Nǹkan márùn-ún tó ṣe é ṣe kí o má mọ̀ nípa Hajj

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Hajj jẹ iṣẹ mimọ fun awọn ẹlẹsin Islam, ti o si le ni miliọnu meji eeyan to ma n kora wọn jọ si ilu Mecca lorilẹede Saudi Arabia lati ṣe ijọsin lọdọọdun.
Ọkan lara opo marun un ẹṣin Islam ni Hajj jẹ, ti o si jẹ dandan fun Musulumi to ba ni agbara rẹ lati ṣe, o kere tan ẹẹkan ni igbesi aye rẹ.
Hajj jẹ ọkan ninu ipejọpọ awọn ẹlẹṣin to pọ julọ lagbaye, ti ọpọ eeyan si n wa si Mecca lati origun mẹrin agbaye lati ṣe iṣẹ Hajj.
Ilu Mecca jẹ ilu ti wọn ti bi Anọbi Muhammad ati ibi to ti tẹwọgba iwe mimọ Alkurani.
Ilu yii ni ibudo fun Kaaba, ti awọn kan gbagbọ pe ibẹ lo mọ julọ lagbaye .
Eyi ni awọn ohun marun un to jẹ iyalẹnu ti o ko mọ nipa Hajj.
Kaaba - ohun igbagbe ti Anọbi Ibrahim
Iṣẹ Hajj ọdọdun jẹ ọkan lara opo Islam, bo ti jẹ pe idarinjin le wa fun ẹnikẹni to gbagbọ pe ẹṣin da lori Anọbi Muhammad, oludasilẹ ẹṣin naa.

Oríṣun àwòrán, EPA
Ẹwẹ, iṣẹ Hajj yii ti bẹrẹ lati igba aye Anọbi Ibrahim, ẹni ti igbagbọ wa pe oun lo kọ Kaaba ọhun.
Iṣẹ Hajj da lori bi o ṣe fẹ fi ọmọ rẹ ọkunrin se etutu fun Allah lati ti le fi ara jin fun un.
Anọbi Ibrahim, ni ọpọ mọ si Abraham ni ẹṣin Kritẹni ati Judaism, to si jẹ eeyan pataki fun ẹṣin mejeeji.
Ko si iyapa laarin akọ ati abo

Oríṣun àwòrán, Yassine Gaidi/Anadolu Agency
Bi awọn opo yooku ṣe tako ki akọ ati abo jọ wa papọ lasiko ijọsin, bi ti mọsalasi, ko si iru eyi lasiko Hajj laarin ọkunrin ati obinrin.
Imura to yaayi
Awọn to lọ si Mecca ni ilana aṣọ to yẹ ki wọn tẹle lasiko Hajj eyi to ṣafihan idọgba ati mimọ.

Oríṣun àwòrán, EPA
Awọn ọkunrin ma n wọ aṣọ funfun bi ọpa meji, ti wọn pe ni Ihram, to tumọ si idọgba awọn onigbagbọ lai wo ipo ti eeyan naa wa.
Awọn obinrin kii wọ aṣọ funfun bi ti awọn ọkunrin ṣugbọn wọn ma n wọ nnkan ti yoo bo ara wọn.
Wọn yoo bori ṣugbọn wọn le ṣi oju wọn silẹ.
Gigun Oke
Ọkan lara iṣẹ pataki Hajj ni Tawaf, to ni i ṣe pẹlu yi yi Kaaba ka ni igba meji. Ibẹrẹ iṣẹ Hajj ati ni opin rẹ ni eyi ma n waye. Ṣugbọn n jẹ o mọ pe ọna miiran wa to ni ṣe pẹlu gigun oke?
Lara iṣẹ Hajj ni siṣe abẹwo ati rinrin ni igba meje laarin oke Safa ati Marwah, eyi to wa ni Masjid al-Haram.
Eyi lo wa fun iranti inira Hajar, iyawo Anọbi Ibrahim, to ṣa lati oke mejeeji ni igbiyanju lati wa omi fun ọmọ rẹ.
Oke Arafat
Kaaba jẹ iṣẹ pataki ninu iṣẹ Hajj, bakan naa ni Oke Arafat, to wa ni ita Mecca.

Oríṣun àwòrán, EPA
Awọn eeyan yoo tu sita lati igba ti oorun ba ti jade, ti wọn yoo si ma a gba adura, kika Kurani ati awọn nnkan miiran fun adura.
Agbegbe yii jẹ agbegbe to ṣ pataki fun Islam. Gẹgẹ bii igbagbọ Islam, ibi yii ni Anọbi Muhammad ti ṣe iwaasu ikẹyin rẹ.












