"Ogun ló lé wa kúrò ní Congo lọ Israel, a tún ti ń kojú ogun míì tó ju ti Congo lọ ní Israel"

Àkọlé fídíò, “Ogun ló lé wa kúrò ní Congo lọ Israel, a tún ti ‘n kojú ogun míì tó ju ti Congo lọ ní Israel”
"Ogun ló lé wa kúrò ní Congo lọ Israel, a tún ti ń kojú ogun míì tó ju ti Congo lọ ní Israel"

Ọmọ orilẹede Congo kan to n ṣatipo ni Israel, Tonton Laupa, ti ṣalaye pe ko rọrun lati maa gbe ni Israel lasiko yii.

Ẹni ogoji ọdun naa to n ṣatipo ni Israel lati ọdun mẹsan an sẹyin sọ pe bo tilẹ jẹ pe ogun lo le oun kuro ni Congo lọdun mẹsan an ṣeyin, ogun to n waye laarin Israel ati Iran buru ju ti eyii to le oun kuro ni Congo lọ.

Ọkunrin naa, ti iyawo rẹ pẹlu ọmọ mẹrin ni wọn n gbe ni Israel ti sọ pe oun ko kọ lati kuro ni ibi ti wọn n gbe bayii.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn kii le sun mọ lalẹ latari bi Iran ṣe maa n fi ado oloro ranṣẹ si Israel lorumọju.

Ẹkurẹrẹ ohun to sọ wa ninu fidio oke yii.