Abacha: Ǹjẹ́ òfin fààyè gba ààrẹ láti kó owó aráàlú lọ sílẹ̀ òkèèrè láì jẹ́ kí wọ́n mọ̀

Aworan oloogbe Abacha

Oríṣun àwòrán, others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Latigba ti iyawo Oloogbe Ọgagun Sani Abacha, Maryam Abacha, ti sọ pe aarẹ tẹlẹ ni Naijiria naa ko ji owo ilu ko pamọ si oke okun ni awuyewuye ti n jade lori ọrọ naa.

Ṣe igbagbọ ọmọ Naijiria ni pe bi Abacha ṣe jẹ apaṣẹ-waa, ologun to buru naa lo tun lu owo orilẹede yii ni ponpo.

Eyi ri bẹẹ pẹlu bi owo gọbọi ṣe n wọle si Naijiria lati ọdọ awọn orilẹẹde agbaye ti Oloogbe Sani ko owo ilu yii si ọdọ wọn.

Ati pe o fẹrẹ ma si ijọba kan ti ko gba ipe lati oke okun léyin Abacha, ti awọn orilẹede naa n sọ fun wọn pe Abacha kowo Naijiria si ọdọ awọn, ti wọn si n da owo naa pada.

Ṣugbọn Maryam, Iyawo Abacha, sọ lọjọ Aiku to kọja yii, pe ojuu ta a lo ṣe ti ọkọ oun fi n kowo Naijiria pamọ.

O ni bi Abacha ṣe ṣeto iṣuna Naijiria ko ye awọn òpè to n sọ pe ọkọ oun kowo pamọ ni.

Abilekọ Abacha fi kun un pe ọkọ oun tọju owo fun Naijiria ni, ki i ṣe pe o kowo sa pamọ.

O ni owo to fi silẹ sile ijọba nkọ, ṣebi kia lo tan, ti aye ko si ri iyẹn sọ, afi ti ibanilorukọjẹ ti wọn n gbe kiri.

Lati mọ boya o ṣee ṣe labẹ ofin, ki olori ilu kowo pamọ silẹ okeere lai jẹ pe araalu mọ, BBC ba amoye nipa ọrọ oṣelu sọrọ, iyẹn Ọmọwe Festus Adedayo,

Oun si ṣalaye pe:

Ìyàwó Abacha ń pé ọmọ Naijiria lómùgọ̀, nítorí orúkọ ọkọ rẹ̀ tó fẹ́ẹ́ túnṣe

Ọmọwe Festus Adedayo

Oríṣun àwòrán, Festus Adedayo

Àkọlé àwòrán, Ọmọwe Festus Adedayo

"Gẹgẹ bii olootọ iyawo lọọdẹ ọkọ, o yẹ ka ki Abilekọ MaryamAbacha fun bi ko ṣe fẹ ki aye gbagbe ọkọ rẹ.

"Nibi to si ti n gbiyanju lati ṣe eyi, o ti gbe igbesẹ to fi n pe ọmọ Naijiria ni omugọ.

Eyi lọrọ ti gbajumọ akọroyin ati onkọwe nipa ọrọ to n lọ lawujọ, Festus Adedayọ sọ fun BBC Yoruba.

Koda, o fi kun un pe, "Ọrọ Abilekọ Abacha to sọ pe ọkọ oun tọju owo Naijiria silẹ okeere pani lẹrin-in pupọ, ko si si ọgbọn iṣuna kankan nibẹ bo ti wu ko mọ.

"Bi ijọba ologun ba tiẹ fẹẹ tọju owo Naijiria si oke okun bo ṣe wi, igbesẹ ati ilana wa fun iru ẹ."

Ọgbẹni Festus Adedayọ sọ pe ohun to daju ni pe iru rẹ ko ṣee ṣe lẹyin banki apapọ Naijiria, to gbọdọ fi aṣẹ si i.

O fi kun unpe iyawo olori Naijiria tẹlẹ naa fẹ tun orukọ ọkọ rẹ ṣe ni, eleyi to ni yoo le diẹ ati pe o yẹ 'ki eeyan kaaanu Abilekọ Abacha, pẹlu awijare rẹ to ni o panilẹrin jọjọ.

Ọmọwe Adedayọ fi iṣejọba Abacha we ti awọn apaṣẹ-waa agbaye bii Idi Amin Dada ilẹ Uganda, Augusto Pinochet ti Chile, Francois Duvalier ti Haiti ati bẹẹ bẹẹ lọ.

O ni lẹyin o rẹyin ni aṣiri Abacha tu, pe ki i ṣe pe o ya ika apaṣẹ -waa lasan, o tun ji owo ilu Naijiria ko bii ẹni ti nnkan n ṣe agbari rẹ ni.

Adedayo sọ pe gbogbo owo Abacha to ji ko ti wọn n gba pada, ati awọn mi-in ti ẹni kan ko ni I igba laye yii mọ, fi han pe eṣu meji lo dari Abacha lasiko ijọba rẹ:

Eṣu agbara to n pani ati ti owo kiko.