Àwọn jàndùkú agbébọn yabo abúlé kan, wọ́n yìnbọn fún aláboyún nígbà márùn ún, èèyàn márùn-ún jáde láyé

Aworan alaboyun to fara gbọta
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ninu ọfọ lawọn eeyan abule Agwa ni ijọba ibilẹ Oguta wa nipinlẹ Imo, lẹyin tawọn janduku darandaran yabo abule naa.

Ọpọ eeyan, to fi mọ alaboyun kan, lo padanu ẹmi wọn ninu ikọlu ọhun, nigba ti awọn mii si farapa.

Ṣaaju ni iroyin kan sọ pe awọn janduku agbebọn ṣe ikolu si abule Obeakwuma Mbano lọjọ Ẹti ọjọ kẹrindinlogun oṣu Karun un nibi ti wọn ni awọn janduku ọhun ti n yinbọn soke bo ṣe wu wọn.

Alaboyun kan, Joy Achibugo, si n gba itọju lọwọ bayii nile iwosan lẹyin to fara gbọta nigba marun un ọtọtọ

Alaboyun kan, Joy Achibugo, si n gba itọju lọwọ bayii nile iwosan lẹyin to fara gbọta nigba marun un ọtọtọ.

Bi awọn ara ileto naa ṣe n ṣewadi nnkan to ṣokunfa ikọlu naa lawọn janduku mii tun ṣe ikọlu si Umuekpu, Mgbala atawọn abule mii ni Agwa lọjọ kẹrin oṣu Kẹfa yii.

Awọn eeyan to wa lagbegbe naa sọ pe eeyan marun un lawọn janduku naa pa lopopona Ejemekuru si Agwa.

Bakan naa ni wọn sọ pe wọn tun pa ẹnikan sinu ile ni Umeukpu ni Agwa.

Awọn kan sọ pe ede-ai-yede wa laarin eeyan ileto Amakohia-Ubi atawọn darandaran ni ijọba ibilẹ iwọ oorun Owerri.

A gbọ pe awọn ọdọ lo le awọn janduku darandaran naa lọ, ṣugbọn wọn bẹrẹ sii yinbọn nigba ti wọn de Agwa.

Aworan ẹni ti ibọn ba lẹsẹ

"Nigba ti a n sa asala fun ẹmi wa ni ibọn ba ọmọ-ọmọ mi to loyun, ọta ibọn lu iho sara ilẹkun ati ile ti a n gbe"

Iya-iya alaboyun ti wọn yinbọ fun, Theresa Achikbuo, sọ fun BBC pe alaboyun naa de lati oko nigba naa ni ti o si sọ fawọn ọmọ rẹ lati ko awọn igi idana to lọ ṣẹ wọle.

Achikbuo ni bi oun ṣe ni koun fẹyin lelẹ lati sinmi loun gbọ iro ibọn.

O ni nigba tawọn n sa asala fun ẹmi awọn ni ibọn ba ọmọ-ọmọ oun to loyun.

O fi bii ọta ibọn ṣe lu iho sara ilẹkun ati ile ti wọn n gbe han BBC.

Theresa to sọ pe iru iṣẹlẹ yii ko waye ri ni ileto naa sọ pe awọn adari ijọba ipinlẹ Imo ko tii ṣabẹwo si agbegbe naa lati igba ti iṣẹlẹ ọhun ti waye.

Aworan ọkunrin ti ibọn ba lẹnu

"Buọda mi ku nibi iṣẹlẹ naa, ọpọ eeyan mii naa ku nigba tawọn miran n gba itọju bi nile iwosan."

Davis Ekene Onyejiekwe ti ibọn ba lẹnu n gba itọju lọwọ nile iwosan ẹkọṣẹ iṣegun fasiti ijọba apapọ FUTHO niluu Owerri.

O sọ fun BBC pe buọda oun padanu ẹmi rẹ nibi iṣẹlẹ naa, nigba tawọn mii farapa.

Onyejiekwe ni ọpọ eeyan mii naa ku ninu iṣẹlẹ ọhun nigba tawọn miran n gba itọju bi toun nile iwosan.

Ko ṣai fidi rẹ mulẹ awọn ti ko lowo lati tọju ara wọn n gbadura si Eledua fun iwosan ninu ile wọn.

Aworan obinrin ti wọn pa ọkọ rẹ

"Ọkọ alaboyun kan, to ti bi ọmọ meji tẹlẹ, ṣagbako iku lọwọ awọn agbebọn naa nigba to n lọ sile"

A tun gbọ wi pe ọkọ alaboyun kan ẹni ọdun mejilelogun to tun lọmọ meji ṣagbako iku lọwọ awọn darandaran loju ọna rẹ si ile.

Kasarachi ti a gbọ pe ọkọ rẹ n ṣiṣẹ atọkọ ṣe, sọ pe ilu mii ni Ndoni nipinlẹ Rivers lawọn n gbe.

Bakan naa ni o sọ pe oun ko tii ri oku ọkọ oun lati igba toun ti gbọ iroyin iku rẹ.

Kasarachi ni ọmọ mẹfa ni ọkọ oun fi silẹ lọ, o ni awọn si n duro de alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Imo, Henry Okoye, lati fesi si atijiṣẹ toun fi ranṣẹ si i.