Ojú mi ni omi ṣe wọ́ ìyàwó àti ọmọ mi lọ, èèyàn mẹ́sàn-án ni èmi nìkan pàdánù nínú ẹ̀kún omi Mokwa'

Oríṣun àwòrán, Gift Ufuoma
- Author, Azeezat Olaoluwa
- Role, BBC News, Mokwa Town
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8
Aye o ri bakan naa mọ fun ọkunrin kan, Adamu Yusuf, ẹni to padanu eeyan mẹsan-an ninu idile rẹ sinu ẹkun omi to ṣẹlẹ ni Tiffin Maza, ọkan lara awọn agbegbe ti omiyale ti waye lọsẹ to kọja, ni Aarin-Gbungbun Ariwa Naijiria.
Ọmọ kan ṣoṣo naa ni Adamu ṣẹṣẹ bi, o ṣalaye fun BBC pe ọmọ ikoko naa pẹlu iya rẹ, wa lara awọn eeyan ti omi wọ lọ latari ojo nla to rọ l'Ọjọruu mọju Ọjọbọ, nipinlẹ Niger. Eyi to fa omiyale ati ẹkun omi to mu ki ọpọ ile o ri.
"Iyawo mi lo ji mi nigba ti omi ya wọle, mo si sare ko gbogbo awọn ẹbi mi to wa nitosi jọ, mo ni ki kaluku di ara wọn mu. Bi a ṣe jade sita bayii, a ri omi to ti gba gbogbo ile wa , titi kan palọ wa ati inu ọgba paapaa. Ẹru ba wọn bi wọn ṣe ri omi naa, nibẹ ni gbogbo wa ko si ti ri ara wa mọ."
O ku ọla ti iṣẹlẹ omiyale naa yoo ṣẹlẹ ni iyawo Adamu ati ọmọ ikoko ti wọn bi ṣẹṣẹ pada si Mokwa. Ile awọn obi iyawo ni wọn wa fun bi ọsẹ meloo kan lẹyin ti obinrin naa bimọ.
"Oju mi bayii ni omi ṣe wọ mọlẹbi mi lọ, ti mo n wo wọn bayii lai le ṣe nnkan kan si i. Emi gan-an ti mi o ku, nitori pe mo mọ bi wọn ṣe n luwẹẹ ni omi ko ṣe gbe mi lọ. Ọlọrun lo da mi si". Bẹẹ ni Adamu ṣalaye.
Nigba ti yoo fi di ọjọ Aiku, awọn alabojuto iṣẹlẹ naa kede pe eeyan to ti ku ti le ni igba (200). Lọjọ Ẹti, aadọfa eeyan ni wọn lo ku, ko too gunke di igba laaarin ọjọ kan sira wọn. Ibẹru ṣi wa lọkan awọn eeyan, pe o ṣee ṣe ki onka awọn to ti di oloogbe tun pọ si i.

Oríṣun àwòrán, Gift Ufuoma
Bí èèyàn jẹ orí ahun, yóò ké tó bá dé Tiffin Maza
Lọjọ Satide, lẹyin ẹkun omi naa, gbogbo agbegbe Tiffin Maza kan gbinrin-gbinrin fun ibanujẹ, aini ireti mọ ati adanu.
Aṣọ fọn kan ojuu popo, timutimu to ti rin fun omi kari ilu, awọn irin ikọle ati ọpọlọpọ ile to ti wo lulẹ latari omiyale lo gba gbogbo agbegbe naa kan.
Kedere lo han pe awọn ile to rọju duro lai wo lulẹ paapaa ti fi ara ko ijamba, orule wọn ti ṣi danu, apa kan awọn ile naa si ti ya lulẹ bi àlàpà.
Nibi ti Adamu fi n ṣe yara nigba kan ti di ilẹ lasan, o si fi ibanujẹ ṣalaye pe :
"Gbogbo nnkan ini mi pata ni mo ti padanu sinu ẹkun omi yii. Ohun kan ṣoṣo ti mo ni bayii ko ju aṣọ ti mo wọ yii lọ, ọrẹ mi kan lo si fun mi."
O ni wọn ti ri oku ọkan lara awọn ẹbi oun, oun si ti gba kadara, pe awọn toun ko ri mọ yẹn naa yoo ti ku, wọn ko le pada wale mọ laaye.
Ẹlomi-in ti iṣẹlé yii tun kan ni ọmọdekunrin kan, Isa Muhammed, ẹni ọdun mọkandinlogun (19). Olukọ rẹ pẹlu awọn ẹbi tiṣa naa mẹjọ ni wọn ba àgbàrá ojo lọ. Niṣe ni omi wọ ile tiṣa naa lọ raurau, latigba naa ni Muhammed si ti n sunkun lai dakẹ.
"Wọn ti ri oku eeyan meji ninu wọn, ọkan ninu awọn oku naa jẹ ọmọ ọwọ. Ṣugbọn tiṣa mi, ọmọ rẹ keji, aburo rẹ ati awọn ẹbi wọn mẹrin ni a ko ti i ri rara. Ile kan wo lu iyawo rẹ ti ko si ninu ile pẹlu awọn to ku, ẹsẹkẹsẹ lo si ku."
Muhammed funra rẹ padanu eeyan kan to da bii aburo fun baba rẹ.
"Ẹgbọn Musa jẹ ọrẹ gidi fun baba mi. Oun lo n tọju mi lati 2023 ti baba mi ti ku. O kọ mi pe ẹkọ ṣe pataki, o si maa n ni ki n ṣe ohun to yẹ.
"Nigbakigba ti mo ba da wa ti mo si ranti wọn bayii, omi maa n jabọ loju mi ni. Mi o ti i le sun latigba ti ijamba yii ti ṣẹlẹ." Muhammed lo ṣalaye bẹẹ.
Omi naa ti fa bayii, awọn olougbe to ṣẹku si kora jo lati ṣe adua fun awọn eeyan ti ijamba kan, wọn tun n wa awọn ti wọn ko ri pẹlu.
Awọn olugbe agbegbe naa kan sọ fun BBC pe ẹkun omi ọhun ga pupọ, to bẹẹ to gun niwọn ẹsẹ bata meje lawọn ibi kan.
Òórùn buruku lo gba agbegbe Tiffin Maza yii, awọn eeyan ibẹ si sọ pe itumọ rẹ ni pe oku ọpọ eeyan lo ṣi wa labẹ awọn ẹrẹ ti omi naa ko jọ.
Bi eeyan ba si debẹ, yoo sunkun!
Iṣẹ takuntakun lo n lọ lati ri awọn oku gbe jade lati Ọjọbọ, ki wọn le sin wọn nilana to yẹ.
"Emi o ri iru agbara ojo to to bẹẹ yẹn ri laye mi, ṣugbọn mo dupẹ pe awọn ẹbi mi ko ba a Iọ." Iya agba ẹni ọdun marundinlaadọrin (65) Ramat Sulaiman, lo sọ bẹẹ.
Ile iya naa ba omi lọ raurau, oun ati awọn eeyan rẹ ko si ni ibugbe kankan bayii.

Oríṣun àwòrán, Gift Ufuoma
''Ọgọ́rùn-uń ọmọde ni omi wọ́ lọ níléé kéú kan''
Ninu ọrọ iya naa, o ni awọn ọmọde kan to n kọ ẹkọ nipa imọ Kurani, ti wọn to ọgọrun-un (100) ni omi wọ lọ to wa nile kẹta tiẹ."
Iran inira ni fun mi lati wo, awọn ọmọde naa n kigbe fun iranlọwọ, ṣugbọn ko sẹni to le ṣe ohunkohun fun wọn bi wọn ṣe n ke to, ile ti wọn wa ninu ẹ naa ri wọlẹ, omi si gbe wọn lọ."
Ọmọ Ramat to jẹ ọkunrin, Saliu Sulaiman, naa fara ko ninu ijamba yii, ko rile gbe mọ bẹẹ ni ko si owo kankan lọwọ rẹ mọ.
" Mo padanu owo to to $1,500 sinu omi naa. Owo ti mo ri ninu ere oko mi ti mo ta ni ọjọ to ku ọla ti wahala yii maa ṣẹlẹ ni. Mo tiẹ gbiyanju lati wọle lọọ ko owo naa, ṣugbọn ọwọ agbara omi yẹn le pupọ, o dẹru ba mi."
"Mo tun padanu apo ẹpa mọkanla, ati apo ẹwa meje, mi o si le wọle ko wọn. Ṣugbọn mo dupẹ pe a jade laaye, ọpọ oku lo wa ninu omi."
Bẹẹ ni Saliu Sulaiman wi.
O loun ko le sun latigba ti wahala naa ti ṣẹlẹ. Ọkan oun ti poruru.

Oríṣun àwòrán, Gift Ufuoma
Àwọn aláṣẹ kò tí ì lè sọ ìdí ẹ̀kún omi yìí
Ohun to fa ẹkun omi yii pato ko ti i ṣee fidi ẹ mulẹ, boya adagun omi ti a mọ si 'Dam', ṣi silẹ nibi kan ni tabi bẹẹ kọ.
Olori agbegbe Mokwa, Alhaji Muhammadu Shaba Aliyu, sọ fun BBC pe àgbá kan wa lagbegbe naa to le pin omi sita nigbakugba ti ojo ba rọ, o ni ṣugbọn ọwọja ojo yii funra rẹ le gan-an ni, o si ti pọju.
Awọn olugbe sọ fun BBC pe awọn gbagbọ pe ki i ṣe ojo to rọ ju naa lo fa omiyale yii.
"Ojo yẹn o le fa ẹkun omi yii, nitori o ti mọwọ duro, ko si omi nibi kankan mọ. Ita ni mo wa, lojiji ni mo si ri i ti omi bẹrẹ si i tu jade yanturu to si n tu gbogbo ohun to wa loju ọna ka." Muhammed lo ṣalaye bẹẹ.
Arabinrin Sulaiman ni tiẹ, sọ pe: Lẹyin ti mo kirun tan, ti mo sun ti mo si taji, mo ṣilẹkun mo si wo ita, mi o ri omi kankan. A o mọbi to ti wa, orisun omi naa ko ye wa rara ni."
"Fun awọn to sọ pe ojo lo fa ẹkun omi yii, irọ ni wọn n pa. Ojo ti da ki ẹkun omi too bẹrẹ. Ko sẹni to mọ ohun to fa omiyale yii, ọdọ Ọlọrun lo ti wa."
Ọgbẹni Adamu lo sọ bayii ni tirẹ.
Bakan naa ni Igbakeji alaga ijọba ibilẹ Mokwa, Musa Alhaji Aliyu Kimboku, sọ pe ojo kọ lo fa omiyale naa.
Ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri (The National Emergency Management Agency) NEMA, ṣalaye pe awọn to farapa n gba itọju lọwọ, awọn ti ko si rile gbe mọ ti wa ni ibudo kan ti wọn ti n fun wọn ni awọn nnkan ti wọn nilo.
Ṣaaju ni ajọ to n ri si oju ọjọ ti sọ pe o ṣee ṣe ki ojo rọ fun igba ọjọ (200 days) lapa Ariwa Naijiria lọdun yii, to si le ju bẹẹ lọ lawọn apa Guusu Naijiria.
Ni ibẹrẹ oṣu Karun-un, ijọba apapọ fi eto ikede kan lọlẹ, lati kọ araalu lẹkọ nipa ewu omiyale, ẹkun omi.
Ipinlẹ ọgbọn (30) ninu mẹtadinlogoji (36) to wa ni Naijiria ni wọn lo wa ninu ewu omiyale, ipinlẹ Niger yii si jẹ ọkan ninu wọn.
Bi awọn ti ijamba yii kan ṣe n tun aye wọn ṣa pada, awọn to padanu eeyan wọn bii Adamu Yusuf, sọ pe oju apa ko le jọ oju ara fawọn mọ laye.
Wọn ni bo tilẹ jẹ pe awọn ti gba kadara, ọgbẹ ọkan ti ko le san lohun to ṣẹlẹ sawọn.














