méjì mi sí àmọ́ inú kàǹga la ti rí òkú rẹ̀ lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta'

Aishat Tahiru tí ọkàn rẹ̀ gbọgbẹ́ àti àwòrán kàǹga tí wọ́n ti rí òkú ọmọ rẹ̀
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Niṣe ni awọN ara adugbo Maiduku ni agbegbe Sango, Ilorin, olu-ilu ipinlẹ kwara, n pariwo pe iru ki ni eleyii lẹyin ti ọmọ oṣu meji di awati ninu yara ti iya rẹ tẹ ẹ si.

Lọjọ kẹẹdọgbọn, osu Karun un ọdun 2025 ni iṣẹlẹ iyalẹnu naa waye ni ojule kẹsan-an, adugbo Maiduku.

Obinrin abilekọ kan ti orukọ rẹ n jẹ Aishat Tahiru lo figbe ta ni nnkan bii aago mẹjọ abọ alẹ pe ọmọ oun ti oun tẹ sinu yara ṣadeede di awati.

Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Aishat Tahiru sọ pe oun tẹ ọmọ naa to jẹ ọmọ oṣu meji ti orukọ rẹ n jẹ Adam Tahiru sinu yara lati sun, ti oun si lọ kirun lẹyinkule ile ti wọn n gbe.

O ṣalaye pe oju orun ni ọmọ tuntun naa wa nigba ti oun fi silẹ.

"Nigba to di bii aago mẹjọ abọ, ti mo kirun tan ni mo ni ki ẹgbọn ọmọ naa lọ wo aburo rẹ to n sun ninu yara ti mo tẹ ẹ ṣi, amọ to pada wa pe oun ko ri aburo oun.

"Emi naa dide wọ inu yara lọ nitori o yami lẹnu pe o ni oun ko ri aburo oun amọ nigba ti emi naa wọle, ko si ọmọ ninu yara mọ."

O sọ pe eyi lo mu ki oun fi igbe ta tawọn si bẹrẹ si ni wa ọmọ oṣu meji kaakiri gbogbo adugbo.

Aishat tẹsiwaju pe nigba ti awọn wa ọmọ naa titi tawọn o ri ni awọn gba agọ ọlọpaa lọ lati lọ fẹjọ iṣẹlẹ naa sun.

O ni lẹyin ọjọ kẹta lawọn ri aṣọ ọmọ naa lẹgbẹẹ kanga ile kan to koju si ile karun-un si ile awọn, igba ti wọn yoo wọ inu kanga, oku ọmọ naa ni wọn ri to ti lefoo.

Iya ọmọ naa sọ pe, iṣẹlẹ naa ba oun lọkan jẹ pupọ nitori oun jiya pupọ lori ọmọ naa ki oun to bi to si n pe fun idajọ ododo lori iṣẹlẹ naa.

Ilé ti ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé

Afurasi mẹjọ ni ọwọ ọlọpaa ti tẹ - ileeṣẹ ọlọpaa

Ninu ọrọ rẹ, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Adetoun Ejire-Adeyemi sọ pe ọwọ ọlọpaa ti tẹ eeyan marun-un ti wọn furasi pe wọn lọwọ lori bi ọmọ naa ṣe di await.

O ni iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.

Agbẹnusọ ọlọpaa naa ṣalaye pe agọ ọlọpaa to wa ni Kulende ni ilu Ilọrin ni wọn kọkọ lọ fi ẹjọ sun, ko to di pe wọn gbe ẹjọ naa wa si olu-Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara fun ẹkunrẹrẹ iwadii.

Alukoro ajọ ọlọpaa fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ, pẹlu alaye pe eeyan mẹjọ lọwọ ti tẹ, ti iwadii si n tẹsiwaju.

O fi idaniloju han pe idajọ ododo yóò waye lori iṣẹlẹ naa.