Àwọn aláṣẹ fi ìkìlọ̀ síta fún àwọn arìnrìnàjò Hajj 2025

Ẹni to n kirun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn arinrinajo mimọ fun Hajj ọdun 2025 ti bẹrẹ awọn iṣẹ isin to gbe wọn lọ ni Mecca, Saudi Arabia.

Hajj jẹ iṣẹ isin to gba ọpọlọpọ irin ati awọn iṣẹ agbara, eyi to ti mu ki awọn alaṣẹ Saudi Arabia lati fi ikede sita nipa ooru amuju to ma n wa ni orilẹede naa lasiko Hajj.

Ajọ alalaaji ni Saudi sọ pe ooru to n mu wọ 45 degrees Celsius lasiko ti Hajj n waye.

Ninu atẹjade ti wọn fi sita loju opo ayelujara wọn, wọn ni ooru naa lewu pupọ, eyi to le mu ki eeyan o daku, to si le la ẹmi lọ.

O to miliọnu meji eeyan to ma n lọ fun Hajj lọdọọdun lati orilẹede agbaye lati ṣe awọn iṣẹ isin bii sisọ oko mọ asitaani, gigun oke Arafa ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Oorun to n mu ni Saudi Arabia ma n gbona to 45 degrees Celsius, to si ma n gbona to 50 degrees Celsius ni awọn agbegbe kan.

Eyi ko ṣẹyin bi Saudi Arabia ṣe wa ninu aginju Arabian desert.

Nitori eyi, ileeṣẹ to n mojuto Hajj ti fi awọn ilana sita fun awọn arinrinajo, lati fi daabo bo ilera wọn.

Duro labẹ atibaba

Ẹni to n kirun labẹ atibaba

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Imọran akọkọ ti wọn fi sita fun awọn arinrinajo ni pe ki wọn o duro ni abẹ atibaba lasiko ti ooru ba n mu ni ọsan.

Wọn sọ ninu atẹjade naa pe, ki wọn o ma ṣe kuro ni abẹ atibaba naa laarin aago mẹwaa owurọ si mẹrin ọsan.

Aarin asiko yii ni oorun ma n mu ju, ti ayika si ma n gbona janjan.

Irun Zuhr ati Asr

Lasiko irun Zuhr ati Asr, imọran ti awọn alaṣẹ Saudi fun awọn arinrinajo ni pe, ki wọn o yago fun lilọ si mọṣalaaṣi Namirah ati Jabal Al-Rahma.

Dipo bẹẹ, ileeṣẹ Hajj sọ pe ki wọn o duro labẹ atibaba wọn lati kirun un.

Lilo ọkọ

Awọn to wa ninu ọkọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn alaṣẹ rọ awọn arinrinajo Hajj pe, ki wọn o lo awọn eto irinna ti awọn alaṣẹ pese bii bọọsi ati ọkọ oju'rin, lati de Muzdalifah.

Muzdalifah jẹ ibi aaye to fẹ nitosi ilu Mecaa, nibi ti awọn arinrinajo ti ma n ṣe iṣẹ isin ni orumọju.

Fifi nnkan bori

Awọn to fi nnkan bori ninu oorun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Imọran miran tun ni pe ki awọn eeyan naa fi fila ati ibori awọn obinrin bo ori wọn. Eyi ni wọn ni yoo daabo bo wọn lọwọ oorun.

Lilo ibori ni awọn alaṣẹ sọ pe yoo dena mọ oorun ko ma ba a ṣe idiwọ fun awọn eeyan lati ṣe iṣẹ isin wọn.

Omi mimu

Ni ipari, dandan ni fun awọn arinrinajo lati ma a mu omi ati awọn nnkan ẹlẹrindodo lọpọlọpọ nitori ongbẹ.

Omi mimu ma n rọpo awọn eroja ara bii òógùn to n jade ninu ara lasiko ere idaraya tabi irin, to si tun ma n mu adinku ba aarẹ ara tabi ki eeyan o daku.