Ǹ jẹ́ èèyàn lè jẹ ànàmọ́ tàbí àlùbọ́sà tó ti ń hù? Àlàyé rèé

Aworan anamọ ati alubọsa to ti n hu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Nazanin Motamedi
    • Role, BBC Persian
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ti o ba n dana ounjẹ alẹ ti o kan ṣadeedee ri pe anamọ ti o fẹ se ti n hu, n jẹ o si le se anamọ naa? Abi ṣe wa a da a nu ni?

Iru nnkan yii maa n ṣẹlẹ, ero awọn eeyan si ṣe ọtọọtọ lori rẹ.

Amọ, ko si idahun kan gboogi lori bo ya eeyan le jẹ ewebẹ bii alubọsa tabi garlic to fi mọ anamọ to ti n hu.

Ki lo maa n ṣẹlẹ si anamọ to ti n hu?

Bi anamọ ba ti bẹrẹ si ni hu, eyi tumọ si pe o fẹ di igi tuntun pada niyẹn.

Lasiko yii ni kẹmika kan ti orukọ rẹ n jẹ glycoalkaloids maa n jade lati ara anamọ eyi to maa n fi daabo bo ara rẹ lọwọ awọn kokoro to le ṣakoba fun un.

Lara awọn kẹmika naa ni Solanine naa wa, eyi si maa n wa lara awọn ewebẹ mii naa bii tomato ati ata.

Kikore ati fifi awọn nnkan yii pamọ le jẹ kawọn kẹmika yii pọ lara wọn, eyi si le ṣakoba fun agọ ara eeyan atawọn ẹranko.

Ṣe eeyan le jẹ awọn ewebẹ to ti n hu?

Ọmọwe Chris Bishop to jẹ onimọ nipa imọ ijinlẹ lori ikore oko ni fasiti Lincoln sọ pe ''ewu to wa ninu anamọ to ti n hu ni kẹmika ti wọn n pe ni glycoalkaloids, eyi lo maa n jẹ ki iru anamọ bẹẹ koro lẹnu.

O maa n ṣe iru ẹni to ba jẹ iru anamọ bẹẹ bi ẹni pe yoo bi i.

Idi niyii ti ko fi dara lati maa jẹ anamọ to ba ti lawọ ewe lara.''

Ọmọwe Bishop ni o yẹ ki eeyan ge ibi to ti n hu kuro tori ibẹ ni kẹmika to le ṣakoba fun ara maa n wa.

Olukọni fasiti naa ni eyi to ba ku lara anamọ naa dara fun jijẹ ti eeyan ba ti ge ibi to n hu kuro.

Aworan ọwọ to n bẹ anamọ

Oríṣun àwòrán, Shutter Stock

Ajọ FSA to ṣamojuto ounjẹ jijẹ ni UK naa ti sọ pe eeyan le jẹ anamọ to ti n hu ti eeyan ba le gbe awọn igbesẹ kan.

Ajọ FSA ṣalaye pe ''ti eeyan ba ti ge ibi to n hu lara anamọ naa tan, eeyan le se eyi to ku jẹ ti ko ba tii maa jẹra.

Ṣugbọn ti ara anamọ ba ti n ni awọn ewe, o san ki eeyan ju u nu tori kẹmika to le ṣakoba fun ara maa n wa nibi to ba ti n ni awọ ewe.

Eeyan le jẹ anamọ to ba ti n hu ti ko ba tii rọ lọwọ tori anamọ to ba ti rọ lọwọ ko le ṣe anfaani kankan fun ara mọ.''

Aworan obinrin to mu anamọ to ti hu dani

Oríṣun àwòrán, Shutter Stock

Kẹmika 'Solanine'

Ọjọgbọn Cathie Martin ti Fasiti East Anglia kilọ pe ki ẹnikẹni ma jẹ anamọ to ti n hu.

Ọjọgbọn Martin ni iru anamọ bẹẹ maa n ni kẹmika glycoalkaloid ati solanine lara eyi to le ṣakoba fun agọ ara eeyan atawọn ẹranko bii ologbo ati aja.

Bo tilẹ jẹ pe ko wọpọ, iṣẹlẹ kan waye lorilẹede UK lọdun 1978 nigba tawọn akẹkọọ kan dero ile iwosan lẹyin ti kẹmika solanine ṣe ipalara fawọn akẹkọọ naa to jẹ iru anamọ bẹẹ.

Awọn apẹẹrẹ tawọn eeyan to ba jẹ iru anamọ bayii maa n ri ni eebi, igbẹ gbuuru ati inu rirun.

Eyi tun le fa ki oyi maa kọ eeyan, o tun le jẹ ko maa rẹ eeyan tabi ki ẹni naa ma riran daadaa mọ.

Koda, o ṣee ṣe ki eeyan gba ibẹ ku tori akọsilẹ fi han pe jijẹ iru anamọ yii ti ṣeku pa awọn eeyan ri.

Aworan anamọ to ti n hu

Oríṣun àwòrán, Shutter Stock

Imọran nnkan ti o le ṣe lori anamọ to ti n hu

  • Ge ibi to ti n hu lara anamọ rẹ kuro
  • Da anamọ rẹ nu ti ibi to ba ti n hu ba pọ gan an tabi ti anamọ ọhun ba ti rọ lọwọ
  • Ranti lati ge ibi to ba ti n yọ awọ ewe kuro lara anamọ ti o fẹ jẹ, nibẹ ni kẹmika to lewu maa n wa
  • Ti o ba ti ri pe anamọ ti o fẹ se ti n jẹra, tete da a nu
  • Ṣe pẹlẹ ti o ba fẹ gbin anamọ to ti n hu, o ṣee ṣe ki o fọwọ ṣeṣe, kokoro si le gbe ibẹ wọ inu ara rẹ

Ti o ba loyun, tabi ti o n fawọn ọmọde lounjẹ, o ṣe pataki fun ọ lati tẹle imọran to wa loke.

Aworan anamo ati alubọsa ninu apẹrẹ

Oríṣun àwòrán, Shutter Stock

Wo bi o ṣe le ko anamọ pamọ

  • Tọju anamọ rẹ sibi ti ko si ooru bii inu kọnbọọdu
  • Ma ṣe ṣan anamọ ki o to ko o pamọ tori o maa n tete hu ti omi ba wa lara rẹ
  • Ma ṣe ko anamọ pọ mọ alubọsa tori awọn kẹmika to n jade lara awọn mejeeji lo jẹ ki wọn tete maa hu

Mọ nipa alubọsa ati galiiki to n hu

Ọjọgbọn Martin fi idi rẹ mulẹ pe eeyan le jẹ alabọsa tabi galiiki to ti n hu.

O ni iru alubọsa tabi galiiki bẹ ko ni kẹmika kankan to le ṣakoba fun eeyan lara rara.

Ọjọgbọn Martin sọ pe lati inu mudunmudun to wa ninu iru alubọsa bẹẹ lo ti maa n hu jade.

Amọ, Ọjọgbọn Martin ni nnkan to wa nibẹ ni pe o le kuro lẹnu tabi ko rọ.

Awọn onimọ nipa ewebẹ sọ pe o dara lati tọju alabọsa ati galiiki sibi ti ko si oorun.

Wọn ko dara lati fi alubọsa pamọ sinu ọra tabi sinu ike tori atẹgun ko ni raye wọ ibẹ.

Bakan naa ni wọn sọ pe alubọsa tabi galiiki to ba ti rọ ko dara fun jijẹ mọ.