Tanzania fi òfin de X nítorí pé àwọn aráàlú n wo fídíò ìbálòpọ̀ níbẹ̀

Oríṣun àwòrán, NurPhoto /Getty Images
Ijọba orilẹede Tanzania ti fi ofin de lilo oju opo ayelujara X, ti a mọ si Twitter nigba kan, nitori pe o n fi aaye silẹ fun awọn to n lo o lati ma a pin aworan ati fidio ibalopọ.
Minisita fun eto iroyin lorilẹede naa, Jerry Silaa, sọ fun awọn akọroyin pe, o tako ofin, aṣa ati iṣe orilẹede Tanzania.
Lati ọsẹ bi i meji ni awọn ọmọ orilẹede naa ti n pariwo pe, awọn ko ri X lo.
Eyi waye lẹyin rogbodiyan oṣelu kan to ṣẹlẹ, ti awọn kan si gba ọna ẹburu wọ oju opo ileeṣẹ ọlọpaa.
Ajọ kan to n ja fun ẹtọ ọmọniyan sọ pe, nnkan ti Minisita Silaa sọ, jẹ apẹẹrẹ igbesẹ ti ijọba n gbe lati pa awọn araalu lẹnumọ lori ayelujara ni imurasilẹ fun idibo aarẹ ati ti ile aṣofin ti yoo waye ninu oṣu Kejila.
Igba akọkọ kọ ree ti wọn n fi ẹsun kan ijọba Aarẹ Samia Suluhu Hassan, pe lojoojumọ lo n pa awọn eeyan lẹnu mọ nitori erongba lati ṣi wa ni ipo.
Ṣé ó wù ọ́ láti ka ìròyìn nípa ìlẹ̀ òkèrè? Darapọ̀ mọ́ wa ní Whatsapp Channel
Ninu ọrọ kan to kọ si ori X, ajọ Legal and Human Rights Centre (LHRC) sọ pe, bi ijọba ṣe fofin de Twitter naa niyẹn ṣaaju idibo ọdun 2020.
Yatọ si X, awọn eeyan ni Tanzania ko tun raaye lo oju opo ayelujara Clubhouse ati Telegram, ayaafi ti wọn ba lo VPN, gẹgẹ bi ajọ naa ṣe sọ.
O ni nnkan to ba ni lọkan jẹ ni pe minisita naa fidirẹ mulẹ pe, ijọba lọwọ si bi wọn ṣe di oju opo X pa, bo tilẹ jẹ pe awọn alaṣẹ ati ileeṣẹ ijọba ṣi n lo o.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan, Silaa sọ pe awọn fi ofin de X lẹyin ti oju opo naa kede lọdun to kọaj pe, oun ko ni dina mọ ẹni to ba fẹ ẹ fi fidio ibalopọ sita, niwọn igba ti gbogbo awọn to wa ninu rẹ ba jọ panupọ lati ṣe bẹẹ.
Iroyin sọ pe minisita naa sọ pe bi X ṣe faaye gba pinpin fidio ibalopọ, to fi mọ ti ọkunrin si ọkunrin tabi obinrin si obinrin, jẹ nnkan to tapa a si awọn ilan to de lilo ayelujara ni Tanzania.
O ni igbesẹ ti awọn gbe, jẹ ara ọna lati daabo bo awọn to n lo ayelujara, ati lati ri i daju pe, gbogbo awọn ileeṣẹ ayelujara to n "ṣiṣẹ ni orilẹede wa, pa gbogbo ofin wa mọ".
Ogunjọ, oṣu Karun un, ni ileeṣẹ kan to n tọpinpin ayelujara, Netblocks, kede pe X ko ṣiṣẹ ni Tanzania mọ lẹyin ti iroyin jade pe, awọn onijibiti ti a mọ si hacker, ti gbakoso oju opo ileeṣẹ ọlọpaa, ti wọn si fi fidio ibalopọ sita nibẹ.
Bakan naa ni wọn tun kede pe aarẹ ti ku.
Ileeṣẹ iroyin AFP tun sọ pe wọn tun fi fidio ibalopọ si ori ayelujara ileeṣẹ to n gba owo ori.
Ko ti i si ẹni to le sọ awọn to ṣe iru nnkan bẹẹ, amọ iṣẹlẹ naa waye lasiko kan naa ti ijọba gbogun ti awọn ajijagbara ni Kenya ati Uganda, to sa lọ si Tanzania lati ṣe atilyin fun olori ẹgbẹ alatako, Tundu Lissu.
Awọn agbofinro ti fi si ahamọ fun ẹsun iditẹmọjọba lẹyin to sọ pe oun yoo ṣe agbatẹru ipolongo pe ki awọn araalu ma jade dibo, ti ko ba fi si ayipada si ofin lati faaye gba idibo ti ko ni magomago ninu.
Yatọ si oun, awọn agbofinro tun da awọn ajijagbara ati alatilyin rẹ lati Kenya, to fẹ wa si Tanzania lasiko igbẹjọ rẹ, pada si orilẹede wọn.
Aarẹ Samia sọ pe ijọba oun ko ni i fi aaye gba awọn ajijagbara lati awọn orilẹede yooku to w ani Ila oorun Africa, lati ma a da si ọrọ Tanzania tabi da rogbodiyan silẹ.
Samia jogun ipo aarẹ lyin iku Aarẹ John Magufuli lọdun 2021.
Ṣugbọn ṣa, bi awọn kan ṣe n gboriyin fun un pe o faaye gba idọgba lagbo oṣelu, ni awọn ti ko fẹran rẹ n sọ pe o n lo aṣẹ onikumọ bi i Magufuli, paapaa bo ṣe n gbaradi lati dije fun igba akọkọ gẹgẹ bi oludije fun ẹgbẹ oṣelu to wa nipo.
Ijọba sọ pe ipo to dara ni iṣejọba awaarawa wa ni Tanzania, ati pe eto idibo naa yoo lọ lai si magomago kankan.












