Ìrètí àwọn òbinrin kan láti di ọlọ́mọ láyé já sófo lẹ́yìn tí àwọn ológun ba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọlẹ̀ ọmọ jẹ

Ibi yii ni yara ayẹwo ti wọn ko awọn ọlẹ ọmọ ti wọn fẹ lo fun IVF si

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ibi yii ni yara ayẹwo ti wọn ko awọn ọlẹ ọmọ ti wọn fẹ lo fun IVF si
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

"Ironu ba mi, gbogbo ero mi ja si pabo," Noura, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, obinrin lati orilẹede Palestine ni o ti ku oun pẹlu ofo bayii.

Lẹyin ọpọlọpọ ọdun to fi ṣe IVF, o ni oyun ni oṣu Keje ni ọdun 2023. "Inu mi dun." O ranti, to si ṣapejuwe ọjọ naa gẹgẹ bii eyi to dun mọ ju laye.

Oun ati ọkọ rẹ, Mohamed pinnu lati fi ọlẹ ọmọ mii pamọ si ile iwosan Al-Basma niluu Gaza, nibi ti wọn ti n tọju ọlẹ ọmọ naa, pẹlu ireti lati ni ọmọ si ni ọjọ iwaju.

"Mo ro pe ala mi ti wa si imusẹ ni," o sọ. " Ṣugbọn ijọ ti awọn ọmọ Israel wa, ẹmi kan sọ fun mi pe o ti tan."

Aisan ba ilera Noura nigba ti oyun naa pe oṣu meje.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Noura's family archive

Israel kọlu ileeṣẹ ologun ni Gaza ni idahun si ikọlu to waye ni ẹnu ibode ni ọjọ Keje oṣu kẹwaa ọdun 2023, nibi ti o le ni ẹgbẹrun kan eeyan to padanu ẹmi wọn, ti wọn si mu eeyan to le ni igba si ahamọ.

Lati igba naa, o le ni eeyan ẹgbẹrun lọna mẹrinlelaadọta to ti padanu ẹmi wọn niluu Gaza, ajọ eleto ilera kede.

Gẹgẹ bii ọpọ ọmọ ile Gaza, Noura ati Mohamed ni lati ma sa kiri, ti wọn ko si ni anfani si ounjẹ ati awọn eroja mii fun oyun naa lati wa ni alaafia.

"A ma n rin fun ọpọ wakati, ti a si n kuro lati ibi kan si ibi kan pẹlu ẹru ibugbamu ado oloro," Mohamed ṣalaye.

Aisan ba ilera Noura nigba ti oyun naa pe oṣu meje.

"O bẹrẹ si ni ma da ẹjẹ lara, a ko ri ọkọ lati gbe lọ si ile iwosan. Ọkọ agbegi ni a ri fi gbe lọ si ile iwosan.

"Nigba ti a de, oyun bibajẹ ti bẹrẹ."

O binu ọmọ ṣugbọn o bi kan ku, ti ọkan yooku naa si ku lẹyin wakati diẹ ti wọn bi. Mohamed ni ko si ẹrọ atẹgun ti awọn le gbe awọn ọmọ naa si.

"Laarin iṣẹju diẹ, gbogbo nnkan ti bajẹ," Noura sọ.

Lẹyin ti wọn padanu awọn ibeji wọn, wọn tun padanu awọn ọlẹ ọmọ ti wọn fi pamọ ni ile iwosan.

Ọpọ ọlẹ ọmọ lo bajẹ.

Gbogbo awọn to ko ọlẹ ọmọ wọn si Al-Basma clinic, lo padanu bayii

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Gbogbo awọn to ko ọlẹ ọmọ wọn si Al-Basma clinic, lo padanu bayii

Oludari ile iwosan Al-Basma, Dr Baha Ghalayini sọrọ pẹlu ibanujẹ ọkanbi o ṣe n ṣalaye ikọlu naa.

Dr Ghalayini ni oun to dun oun ju ni pe o le ni ẹgbẹrun ọlẹ ọmọ to w ani ipamọ oun, ti oun si tun ni ẹgbẹrun kan atọ ọkunrin ati ẹyin ni ipamọ.

"Awọn ibi ti a n ko awọn nnkan wọnyi si to bajẹ ni wọn jẹ ẹgbẹrun mẹwaa dọla ni ọkankan.

Dokita Ghalayini ni ti oun ba wo, o le ni ọgọrun un obinrin to ti padanu anfani lati di ọlọmọ laye, ti wọn ko si le ṣe iṣẹ abẹ mọ.

"Ọpọ wọn ti n dagba, ọpọ ni aarun jẹjẹrẹ ati awọn aisan mii. A fun awọn kan ni abẹrẹ to jẹ pe ẹkan pere ni wọn le gba laaye wọn.

"Ka tun bẹrẹ ni ko rọrun fun ẹnikẹni."

'Oju mi ni gbogbo ẹ ti dawo'

Dokita Ghalayini ni gbogbo ile iwosan Gaza to wa fun ọmọ bibi ti wọn jẹ mẹsan an ni wọn ti dawo, ni wọn ko siṣẹ mọ.

Noura ni ohun to ṣẹlẹ ti sọ oun ati ọpọ obinrin di ẹni ti ko le bimọ mọ. Awọn eeyan bii Sara Khudari, to bẹrẹ irinajo nini ọmọ laye rẹ ni ọdun 2020. O n mura lati lọ fi ẹyin rẹ pamọ nigba ti ogun Gaza bẹ silẹ ninu oṣu kẹwaa ọdun 2023.

"Gbogbo igbiyanju mi, oju mi lo ti dawo."

Ati Islam Lubbad, ẹni ti ile iwosan Al-Basma ranlọwọ lati bi ọmọ ni ọdun 2023, ṣugbọn lẹyin oṣu diẹ ti ogun naa bẹrẹ, o padanu ọmọ naa.

"A ko ri ibi duro si, a kan n rin kiri," o sọ bi o ṣe n ranti iṣẹlẹ naa ."