Fídíò rèé nípa bí àkọlù-kọgbà ṣe ń wáyé ní ojú pópó Tehran, bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ń sá kúrò ní ìlú torí àdó ikú Israel
- Author, By Taraneh Fathalian, BBC Persian
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Bi orilẹede Israel ati Iran se n yin ado iku lu ara wọn, ọpọ eeyan lo ti n di igba ati agbọn wọn lati sa kuro ni ilẹ Iran.
Ẹwẹ ninu fidio yii, ileesẹ iroyin BBC Persian nilẹ Iran bawọn eeyan kan nilu Tehran sọrọ, awọn to kọ lati darukọ tabi fi oju wọn han lori ẹrọ ayaworan, amọ wọn kede ipinnu wọn lati duro tabi fi ilẹ Iran silẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Èèyàn 224 kú ní Iran, 24 kú ní Israel bí orílẹ̀èdè méjéèjì ṣe ń lu àdó olóró lu ara wọn
Bi o tilẹ jẹ pe a ko tii le sọ iye eeyan to ti jade laye nilẹ Iran lati ipasẹ ado iku naa ni alẹ ọjọ Ẹti.
Amọ pẹlu akọtun isẹlẹ ikọlu to waye titi di ọjọ Aiku, ẹka eto ilera nilẹ Iran ni ado oloro ilẹ Israel ti pa eeyan to to okoolerugba ati mẹrin (224).
Bakan naa, gẹgẹ bi ileesẹ Olootu ijọba ilẹ Israel, Benjamin Netanyahu ti wi, titi di alẹ ọjọ Ẹti to kọja ni ilẹ Israel, eeyan mẹrinlelogun lo ti ku lati ipasẹ ado iku ti orilẹede Iran yin si wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
"Mò ń sọ ó dàbọ̀ sáwọn dúkìá tí mo yán òógùn, kí n tó rà wọ́n, èyí tó gba oorun lójú mi, mo lérò pé màá bá a, tí mo bá dé padà"
Bi orilẹede Israel ṣe tẹsiwaju lati ma ju ado oloro si orilẹede Iran, ọpọ awọn olugbe olu ilu Tehran ti pinnu lati koju sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ ati tito fun rira epo bẹnitiroolu lati le ni anfani lati kuro ni ilu naa, ti wọn ko si mọ boya wọn yoo ba ile wọn bi wọn ṣe fi silẹ.
Ọkan kan kọ; "Mo ko awọn nnkan ti mo nilo ati awọn nnkan ti mọlẹbi fun mi, ti mo si kọri sọna. Kikuro ni ile ẹni buru gan an nitori eeyan ko mọ igba ti eeyan ma pada.
Ẹlomiiran kọ; " Ile mi ko ri ibanujẹ bayii ri. N ko mọ boya ma le pada si ile naa."
Ẹnikan gbe aworan ibi ti o ti n siṣẹ, pẹlu ẹrọ kọmputa rẹ si ayelujara;
"Mo n sọ o dabọ si awọn nnkan yii ti mo sisẹ takuntakun lati ra, to gba oorun loju mi. Mo n lero pe mo ma ba pada ti mo ba pada de."
Olugbe agbegbe kan ti eeyan bii milọnu mẹwaa n gbe ṣapejuwe ilu naa gẹgẹ bii ibi ti ala ti n wa si imusẹ fun fasiti ati iṣẹ."
O fikun: "Mo ra awọn nnkan si ile mi pẹlu ifẹ ati igbiyanju. Mo n sọ o dabọ ni idakẹjẹ, pẹlu igbagbọ pe ma le pada si ile mi to rẹwa yii."

Oríṣun àwòrán, Social media
Awọn eeyan yii ti pinnu lati kuro ni agbegbe naa ṣaaju ki Israel to fi ikilọ ransẹ pe ki wọn kuro ni agbegbe naa lọjọ Aje.
Ileeṣẹ ologun Israel ni ki awọn olugbe agbegbe ọhun kuro ni lẹsẹkẹsẹ paapa ni apa ariwa orilẹede naa, Tehran.
Eyi waye ni ọjọ kẹrin ti orilẹede Israel fi ado oloro ransẹ si Iran, to si ṣekupa eeyan 224 gẹgẹ bii ajọ ilera Iran ṣe ṣalaye.
Idahun ado oloro lati wọ Iran naa ṣekupa eeyan 24 ni Israel gẹgẹ ajọ eleto ilera Israel ṣe ṣalaye.
Ṣaaju ni ado oloro to n wa lati orilẹede Israel gbajumọ ibudo ileeṣẹ ologun ṣugbọn eyi ti yipada, ti wọn si si ṣe ikọlu ai awọn agbegbe ti awọn eeyan n gbe.
Awọn akọroyin BBC ko ni anfani lati gbe iroyin sita lati orilẹede Iran nitori ofin ti ijọba fi de wọn ṣugbọn awọn eeyan kan fi iriri wọn ransẹ si ileeṣẹ BBC Persian.
Awọn olugbe kan ni awọn ti pinnu lati duro nitori awọn obi wọn to jẹ agbalagba, ọmọde, eto ilera to peye.
Obinrin kan sọ fun BBC Persian ni oun loyun, ti o si tun ni ọmọ kekere to jẹ obinrin. "Bawo ni mo ṣe fẹ gbe ninu sunkẹrẹ fakẹrẹ? Gbogbo nnkan ti mo kọ sibi... nibo ni mo fẹ lọ?"
Ẹlomii ni oun ko ni ọkọ, ti oun ko si fẹ rin kilomita 800 lọ ba awọn mọlẹbi rẹ ni Shiraz nikan. "Bo ti lẹ jẹ pe mo ni ọkọ, oun to n ba mi lẹru ni ki kuro ni Tehran lọ sibi to jina, lai si epo rọọbi, pẹlu iṣoro pe ọkọ le taku lọna," o sọ.
O ni awọn ọrẹ rẹ to kuro Tehran ni wọn wa nibi ti wọn taku si fun ọpọ wakati.
"Irinajo to yẹ ko gba wọn ni wakati mẹwaa si mejila wa di ogun wakati. Ko si tikẹẹti fun bọọsi naa."

Oríṣun àwòrán, ASAD/Middle East Images/Getty Images
Obinrin kan to ni oun jẹ ẹni ogoji ọdun pẹlu ọmọ meji sọ fun BBC pe oun ko ni ibi kan re lasiko yii.
" Ka ma parọ, ọkan mi o gba lati kuro ki ma wa pada ki aye mi ti bajẹ. Mo ti sisẹ karakara fun ọpọ ọdun lasiko Covid, ọwọngogo ati ọpọ nnkan mi. N ko ni agbara lati bẹrẹ lati ibẹrẹ pada.
Iṣẹlẹ yii ko yọ awọn to wa ni oke okun kuro ti wọn kominu lori awọn eeyan wọn to wa ni ile, ti wọn si n kan si wọn pẹlu ẹrọ ibaraẹnisọrọ.
Eeyan kan lati ori ayelujara Instagram ni: "O ma n ro pe kikuro ni ile ma n fa aisan ṣugbọn bayii ni ohun wa, a ti kọgbọn lori ti aisan ile jẹ ti eeyan ba wa ni ọna jinjin."
Awọn ọmọ orilẹede Iran kan ni awọn eeyan kan pinnu lati ma kuro ni agbegbe lẹyin ọpọ ẹbẹ.
Ọkunrin kan ni, " awọn eeyan kan ko ni owo lọwọ, wọn ko ni ibikibi lati lọ, Ẹ kan ma sọ fun wọn pe ki wọn kuro."













