Àwọn ọmọ Onílẹ̀ lẹ ìwé ‘gbé ilé rẹ kúrò lórí ilẹ̀ wa’ sí ara ilé gómìnà Aiyedatiwa pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ilégbèé míì ní Akure, ariwo sọ

O seese ki ọpọlọpọ awọn onile ni agbegbe Alagbaka extention n'ilu Akure, ti n se olu-ilu Ipinlẹ Ondo, di alainile lori laipẹ.
Eyi waye bi ẹbi Olokunjuwon ati Umelu ṣe kede lọjọ Aiku to kọja pe, awọn ni wọn ni awọn ilẹ agbegbe naa ni ibamu pẹlu idajọ Ileẹjọ to ga julọ lorileede yi.
Ni ibamu pẹlu idajọ Ileẹjọ, wọn ti paṣẹ fun ogunlọgọ awọn to kọ ile si ori ilẹ lagbegbe naa, lati kogba kẹru wọn ni kiakia tabi ki wọn wa ba idile naa se idunadura lakọtun, ti wọn ba si nifẹ lati gbe ni agbegbe naa.
Abẹwo BBC Yoruba sagbegbe naa safihan rẹ pe, wọn ti lẹ iwe kaakiri awọn ile to wa lagbegbe naa, pe ki wọn kuro lori ilẹ ti wọn kọle si tabi ki wọn ṣe idunadura pẹlu ẹbi mejeeji.

Kí ni ẹgbẹ́ àwọn tó kọ́ ilé sí agbègbè náà sọ?
Ẹgbẹ awọn onile lagbegbe naa ti kọ jalẹ, bi wọn ṣe fi aake kọri pe ko si idajọ Ileẹjọ to pa iru asẹ bẹẹ.
Alaga ẹgbẹ awọn to kọ ile si agbegbe naa, Fred Ojo, lasiko to n ba ileeṣẹ BBC Yoruba sọrọ sọ pe, idile Olokunjuwon ati Umelu n gbiyanju lati se imuṣẹ idajọ Ileẹjọ lati ọdun 2017 ni.
O ni asiko yii ni iIeẹjọ giga ilu Akure paṣẹ pe ki wọn dawọ duro ná titi ti wọn yoo fi gbọ idajọ Ileẹjọ giga julọ lori isẹlẹ naa.
Alaga ẹgbẹ awọn onile naa sọ pe, awọn ọmọ onilẹ ti lọ lẹ iwe siwaju gbogbo ile agbegbe naa, lati le wọn kuro, to fi mọ ile Gomina Ipinlẹ Ondo, Lucky Aiyedatiwa.
Ọgbẹni Ojo Sapejuwe igbesẹ yii gẹgẹ bi eyi to tako ti Ileẹjọ giga ti ilu Akure.
O wa sekilọ fun awọn ajagungbalẹ naa pe igbesẹ ti wọn gbe yii tumọ si pe wọn n fi ọwọ pa ida ofin loju ni.
O fikun pe awọn yoo si ri daju pe wọn ṣe ohun gbogbo ni ibamu pẹlu aṣẹ Ileẹjọ naa.

Kí ni àwọn mọ̀lẹ́bí tó ni ilẹ̀ sọ?
Ninu atejade ti ẹbi naa fi sọwọ si awọn Akoroyin lọjọ aje, wọn sọ di mimọ pe ile ẹjọ giga julọ lorileede yii ti fagile idajọ ile ẹjọ giga to joko n'ilu Akure lọdun 2017.
Idajọ ile ẹjọ giga julọ yii ko faye gba awọn to kọ ile sori ilẹ naa lati tẹsiwaju ati ma gbe ni agbegbe ti ilẹ naa wa.
Ninu atẹjade ti awọn olori ebi naa, Adegboyega Olokunjuwon, Thomas Ojo, ati Olusola Osore bọwọlu, wọn ni irọ to jina sootọ ni ọrọ ti awọn onile naa sọ pe ẹjọ naa si wa niwaju Ileẹjọ giga julọ.
Wọn salaye rẹ pe Ileẹjọ giga julọ ti ṣe idajọ lori ẹjọ naa, to si pasẹ pe ki wọn kuro lori ilẹ wọn ni kiakia.
Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, wọn salaye rẹ pe, Adajọ Helen Ogunwumiju, ẹni to saaju igbimọ onidajọ ẹlẹni marun-un, lo fagile ẹbẹ awọn to kọ ile sori ilẹ naa, eyi to mu ki wọn lọ Ileẹjọ kotemilọrun.
Ẹbi naa sọ pe igbesẹ wọn lo wa ni ibamu pẹlu aṣẹ Ileẹjọ giga julọ lorileede.












