Ẹ wo bí àwọn mùsùlùmí ṣe ń yayọ̀ ọdún Ileya káàkiri àgbáyé lónìí

Awọn musulumi kaakiri agbaye n yayọ ọdun Eid-el-Kabir ti ọpọ mọ si ọdun Ileya lonii.
Ọdun Eid-el-Kabir jẹ ọkan pataki lara awọn ọdun to ṣe pataki fawọn musulumi ododo.
Awọn onimọ nipa ẹsin Islam sọ pe, ọdun Ileya ni awọn musulumi fi ma n ranti bi Anabi Ibrahim ṣe fẹ fi ọmọkunrin rẹ Ismail rubọ gẹgẹ bii aṣẹ ti Ọlọrun pa fun un.
Igbagbọ awọn onimọ nipa ẹsin Islam ni pe, Ọlọrun Allah pese agbo fun Anabi Ibrahim lati fi ṣe irubọ naa.
Nigba ti Anabi Ibrahim fẹ pa Ismail ni Allah sọ pe ko ma pa ọmọ naa, o si pese ẹran agbo fun un lati fi ṣe irubọ ti o fẹ ṣe.
Oriṣiiriṣii ẹran lawọn musulumi maa n pa kaakiri agbaye lati fi yọ ayọ ọdun Sallah.
Pipa ẹran pọn dandan fun musulumi to ba lagbara ati owo lati ṣe bẹẹ.
Ẹran ti wọn ba pa lọjọ Ileya lo wa fun irubọ si Allah, ti wọn si maa n pin laarin ẹbi, ọrẹ ati awọn alaini lawujọ.
Awọn musulumi maa n ṣe eleyii lati fi ṣe itọrẹ aanu fawọn eeyan, o si tun jẹ ami igbọran si Ọlọrun Allah.
Kaakiri agbaye lawọn musulumi ti lọ si Yidi lonii lati kirun ọdun Eidel-el-Kabir.
Aṣọ n pe aṣọ ranṣẹ lawọn yidi lonii nibi tawọn musulumi ti n yayọ ọdun.
Awọn musulumi tu yaya jade lọ si yidi niluu Ibadan ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Oyo lati kirun fọdun .







Idi tawọn musulumi ṣe n pa ẹran agbo ninu ọdun Sallah

Oríṣun àwòrán, Gautam Bose via Getty Images















