Wọ̀nyí ni ohun tí àwọn ilẹ̀ Africa tí Trump fòfin dè láti má wọ America mọ́ ń bèèrè

Obinrin arinrinajo kan lo n wo bii pe ọrọ naa ko ye e mọ yii.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ariynajiyan ti n waye lori ofin naa, awọn kan n sọ pe oṣelu ati ẹlẹyamẹya ni wọn fi gbe e kalẹ. Wọn ni ko si akoyawọ ninu igbesẹ ofin yii rara.
    • Author, Jelilat Olawale
    • Role, BBC News
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Aarẹ orilẹede America, Donald Trump, ti fofin de awọn orilẹede mejila kan pe wọn ko le wọ America mọ. Meje ninu awọn orilẹede naa si jẹ ilẹ Africa.

Ohun to jẹ ki BBC wa ọna lati mọ ohun ti awọn eeyan n sọ lori ofin yii kaakiri niyi, nipa lilo oju opo ti a mọ si Google Trends ati awọn ẹka BBC ilẹ Africa lori ayelujara.

Eyi ni awọn ibeere to le tente ninu ohun ti awọn eeyan fẹẹ mọ nipa ofin Aarẹ Trump yii.

Àwọn orílẹ̀èdè wo ni òfin dè báyìí?

Meje ninu awọn orilẹede ti ofin de lati ma ṣe wa si America mọ jẹ ilẹ Africa, awọn naa ni:

  • Chad, Congo-Brazzaville, Equatorial Guinea, Eritrea, Libya, Somalia, ati Sudan.

Awọn yooku ni Afghanistan, Myanmar, Haiti, Iran, ati Yemen.

Bakan naa ni ofin yii de awọn orilẹede mi-in naa lawọn apa ibi kan, wọn ni o lojuu fisa ti wọn le gba bi wọn ba fẹẹ wa si America.

Awọn wọnyi ni:

  • Burundi, Togo, Sierra Leone to wa ni Africa, Cuba, Laos, Turkmenistan ati Venezuela.

Awọn fisa ti wọn ni wọn ko le gba ni ti akẹkọọ ati arinrinajo afẹ (student and tourist visas), nigba ti wọn le ri awọn oriṣi fisa yooku gba.

Ṣé gbèdéke wà fún òfin yìí láti kásẹ̀ nílẹ̀? Kí ni àwọn tó kàn yóò ṣe kí òfin náà lè dópin?

Gẹgẹ bi eto ti wọn ṣe lori ofin yii, wọn ni yoo bẹrẹ ni aago mejila kọja iṣẹju kan aarọ, (aago Washington) ọjọ Aje, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹfa ọdun 2025.

Ofin to de awọn orilẹede yii ko ni gbedeke igba ti yoo wa sopin, ṣugbọn awọn fisa ti wọn ba ti lu lontẹ ṣiwaju igba naa yoo ṣi wulo, gẹgẹ bi ofin naa ṣe sọ.

Aarẹ America sọ pe o ṣee ṣe ki atunyẹwo waye lori ofin yii, bi ayipada ba wa. O si tun ṣee ṣe ki afikun ba awọn orilẹede ti ofin yoo de, bi idunkooko mọni ṣe n pọ si i lorilẹede agbaye.

Kí ló dé tí wọ́n fi ojú sun àwọn orílẹ̀èdè Africa kan?

Aarẹ Trump sọ pe awọn orilẹede ti ofin yii kan ko kunju oṣuwọn to lati pese iwe irinna ati awọn iwe to jọ mọ bẹẹ. O ni o tun ṣee ṣe ki wọn maa fẹẹ gba awọn eeyan wọn pada siluu mọ.

Idi miran to tun sọ ni pe wọn n ru ofin to de fisa America, wọn si tun le koba aabo ati alaafia ilu oun.

Agbẹnusọ ile ijọba America, Abigail Jackson, ṣalaye pe ofin yii yoo da aabo bo awọn ọmọ America lọwọ awọn ara okeere to le ṣe wọn ni jamba.

" Ofin ti a fi ọgbọn ori gbe kalẹ yii kan awọn orilẹede ti ayẹwo gidi ko si, awọn ni wọn pọju ninu awọn to yẹ ko ti kuro l'America, ṣugbọn ti wọn taku sibẹ lẹyin ti ọjọ ti lọ gidi lori iwe irinna wọn. Abi awọn ti wọn kuna lati sọ ododo nipa ara wọn ati iru eeyan ti wọn jẹ boya ẹni ibi ni wọn,"

Bayii ni Abigail Jackson ṣalaye fun alajọṣiṣẹ BBC l'America, CBS.

 Aworan to ṣafihan awọn orilẹede ilẹ Africa ti wọn ni wọn ko gbọdọ de America mọ.

Oríṣun àwòrán, The White House/ BBC

Ǹjẹ́ nìtorí ààbò ni òfin yìí ṣe wáyé tàbí òṣèlú lò fà á?

Nigba to n ṣalaye nipa ofin yii, Aarẹ Trump mẹnuba ikọlu to waye ni Boulder, Colorado, o ni ewu ni awọn eeyan kan ti wọn n gbe ilu naa lai jẹ pe wọn ti yẹ wọn wo daaaa ki wọn too wọle.

Ṣugbọn afurasi ninu ikọlu Boulder Colorado jẹ ọmọ Egypt, Egypt ko si si ninu awọn orilẹede ti Trump fofin de bayii.

Eyi ni awọn awoye fi n sọ pe akoyawọ kankan ko si ninu ofin yii, wọn lo jọ ohun ti wọn fi ẹya ati oṣelu ṣe.

Paapaa bo ṣe jẹ pe gbogbo ilu ti iṣoro aabo wa fun ni ofin naa kan, to si jẹ pe awọn mi-in ti wọn ko tiẹ ni wahala aabo rara tun wa ninu awọn to fofin de.

Ajọ Iṣọkan ilẹ Africa, ( African Union) sọ pe ohun to ru oun loju ninu ọrọ yii ni pe igbesẹ naa le nipa to lewu. O ni ki America wa ọna mi-in tọ̀ ."

Ajọ Amnesty International USA, ni tiẹ, ṣapejuwe ofin naa bii ojuṣaaju, ẹlẹyamẹya, iwa ika. Bẹẹ ni Human Rights First l'America sọ pe ọna kan lati gbogun ti awọn arinrinajo ni.

Ipa wo ni òfin yìí máa ni lára àwọn ẹbi ati arinrinajo to n gbé l'America?

Ofin yii fi awọn anfaani kan silẹ fun awọn ti wọn ti n gbe ni America tẹlẹ.

  • Awọn to ni iwe igbelu ko ni iṣoro kankan, wọn le maa wọle .
  • Awọn ọmọde ti awọn ọmọ America gbatọ.
  • Awọn ti wọn jẹ ọmọ America ati orilẹede mi-in, ko ni iṣoro nipa ofin yii.
  • Awọn ẹbi awọn eeyan ti wọn jẹ ọmọ America naa ṣi le ṣe fisa America.
  • Awọn ti wọn jẹ oṣiṣẹ ijọba ilẹ America, ti wọn ti ṣiṣẹ fun ọdun mẹẹẹdogun, pẹlu ọkọ/aya ati awọn ọmọ wọn.
  • Awọn ti wọn ni fisa arinrinajo to ni i ṣe pẹlu ogun tabi ẹlẹyamẹya lati Iran, to le wọn de America ko ni iṣoro pẹlu.
  • Awọn ọmọ Afghan ti wọn ni fisa arinrinajo ọtọ naa le wọle pẹlu.

Itumọ anfaani ni yii ni pe bo tilẹ jẹ pe wọn fi ofin de awọn orilẹede mejila yii, ko kan awọn eeyan ti a ka soke pẹlu anfaani yii.

Ṣé ó ṣeé ṣe kí àwọn kan pe òfin yìí lẹ́jọ́?

Jeff Mason, akọroyin ileeṣẹ Reuters to n kọ nipa ohun to n ṣẹlẹ nile ijọba America, sọ fun BBC, pe ofin ti Trump ṣe yii ṣe rẹgi pẹlu eyi to ṣe ni saa akọkọ rẹ ni 2017, eyi to da oju sọ ọpọ orilẹede to jẹ ti awọn ẹlẹsin Islam. Bo tilẹ jẹ pe ti asiko yii tun pọ si i.

Mason ṣalaye pe aarẹ lo ṣofin yii, o si ṣe deede pẹlu ofin apaṣẹ ni. Ati pe iṣakoso yii gbagbọ pe oun ni agbara lati ṣe iru ofin bẹẹ.

Ṣugbọn o ni oun wo o pe ofin yii naa le koju awọn iṣoro kan labẹ ofin, gẹgẹ bo ṣe ri fun ti akọkọ rẹ, bẹẹ lo ni ipa ti yoo ni lara awọn to kan naa to nnkan ti eeyan yoo ronu le lori.

Ṣé òfin yìí lè dí àwọn agbábọ́ọ̀lù tó ń lọ sí America ní 2026 fún ife ẹ̀yẹ àgbáyé lọ́wọ́?

Iroyin ayọ kan to wa fun ajọ FIFA ni pe ofin Trump yii yọ awọn elere idaraya silẹ, awọn olukọni wọn, awọn ọmọ ẹgbẹ, awọn alatilẹyin ati awọn ẹbi wọn ti wọn ba fẹẹ rin irin ajo fun ere idaraya pataki bii ti ife ẹyẹ Agbaye ati Olympics.

O tumọ si pe orilẹede Iran to ti pegede fun ife ẹyẹ agbaye naa yoo le ran awọn ikọ rẹ ati awọn alatilẹyin ẹgbẹ to ba yẹ lọ lati dije.

Ṣugbọn o, wọn ko ni i gba awọn agbabọọlu Iran laaye lati mu ọrẹ abi alagata lọ sibi ere bọọlu naa. Awọn ẹbi wọn to jẹ bii ọmọ ati iyawo nikan lo le ba wọn lọ.

Báwo ni òfin yii ṣe yátọ̀ sí èyí tí Trump ṣe ni 2017?

Ni saa akọkọ rẹ, Aarẹ Trump ṣofin to ni ki orilẹede Musulumi meje ma wọ America, eyi ti awọn awoye ọrọ pe ni fifi ofin de awọn Musulumi.

Ofin naa koju iṣoro pupọ, wọn si ṣe agbeyẹwo rẹ lọpọ igba ki ile ẹjọ to ga julọ l'America too gba a wọle ni 2018. Aarẹ Joe Biden lo pada waa yi ofin ọhun pada ni 2021.

Ofin tuntun ti Trump ṣe yii yatọ si agbekalẹ akọkọ, gẹgẹ bi Jake Kwon lati Ariwa America ṣe sọ.

Ofin tuntun naa ko sọrọ nipa ẹsin lọtẹ yii, o yi i si pipẹ ju bo ṣe yẹ lọ niluu ati aiṣe deede oṣelu.

Nigba ti awọn ilu bii Iran, Libya ati Somalia wa nibẹ lọtẹ yii, wọn tun ṣe afikun ẹ pẹlu ilu mejila.

Iyatọ mi-in ni pe gbedeke aadọrun-un si ọgọfa ọjọ (90 to 120 days) wa fun ofin ti tẹlẹ, eyi ti wọn ṣẹṣẹ ṣe yii ko ni gbedeke kankan.