Lamine Yamal àti agbábọ́ọ̀lù mẹ́sàn án tó lówó lórí jùlọ lágbàáyé ní 2025

Lamine Yamal

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Idi iṣẹ ẹni la a mọni lọlẹ, bi ade ogo ba si ti wa lori iyanju ẹda, onitọhun yoo tayọ laaarin ẹgbẹ rẹ.

Bo ṣe ri ni awọn ẹka iṣẹ gbogbo ree, bẹẹ naa lo ri lawujọ awọn agbabọọlu kaakiri agbaye.

Wọnyi lawọn to ta yọ julọ bayii ninu awọn agbabọọlu ni ọdun 2025, ati iye ti wọn n ko le wọn lori.

Ṣé ó wù ọ́ láti má a ka ìròyìn eré ìdárayá láti orí Whatsapp rẹ?

Lamine Yamal

Bi ikọ agbabọọlu kan yoo ba ra ọdọkunrin nni to n gba bọọlu fun ikọ Barcelona, Lamine Yamal, wọn yoo ni to £340m bayii.

Ẹka iwadii kan ni Swiss Research Centre, lo fidi eyi mulẹ.

Ajọ CIES to n woye bọọlu afẹsẹgba, ṣalaye pe irinwo miliọnu owo euro (400 million euros) ni owo to le ra Lamine Yamal ti ko ju ọmọ ọdun mẹtadinlogun lọ.

Ọmọkunrin to wa lati orilẹede Spain yii ni ẹnikarun-un to kere julọ to gba bọọlu fun igba akọkọ nigba to wa lọmọ ọdun mẹẹẹdogun ati oṣu mẹsan-an.

O ti gba bọọlu sawọn ni igba mẹtalelogun (23 goals), eyi ju iye bọọlu ti Lionel Messi to gba ami ẹyẹ Ballon d'Or gba sawọn lọ nigba mẹjọ, nigba tiyẹn wa ni ọjọ ori ti Lamine wa yii.

Ipa kekere kọ ni Yamal ko ninu aṣeyọri Spain ninu idije Euro 2024 .

Ninu idije naa ni wọn ti fun un ni inagije agbabọọlu to kere ju to si peredege julọ.

O si tun gba ami ẹyẹ La Liga meji ati Copa del Rey ni Barcelona.

Lamine Yamal gba ami ẹyẹ Golden Boy lọdun to kọja, eyi ti wọn n fun agbabọọlu ọmọ ilẹ Europe ti ọjọ ori rẹ ko ti i pe mọkanlelogun.

Ọsẹ to kọja yii ni agbabọọlu naa kọwọ bọwe adehun ọlọdun mẹfa pẹlu ẹgbẹ Catalan.

Adehun naa ti onibiliọnu kan euro tun wa, faaye gba ẹgbẹ agbabọọlu yoowu to ba fẹẹ ra a.

Agbabọọlu márùn-ún àkọ́kọ́ to dára jùlọ

  • Lamine Yamal, ti yoo pe ẹni ọdun mejidinlogun (18) loṣu Keje, ti gba ade lọwọọ Erling Haaland, ẹni ọdun mẹrinlelogun (24), ọmọ agbabọọlu Manchester.
  • £140m lo fi le si i- Ipo keji ni Haaland wa bayii pẹlu €240m (£200m) ti wọn le ra a.
  • Agbabọọlu Real Madrid, Jude Bellingham, ni ọmọ ti wọn n sọ bayii lori atẹ agbabọọlu ilẹẹ Gẹẹsi. 234 million euros (£197m) ni owo rẹ.
  • Kylian Mbappe lo tẹle e, oun jẹ 193 million euros (£162m).
  • Ẹni karun-un ni Jamal Musiala, agbabọọlu Bayern Munich to n gba iwaju fun Germany, 155m euros (£130m) ni wọn le fi ra a.

Agbábọ́ọ́lù mẹ́wàá àti iye wọn

  • Lamine Yamal (Barcelona) £340m.
  • Erling Haaland (Man City) £200m.
  • Jude Bellingham (Real Madrid) £197m.
  • Kylian Mbappe (Real Madrid) £162m.
  • Jamal Musiala (Bayern Munich) £130m.
  • Pedro (Barcelona) £121m.
  • Vinicius Junior (Real Madrid) £109.7m.
  • Cole Palmer (Chelsea) £106.5m.
  • Julian Alvarez (Atletico Madrid) £106m.
  • Florian Wirtz (Bayer Leverkusen) £103m.

Fun agbabọọlu to mọ bi wọn ṣe n da aabo bo ikọ rẹ ju, Pau Cubarsi, agbabọọlu kekere Barcelona ni wọn fun, iye rẹ ni 118 million euros (£99m).

Bart Verbruggen ni wọn fun ni golii to le ju, ọmọ Barcelona yii ni owo rẹ jẹ 64 million euros (£54m).

Florian Wirtz, agbabọọlu German to n gba ipo aarin lo wa nipo kẹwaa.

O ti gbaradi lati darapọ mọ ikọ Premier League champions ni Liverpool, eyi ti afojusun wa pe yoo tobi ju ninu ere bọọlu afẹsẹgba ilẹ Gẹẹsi.