Oro mọkin, ìlú tó ní ẹkùn mọ́kànlá àmọ́ tí ọba alayé kan ṣoṣo n darí wọ́n láì sí ìyọnu

Àkọlé fídíò,
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ẹwure Oro nii jẹ lẹsẹ gbagede

Agutan Oro nii jẹ lẹsẹ yara

Adiyẹ okoko lo ti ko mii de

Bojumọ ba mọ, a maa jẹ ni popo Ọlọfian

Ṣẹ mọ pe Olofian ni akunlẹbọ gbogbo wa

Aja o ṣihan ṣẹyin lode Oro makin

Agbo o ṣihan sin rọrọ

Aja ti o ni rọrọ ni ka lọ le kagbo wa

Ka mu lọ popo Olofian

Ṣẹ mọ pe Olofian ni akunlẹbọ gbogbo wa

Oro mọkin

O mọjọ

Ajoji ni i kẹta ilu ọmọ Olofian

Ka sọ diẹ, ka dakẹ ninu oriki ilu Oro.

Ilu Oro

Ẹ tun kaabo sori eto e kalọ si ilu mi, eto kan lori ikanni BBC News Yoruba, nibi ti a ti maa n ṣe agbeyẹwo aṣa, iṣe, itan ati ohun to yatọ nipa awọn ilu to wa nilẹ Yoruba.

Ilu kan to gbajumọ pupọ ni ilu Oro, eyi to wa ni ijọba ibilẹ Irepodun, nipinlẹ Kwara.

Nilẹ Yoruba, ọpọ abule ni wọn kii gba funra wọn ti wọn si maa n fi ọrọ wọn koko n jabele ti kaluku yoo maa ṣe tirẹ, to ba ti to asiko lati yan ọba tabi baalẹ.

Amọ fun awọn eeyan ilu Oro, ọna to yatọ ni wọn fi n sẹ ijọba.

Ẹkun mọkanla lo parapọ ti wọn n pe ni Oro - Agbe Ola, Iludun, Aafin, Ijomu, Oke Ola, Okerimi, Iddo, Irebode, Sie, ati Olorunsogo ni ẹkun mọkanla to gbe ilu Oro.

Ọba kan ṣoṣo ni wọn ni to n dari gbogbo wọn, bi o tilẹ jẹ pe ẹkun kọọkan lo ni baalẹ ti wọn. Bawo lo ṣe jẹ ati pe boo gan ni wọn ṣe tẹ ilu Oro do?

Ẹkun mọkanla lo wa niluu Oro

Bawo ni wọn ṣe n ṣe iṣakoso niluu Oro?

Oba Joel Oyatoye

Oloro ti ilu Oro, Oba Joel Oyatoye, sọ fun BBC Yoruba pe, Oyolola to jẹ babanla awọ, wa lati ilu Oyo, to si tẹdo si ibi to di ilu Oro lonii.

"Nigba to n bọ, oriṣiriṣi awọn eeyan to wa lati mọlẹbi ọtọọtọ lo ko dani, paapaa bo ṣe jẹ pe ọmọ ọba ni.

"Awọn eeyan to ko dani nigba naa la n pe ni Mọkin lode oni."

Gẹgẹ bi kabiesi Oloro ṣe ṣalaye, lẹyin ti Oyolola ati awọn eniyan rẹ tẹdo tan, ni awọn ajeji lati awọn ilu miran darapọ mọ wọn.

Awọn ajeji naa mu agbegbe ọtọọtọ ti wọn n gbe, ti ọkọọkan wọn si ni baalẹ to n dari wọn.

Awọn baalẹ yii n jabọ fun Oloro to jẹ olori patapata fun gbogbo awọn ẹkun mọkanla naa.

Awọn nnkan pataki to wa niluu Oro

Ẹkun kọọkan lo ni Baalẹ niluu Oro, amọ Oloro ni olori fun gbogbo wọn
Àkọlé àwòrán, Ẹkun kọọkan lo ni Baalẹ niluu Oro, amọ Oloro ni olori fun gbogbo wọn

Gẹgẹ bi ti ilẹ Yoruba yooku iṣẹ oko, ọpẹ dida, aṣọ hihun jẹ iṣẹ tawọn eeyan Oro yan laayo laye atijọ.

Yatọ si eyi, wọn tun maa n rin irinajo kaakiri ti ọpọ wọn kii si gbele eyi lo fa a tawọn kan fi maa n powe pe Oro a gbe alejo ju onile lọ.

Bi o tilẹ jẹ pe ẹsin igbagbọ ati Islam lọpọ eeyan n sin niluu Oro sibẹ wọn ko gbagbe ojubọ awọn babanla wọn.

Ọdun Ọlọfian ni ẹsin ibilẹ ti wọn n sin nilẹ Oro.

Ṣaaju asiko yii, ilu Oro ni ileeṣẹ ti wọn ti n to ọkọ Peugeot ni ipinlẹ Kwara wa, ileeṣẹ ipese ohun itanna, candle àti ileeṣẹ ti wọn ti n fọ okuta naa ti figba kan ri wa niluu Oro ṣugbọn tawọn ileeṣẹ naa ti kogba sile bayii.

Ẹkọ iwe kika gbajumọ niluu Oro, ọpọ awọn ile ẹkọ lo wa niluu Oro lara rẹ ni Oro Grammar ati ilẹ ẹkọ olukọni ijọba ipinlẹ Kwara.

Bi gbogbo ilu Oro ṣe tobi to ọja ọjọ marun-un maru-un ni wọn maa n na to si jẹ pe kaakiri ilẹ Yoruba ni wọn ti maa n wa na ọja naa.

Ọja Ọbada niluu Oro

Yoruba bọ wọn ni iyan l'ounjẹ, ọka loogun airi rara la n jẹkọ, iyan ati ẹgusi ni ounjẹ awọn ara ilu Oro.