Àwọn agbébọn jí ọmọ ilẹ̀ China kan àti èèyàn mí gbé lọ, ṣe olọ́pàá méjì léṣe ní Kwara

Aworan agbebon

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Awọn agbebọn yawọ agbegbe ti wọn ti n wa kusa ni Oreke-Okeigbo nipinlẹ Kwara, ti wọn si ji ọmọ orilẹede China kan ati ọmọ orilẹede Naijiria meji gbe lọ.

Bakan naa ni awọn agbebọn yii tun ṣe ọlọpaa meji lẹsẹ lasiko ikọlu naa.

Sam Xie Wie, ọmọ orilẹede China ati David Adenaiye, lati ipinlẹ Kogi ni wọn n siṣẹ lọwọ nibi ti wọn ti n wa kusa lasiko ti awọn agbebọn yabo wọn.

‎Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ninu atẹjade ti wọn fi lede fun awọn akọroyin fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, ti wọn si ṣalaye pe o waye ni ago mẹfa aabọ ni ọjọ kẹrin oṣu Kẹfa ọdun 2025.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, ‎SP Adetoun Ejire-Adeyemi anipr ni DPO Oreke ṣalaye pe ṣadede ni awọn agbebọn ọhun yawọ ibi ti awọn eeyan naa, ti wọn si sina bolẹ fun awọn ọlọpaa meji to wa pẹlu wọn—ASP Haruna Watsai ati Insipẹtọ Tukur Ogah.

Adeyemi tẹsiwaju pe awọn agbebọn naa tun ko ibọn awọn ọlọpaa naa salọ pẹlu.

Adeyemi ni kọmisana ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara, CP Adekimi Ojo koroju si iṣẹlẹ naa, to si fi da awọn araalu loju pe ọwọ yoo tẹ awọn eeyan laipẹ.

"Awọn ọmọ ogun ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii bayii, ti a o si ri pe ọwọ tẹ awọn eeyan ni kiakia.

Kọmisana wa rọ awọn araalu lati fi ọkan wọn balẹ nitori gbogbo ọna ni ileeṣẹ ọlọpaa yoo fi da abo bo dukia ati ẹmi wọn kaakiri gbogbo ipinlẹ Kwara.

Bakan naa lo fi da awọn araalu loju pe laipẹ awọn yoo foju awọn ọdaran sita fun araaye.