Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Wọ́n ti sin òkú Feranmi Akin-Akinye, ọ̀dọ́mọkùnrin tó jábọ́ láti orí ile alaja pupọ, Cocoa House niluu Ibadan
Iroyin ni fasiti Afe Babalola, to wa niluu Ado Ekiti, ni oloogbe ọhun ti jade
Ko to maa kẹkọọ nipa imọ "cybersecurity" ni aja kẹjọ Cocoa House ṣaaju iṣẹlẹ laabi naa
A gbọ pe akọle kan ni oloogbe ọhun lọ so mọ ori Cocoa House ko to jabọ
__________________________________
Aarẹ Naijiria, Bola Tinubu ti buwọlu biliọnu meji naira fun atunṣe agbegbe Mokwa ti agbara omi ti ṣọṣẹ lọsẹ to kọja
Igba-keji aarẹ, Kashim Shettima, lo kede eyi lasiko to ṣabẹwo si ijọba ibilẹ Mokwa ti omi ti gbe ọpọ eeyan lọ nipinlẹ Niger
Awọn alaṣẹ ni o le ni igba eeyan to ba iṣẹlẹ naa lọ
_________________________________
Aarẹ Amẹrika, Donald Trump ti fofin de orilẹede mejila pe awọn ọmọ ilẹ rẹ ko gbọdọ wọ Amẹrika mọ
Atẹjade lati White House ni eredi igbesẹ ọhun ko ṣẹyin bi awọn ọmọ ilẹ okere ṣe n wuwa ọdaran l'Amẹrika
Lara awọn orilẹede ti ọrọ naa kan ni Libya,Somalia, Sudan, ati Yemen
Awọn orilẹede to ku nkọ?