Iṣu ata yán-an yàn bí fásitì Olabisi Onabanjo ṣe ṣòfin ‘o kò wọ kọ́mú, ó kò ṣe ìdánwò, wọ̀n fi ọwọ́ gbé ọmú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti mọ̀ bóyá wọ́n wọ kọ́mú

Ayẹwo awọn akẹkọọbinrin boya wọn wọ kọmu

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Fọnran kan to lu sita lori ayelujara, eyi to ṣafihan bi awọn akẹkọọ obinrin fasiti Olabisi Onabanjo ti wọn n yẹ wo pe boya wọn wọ kọmu saaju ki wọn to wọle si gbagede idanwo, ni o ti di iṣu ata yan-an yan-an lori ayelujara.

Iṣẹlẹ yii ni ọpọ ti bu ẹnu atẹlu lori ayelujara, ti wọn si n sọ ọkọ ọrọ awọn alaṣẹ fasiti naa fun igbesẹ ti wọn tig be lori awọn akẹkọọ obinrin.

Gẹgẹ bi iroyin naa ti wi, ọkan ninu awọn akẹkọọ to ba awọn akọroyin sọrọ ni awọn ayẹwo yii ma n waye lasiko idanwo.

Akẹkọọ mii to ba awọn akọroyin sọrọ bu ẹnu atẹlu bi awọn ẹsọ alabo to wa ninu ọgba ile ẹkọ naa ṣe n ṣe aṣeju lori ayẹwo wọn lara obinrin.

"OOU ko ni ibọwọ fun awọn akẹkọọ wọn, to de ibi pe awọn ẹsọ alabo ninu ọgba ile ẹkọ naa n le awọn akẹkọọ kiri nitori wọn ko wọ bata ti ile ẹkọ ni ki wọn wọ, ni bayii, kọmu ni wọn n le wa kiri fun."

Awọn aṣoju akẹkọọ ni ile ẹkọ OOU sọrọ lori iṣẹlẹ naa

Ninu idahun si ohun to sẹlẹ ni ile ẹkọ Fasiti OOU, Aarẹ fun awọn akẹkọọ, Muizz Olatunji fi atẹjade sita, to si n jẹ ko di mimọ pe awọn alaṣẹ ile ẹkọ n gbe igbesẹ lati tako imura awọn obinrin kan ti ko bojumu ninu ọgba fasiti naa.

Olatunji rọ awọn akẹkọọ obinrin lati mura nibamu pẹlu ilana ti ile ẹkọ naa la silẹ fun wọn.

Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe ofin o wọ kọmu, o wọle si ile ẹkọ, ko ki n ṣe nnkan tuntun rara ni ile ẹkọ."

Awọn alaṣẹ fasiti Olabisi Ọnabanjo ko ti sọrọ ohunkohun lori fọnran ti awọn akẹkọọ naa gbe sita.

"Kò burú bí àwọn aláṣẹ OOU ṣe f'ọwọ́ gbé ọmú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti mọ̀ bóyá wọ́n wọ kọ́mú"

Igbesẹ yii lo wa mu ki BBC Yoruba tọ onimọ kan nipa ọrọ awujọ lọ, Kayode Oladipupọ lati mọ iha to kọ si ofin o ko wọ kọmu, o ko se idanwo nile ẹkọ.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Oladipupo ni ko si ohun buru ninu bi awọn alaṣẹ ile ẹkọ OOU ṣe fi ọwọ gbe ọmu awọn akẹkọọ naa, lati mọ boya lootọ ni wọn wọ kọmu ṣaaju idanwo wọn.

Gẹgẹ bi Oladipupo ṣe sọ, yatọ si ẹkọ imọ iwe, ile ẹkọ tun wa fun kikọ akẹkọọ nipa hihu iwa ọmọluabi ati iwa rere ni awujọ ti wọn n lọ.

O ni ida aadọta ni imọ ko ninu ojuṣe ile ẹkọ, ekeji ni kikọ awọn akẹkọọ nipa iwa rere wiwu, kii si i ṣe iwa rere ni ki akẹkọọbinrin mase wọ kọmu lọ ile ẹkọ.

"Ohun ti mo le sọ pe o buru nibẹ ni to ba jẹ pe ọkunrin lo fọwọ gbe ọyan wọn, ṣugbọn to ba jẹ obinrin lo ṣe bẹẹ, ko si ohun to buru nibẹ."

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Oladipupo tẹsiwaju pe ohun ti fasiti Olabisi Onabanjo ṣe ko buru rara latari pe wọn ti ṣalaye fun awọn akẹkọọ naa ṣaaju pe, oun ko fọwọ si ki obinrin wa sile ẹkọ lai wọ kọmu.

O ni "Iwa aigbọran ni ki eeyan tahun si awọn alaṣẹ.

Mo mọ pe ọpọlọpọ maa sọ pe ki lo de ti wọn se fi ọwọ gbe ọyan wọn, amọ ọna wo ni wọn fi le mọ pe wọn wọ kọmu bi ko ṣe ti wọn ba ṣe bẹẹ?

"Ohun ti mo le sọ pe o buru nibẹ ni to ba jẹ pe ọkunrin lo fọwọ gbe ọyan wọn, ṣugbọn to ba jẹ obinrin lo ṣe bẹẹ, ko si ohun to buru nibẹ."

Ninu alaye rẹ, gbogbo ile ẹkọ lo ni ofin tirẹ ti awọn akẹkọọ ti buwọlu, awọn si gbọdọ tẹle ofin ile ẹkọ naa ti wọn ti buwọlu ṣaaju.

Nipa titẹ ẹtọ ọmọniyan loju mọle, onimọ naa sọ pe ile ẹkọ OOU ko tẹ ẹtọ awọn akẹkọọ naa loju mọlẹ niwọn igba ti ẹtọ wọn ba le tako ẹtọ ẹlomiran.

Lẹyin naa lo gba awọn aṣoju akẹkọọ, SUG nimọran lati maa fi pataki titẹle ofin kọ awọn akẹgbẹ wọn ni gbogbo igba.

O tun rọ awọn ile ẹkọ lati maṣe kawọ gbera nipa ṣiṣe ojuṣe wọn lati ri pe awọn akẹkọọ gbọdọ kẹkọọ nipa iwa rere daadaa yatọ si ẹkọ iwe nikan.