Ta ló lẹ́tọ̀ọ́ láti pa ẹran Ileya?

Àwòrán àwọn ẹran àgbò níbi tí wọ́n ti ń tà wọ́n

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Àgbò ni wọ́n sọ pé ó dára jùlọ láti pa fún Ileya
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́, ọdún Ileya tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó gbajúmọ̀ nínú ẹ̀sìn Islam ń wọlé dé.

Ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kẹfà ni ọdún Ileya 2025, tó máa ń wáyé ní ọjọ́ Kẹwàá, oṣù Dhul Hijjah, tó jẹ́ kajọ́ kaṣù àwọn mùsùlùmí, bọ́ sí.

Ọdún Ileya jẹ́ èyí táwọn Mùsùlùmí ti máa ń pa ẹran àgbò, màlúù tàbí ràkúnmí ní ìràntí Ànọ́bì Ibrahim tí Ọlọ́run pa láṣẹ láti fa ẹ̀mí ọmọ rẹ̀, Ismail sílẹ̀ fún ìrúbọ ṣùgbọ́n tí Ọlọ́run padà rán Áńgẹ́lì sí i pẹ̀lú àgbò láti fi rọ́pò ọmọ náà níbi tó ti fẹ́ pa á.

Ileya jẹ́ ọdún tó ṣe pàtàkì sáwọn Mùsùlùmí nítorí òhun ni wọ́n kà kún ọdún ńlá níbi tí wọ́n ti máa ń pa ẹran àgbò.

Ta ló yẹ kó pa ẹran Ileya? Ṣé ẹ̀ṣẹ̀ wà níbẹ̀ fún ẹni tí kò bá pa ẹran? Kí ni ẹni tó bá fẹ́ pa ẹran gbọdọ̀ ṣe?

Gẹ́gẹ́ onímọ̀ nípa ẹ̀sìn Islam, Imam Tukur Adam Almannar ṣe sọ, àgbò pípa lásìkò ọdún Ileya kìí ṣe dandan àmọ́ tó ṣe pàtàkì fáwọn tó bá ní ìkápá láti ṣé.

Ọ̀kan lára àwọn Sunnah tí kìí ṣe ọ̀rayàn ni àgbò pípa lásìkò ọdún Ileya jẹ́.

Imam Almannar sọ pé òjíṣẹ́ Ọlọ́run, Muhammad kìí jẹ́ kí ọdún Ileya lọ láì pa àgbò méjì - ọ̀kan fún ìdílé rẹ̀ àti ọ̀kan fáwọn èèyàn rẹ̀.

Ta ni ó pọn dandan fún láti pa ẹran Ileya?

Orí ẹran àgbò àti èèyàn tó mu dání

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Sheikh Tukur Almannar ṣàlàyé gbogbo mùsùlùmí yálà lọ́kùnrin tàbí obìnrin tó bá ti bàlágà, tí kò sí ní àhámọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n tó sì ní ìkápá láti ra ẹran ọdún ní ó pọn dandan fún láti pa ẹran.

Èyí túmọ̀ sí pé gbogbo mùsùlùmí tó bá ní iṣẹ́ gidi lọ́wọ́, tó ń fun lówó láti gbọ́ bùkátà tó sì ń ṣẹ́kù fún un ló lẹ́tọ̀ọ́ láti pa ẹran Ileya.

Onímọ̀ náà fi kun pé kò sí ìyàtọ̀ láàárín irú ẹran tí ọkùnrin tàbí obìnrin le pa tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ẹran Ileya.

Ta ni kò le pa ẹran Ileya?

Gẹ́gẹ́ bí Imam náà ṣe ṣàlàyé, àwọn kan wà tó jẹ́ pé wọn kò lẹ́tọ̀ọ́ láti pa ẹran Ileya.

Sheikh Almannar sọ pé kò tọ́ sí ẹni tí kìí bá ṣe mùsùlùmí láti pa ẹran Ileya. Ó ní ẹni tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ kàn pa ẹran fúnra rẹ̀ ni, a ò lè pe ẹran bẹ́ẹ̀ ní ẹran Ileya.

Bákan náà ló ní kò tọ́ fún ọmọdé tí kò ì tíì bàlágà láti pa ẹran Ileya nítorí ọjọ́ orí rẹ̀ ṣì kéré.

Bẹ́ẹ̀ náà ni Islam kò fàyè sílẹ̀ fún ẹni tó bá jẹ́ ẹrú láti pa ẹran Ileya gẹ́gẹ́ bí Sheikh náà ṣe sọ.