Aringinya: Èyí lohun tójú omidan tó bá mọ ọkùnrin rí yóò rí bí wọ́n bá súnmọ́ ọdún ìṣẹ̀ṣe yìí nílúù Ikare Akoko
Ọdun Aringinya jẹ pataki ọdun iṣẹṣe ti ko ṣe fi ọwọ rọ sẹyin laarin awọn ọmọ ilu Ikarẹ Akoko ni ipinlẹ Ondo.
Awọn omidan ti ko mọ ọkunrin ri ni wọn maa n kopa ninu ọdun naa .
'Laye atijọ Egungun maa n bẹ ori omidan to ba kopa pẹlu oyun ninu'

Ninu ọrọ rẹ, Kabiyesi Ọwaale ti ilu Ikarẹ Akoko, Ọba Adeleke...ṣalaye pe pataki ọdun iṣẹṣe ni ọdun Aringinya ati pe igba iwasẹ ni wọn ti bẹrẹ rẹ to si jẹ pe bi omidan to ba kopa ba ti mọ ọkunrin ri tabi loyun , egungun kan yoo yọ lojiji, yoo si bẹ omidan bẹẹ lori.
Ọba Adeleke Adedoyin fi kun un pe eyi ti yipada bayii nitori ibọwọ fun ofin. Ọbalaye naa ni lọwọ yii, bi irufẹ eyi ba waye, dipo ki egungun naa bẹ eeyan lori, yoo pe ojo sôkalẹ ni ti ilu yoo fi mọ pe ọkan ninu awọn omidan to n kopa ti ṣe oun eewọ.
Nigba to n kin ọrọ ọbalaye naa lẹyin, Olori Bọsede Adeleke to jẹ iya ọba ilu Ikarẹ ṣalaye pe lode oni awọn omidan kekeke lo n kopa nitori pe ọpọ awọn omidan to ti to ile ọkọ lati lọ ti n ba ara wọn jẹ.
Yoo ya ọba mii to n na ika aleebu si awa to n gbe aṣa ga lẹnu nigba to ba ri wa lọrun

Nigba to n dahun ibeere lori awọn itakurọsọ to n waye pẹlu bi awọn ọbalaye kan ṣe n tako iṣẹṣe nitori ẹsin, Ọba Adeleke Adedoyin ṣalaye pe iṣẹṣe lo gbe Yoruba mu atipe ọba ti ko ba le ṣe iṣẹṣe le fi itẹ silẹ fun awọn to fẹ ṣe.
"Ọba to ba loun o ṣe aṣa mọ, nigba to ba jẹ ọba , o yẹ ko fi ọba yẹn silẹ."






