'N400, 000 sí 800,000 là n ra àgbò fún Ileya'

Bi awọn Musulumi kaakiri agbaye ṣe n gbaradi fun ayẹyẹ ọdun ileya eyi ti yoo waye lọla ọjọ Ẹti, BBC Yoruba ṣabẹwo si awọn ọja nipinlẹ Osun, Kwara, ati Oyo lati mọ bi ẹran ṣe gbowo lori si ati bi awọn eniyan se jade si lati ra ẹran.
A ri wi pe, bi awọn onibara ṣe n ra ẹran agbo lawọn kan n ra ẹran maluu ti awọn miran si n ra ẹran rakunmi.
Gbogbo awọn ẹlẹran ti a fọrọ wa lẹnu wo lo sọ wi pe ẹran wọn lọdun yii ju ọdun to kọja lọ.
Niluu Ilorin to jẹ olu ilu ipinlẹ Kwara, awọn oniṣowo ni ohun to fa bi owo ẹran agbo ṣe lọ soke ni wi pe, ibi ti awọn ti n ko ẹran naa wa jina, owo ọkọ si wọn bẹẹ si ni ijọba tun n gba owo ori lọwọ awọn.
Ontaja ẹran agbo kan, Ọgbẹni Ibahim ṣe lalaye pe, ara idi ti ẹran fi wọn ni pe, awọn eniyan ni ipinlẹ Kwara kii sin ẹran agbo daada, to si jẹ pe oke Ọya ni awọn ti n ko ẹran agbo wọle.
O ni bo tilẹ jẹ wi pe maluu tobi ju ẹran agbo lọ, odinwo si agbo nitori awọn eeyan n sin maalu ni Kwara, awọn si n ri ra, ati pe laada ẹran agbo ju ti maluu lọ.
O ni lotitọ ni ọja o ya bo se yẹ ko ri, sugbọn awọn dupẹ lọwọ Ọlọrun nitori olukaluku n ta ọja tirẹ niwọn ba, awọn si n ri owo mulọ sile.
Awọn onibara ti o ba wa sọrọ sọ ọ di mimọ pe, ẹran wọn gan-an lọdun yii, sugbọn awọn ko le ba awọn ontaja ẹran wi pupọ nitori bi ilu ṣe ri.
Iwadii wa lọja naa fihan pe, ẹni to ba fẹ ra ẹran agbo gbọdọ ni okere tan N160,000 lọwọ ko to le ri ẹran to wọ ileya ra.
Ẹran agbo mii wọ N800,000, ti iye ti wọn n ta awọn miran si le ni miliọnu kan naira, awọn ẹran maluu naa wa nibẹ ni orisirisi iye.
Ẹran rakunmi naa o gbẹyin lọja naa, owo rẹ si bẹrẹ lati miliọnu meji naira lọ soke.

'Afara ilu Mokwa to ba omi lọ lo fa a ti ẹran ṣe won f'ọdún Ileya'
Nise ni awọn olugbe ilu Ibadan to fẹ ra ẹran ọdun fun ileya n ṣe haa nitori bi awọn ẹran naa ṣe gbowo lori ju ti ọdun to kọja lọ.
Akọroyin ileeṣe BBC to ṣe abewo si ọja Aleshinloye to wa n'ilu Ibadan fidi rẹ mulẹ wi pe ọpọ awọn ẹran agbo to tobi ni wọn n ta ni N700, 000, awọn to kere diẹ ni wọn ta ni N450,000, N350, 000, ati N270,000.
Ninu iwadii akọroyin BBC Yoruba, awọn ẹran rago ti ọpọ eeyan mọ si musoro ni wọn n ta ni N170, 000, N120,000.
Wọn n ta maalu ni miliọnu kan le diẹ ti awọn miran si n ta ti wọn ni N950,000,N750,000 àti bẹẹbẹẹ lọ.
Lara awọn ontaja to ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye wi pe, afara kan to wa niluu Mokwa nipinlẹ Niger ti ẹkun omi jaa, lo faa ti awọn ẹran ṣe gbowo lori nitori awọn to nko ẹran bọ lati Ariwa Naijiria ti haa siluu Mokwa.
Awọn miran sọ pe ọwọn gogo epo ati bi gbogbo ounjẹ ṣe wọn lo faa ti awọn ẹran naa fi gbowo lori.
Lara awọn to wa ra ẹran agbo ni, iyalẹnu lo jẹ nigbati ohun ri wi pe iyatọ ti de ba bi wọn ti n ra ẹran lọdun yii.
O ni ẹran agbo nla tohun ra lọdun to kọja ni wọn taa ni N170, 000 sugbọn lọdun yii ilọpo meji ti ọdun to kọja ni ohun baa ẹran.
Ẹlomiran ni, bii ẹran agbo ṣe wọn lọdun yii gbenutan nitori wi pe owongogo ẹran agbo yii ko ni jẹ ki ọpọ musulumi ra ẹran, oni ọpọ iyatọ lọba iye ti wọn ra ẹran lọdun yii.
Ọpọ awọn musulumi to wa ra agbo fun ọdun Ileya lo bẹ Aarẹ Bola Ahmed Tinubu lati mu adinku ba owo epo bẹtiro ki ọwọngogo ounjẹ ati ẹran le wa ju ti ọdun yii lọ.
Ẹran agbo fun ọdun ileya pọ ni ọja sugbọn ko si onibara. Yẹkinni Oyeniyi

BBC Yoruba kan si ọja Temidire ni agbegbe Stadium niluu Osogbo nipinlẹ Osun lati mọ bi wọn n ṣe ta ẹran ọdun ileya ati bi awọn musulumi ọlọdun ṣe ra ẹran naa.
Ẹkọ ko soju mimu fun awọn ọlọdun lọdun yii, latari bi ẹran agbo ọdun ko ṣe ṣe e doju kọ lati ra fun ọdun ileya.
Yekinni Oyeniyi, ẹni to jẹ igbakeji alaga awọn ẹlẹran ni ọja Temidire nibi ti wọn ti n ta ẹran agbo fun ọdun ileya, sọ pe owo ẹran agbo ni ọdun yii gbẹnu soke ju ọdun to kọja lọ.
Yekinni, tun fi kun ọrọ rẹ pe, awọn si ni ireti pe awọn eeyan yoo si wa fun ẹran lati raa fun ọdun ileya. Nitori awọn n to lọ si ọdọ awọn Hausa lati ra ẹran pọ ju awọn n to wa si ọdọ awọn Yoruba lati ra ẹran lọ. Oni awọn ni igbagbọ pe awọn naa yoo ta ẹran ta awọn naa.
Ni ọja Temidire nibi ti wọn n ti ta ẹran agbo. Owo ẹran agbo to kere ju ni Ẹgbẹrun lọna ọtalelugba o din mẹwaa naira (250,000).















