Tinubu buwọ́lu N2bn fún àtúnṣe agbègbè Mokwa tí ẹkùn omi bàjẹ́

Ile to le ni ẹgbẹrun meji ni omi wọ lọ
Àkọlé àwòrán, Ile to le ni ẹgbẹrun meji ni omi wọ lọ niluu Mokwa, nipinlẹ Niger
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Aworan Aarẹ Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Facebook.com/officialasiwajubat

Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Tinubu ti buwọlu biliọnu meji naira fun atunṣe agbegbe Mokwa ti ẹkun omi ṣe ijamba fun ni apa ariwa orilẹede naa.

Igba-keji aarẹ, Kashim Shettima, lo kede eyi lasiko to ṣe abẹwo si ijọba ibilẹ Mokwa nipinlẹ Niger lẹyin iṣẹlẹ ẹkun omi to ba ọpọ dukia jẹ, ti ọpọ eeyan si padanu ẹmi wọn.

Shettima ni, aarẹ tun ti paṣẹ pe ki wọn gbe ounjẹ wọ ilu naa fun awọn eeyan ti ijamba naa ṣọṣẹ fun un.

Iye eeyan to ti padanu ẹmi wọn lori iṣẹlẹ yii lo ti le ni igba gẹgẹ bii ohun ti awọn alaṣẹ gbe sita.

Agbẹnusọ ajọ NEMA, Musa Kimboku, sọ fun BBC pe, o le ni eeyan 500 mii to ti sọnu ni ilu, ati pe igbiyanju n lọwọ lati ṣawari awọn eeyan naa.

Koko lati ibi abẹwo igbakeji aarẹ Kashim Shettima si Mokwa

Lasiko abẹwo naa, Igbakeji Aarẹ, Shettima wo itu ti ẹkun omi naa pa, ati bi o ṣe ba ọpọ nnkan oko jẹ ni ilu naa.

Shettima ni abẹwo oun tumọ si pe ijọba yoo gbe igbesẹ ni kiakia lori ijamba omi, ti Aarẹ Tinubu si palaṣẹ pe ki atunṣe bẹrẹ ni loju ẹsẹ.

O wa fi da awọn araalu loju pe aarẹ ni ifẹ wọn lọkan, ti ijọba rẹ yoo si wa ojutu si iṣoro to n koju wọn.

"Aarẹ lo palaṣẹ fun pe ki n wa si Mokwa lati ba awọn eeyan kẹdun lori ohun to waye. Ọkan aarẹ wa pẹlu ẹyin eeyan Mokwa.

"Ijọba apapọ yoo yanju gbogbo iṣoro ti ẹ n koju ati awọn ti ẹ ti pe akiyesi ijọba si.

Shettiman ni Aarẹ Tinubu ti paṣẹ ki wọn se atunṣe si awọn afara to ja lasiko ẹkun omi naa.

Bakan naa lo ni Aarẹ ti paṣẹ pe ki wọn la ọna fun omi lati ma kọja ni agbegbe naa ni kiakia.

Yakubu Garba, igbakeji gomina ipinlẹ Niger wa bẹ ijọba apapọ pe ki wọn tete gbe igbesẹ lori ipa ti ẹkun omi naa fa si agbegbe naa.

"A nilo iranlọwọ oni kiakia, awọn afara mẹrin wa lo ja lulẹ, to si ti di ọna ijẹ ọpọ duro paapa Rabba, awọn akẹkọọ o le kọja lasiko ojo.

Garba sọ pe o le ni ẹgbẹrun meji ile ti ẹkun omi dawo lulẹ, to si sọ ọpọ di ẹni ti ko ni ile lori.

O fikun pe ijọba ipinlẹ ni ilẹ ti wọn le pese fun ijọba lati fi kọle fun awọn eeyan.

Àwọn aláṣẹ kò tí ì lè sọ ìdí ẹ̀kún omi yìí

Ọgbẹni Yusuf ree, o padanu iyawo rẹ ati ọmọ tuntun to ṣẹṣẹ bi sinu ẹkun omi naa to gba gbogbo ilu kan.
Àkọlé àwòrán, Ọgbẹni Yusuf ree, o padanu iyawo rẹ ati ọmọ tuntun to ṣẹṣẹ bi sinu ẹkun omi naa to gba gbogbo ilu kan.
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ohun to fa ẹkun omi yii pato ko ti i ṣee fidi ẹ mulẹ, boya adagun omi ti a mọ si 'Dam', ṣi silẹ nibi kan ni tabi bẹẹ kọ.

Olori agbegbe Mokwa, Alhaji Muhammadu Shaba Aliyu, sọ fun BBC pe àgbá kan wa lagbegbe naa to le pin omi sita nigbakugba ti ojo ba rọ, o ni ṣugbọn ọwọja ojo yii funra rẹ le gan-an ni, o si ti pọju.

Awọn olugbe sọ fun BBC pe awọn gbagbọ pe ki i ṣe ojo to rọ ju naa lo fa omiyale yii.

"Ojo yẹn o le fa ẹkun omi yii, nitori o ti mọwọ duro, ko si omi nibi kankan mọ. Ita ni mo wa, lojiji ni mo si ri i ti omi bẹrẹ si i tu jade yanturu to si n tu gbogbo ohun to wa loju ọna ka." Muhammed lo ṣalaye bẹẹ.

Arabinrin Sulaiman ni tiẹ, sọ pe: Lẹyin ti mo kirun tan, ti mo sun ti mo si taji, mo ṣilẹkun mo si wo ita, mi o ri omi kankan. A o mọbi to ti wa, orisun omi naa ko ye wa rara ni."

"Fun awọn to sọ pe ojo lo fa ẹkun omi yii, irọ ni wọn n pa. Ojo ti da ki ẹkun omi too bẹrẹ. Ko sẹni to mọ ohun to fa omiyale yii, ọdọ Ọlọrun lo ti wa."

Ọgbẹni Adamu lo sọ bayii ni tirẹ.

Bakan naa ni Igbakeji alaga ijọba ibilẹ Mokwa, Musa Alhaji Aliyu Kimboku, sọ pe ojo kọ lo fa omiyale naa.

Saliu Sulaiman ree, o ni omi naa pọ ju, oun ko le wọ yara lati ko owo to$1,500 to jẹ èrè iṣẹ oko oun.
Àkọlé àwòrán, Saliu Sulaiman ree, o ni omi naa pọ ju, oun ko le wọ yara lati ko owo to$1,500 to jẹ èrè iṣẹ oko oun.

Ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri (The National Emergency Management Agency) NEMA, ṣalaye pe awọn to farapa n gba itọju lọwọ, awọn ti ko si rile gbe mọ ti wa ni ibudo kan ti wọn ti n fun wọn ni awọn nnkan ti wọn nilo.

Ṣaaju ni ajọ to n ri si oju ọjọ ti sọ pe o ṣee ṣe ki ojo rọ fun igba ọjọ (200 days) lapa Ariwa Naijiria lọdun yii, to si le ju bẹẹ lọ lawọn apa Guusu Naijiria.

Ni ibẹrẹ oṣu Karun-un, ijọba apapọ fi eto ikede kan lọlẹ, lati kọ araalu lẹkọ nipa ewu omiyale, ẹkun omi.

Ipinlẹ ọgbọn (30) ninu mẹtadinlogoji (36) to wa ni Naijiria ni wọn lo wa ninu ewu omiyale, ipinlẹ Niger yii si jẹ ọkan ninu wọn.

Bi awọn ti ijamba yii kan ṣe n tun aye wọn ṣa pada, awọn to padanu eeyan wọn bii Adamu Yusuf, sọ pe oju apa ko le jọ oju ara fawọn mọ laye.

Wọn ni bo tilẹ jẹ pe awọn ti gba kadara, ọgbẹ ọkan ti ko le san lohun to ṣẹlẹ sawọn.