Irú kan ùn! Anfaani Adugbo yóò gbálejò Oriogbade ní ìbẹ̀rẹ̀ sáà Premier League tuntun

Aworan Bruno Fernandes ati Bukayo Saka

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Saa idije Premier League tuntun yoo gbinaya nigba to ba bẹrẹ loṣu Kẹjọ ọdun yii, ikọ agbabọọlu Manchester United tawọn eeyan mọ Anfaani Adugbo ni yoo gbalejo Arsenal ti inagijẹ wọn n jẹ Oriogbade.

Ọjọ Kẹtadinlogun oṣu Kẹjọ ni ifẹsẹwọnsẹ yii yoo waye ni papa iṣere Old Trafford lẹyin ti Liverpool to gba ife ẹyẹ naa ba ti kọkọ ṣide saa idije EPL tuntun ọhun pẹlu Bournemouth lọjọ Ẹti ọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹjọ kan naa.

Akọnimọọgba Liverpool, Arne Slot, to gba ife ẹyẹ EPL ni saa akọkọ rẹ ninu idije Premier League yoo tun gbiyanju ati tun ife ẹyẹ naa gba ni saa bọọlu tuntun yii.

Ikọ agbabọọlu Man City ti Pep Guardiola n dari yoo bẹrẹ saa bọọlu tuntun tiwọn nigba ti wọn ba koju Wolverhampton Wanderers ni papa iṣere Molineux.

Lọjọ Aiku ọjọ kẹtadinlogun oṣu Kẹjọ naa ni ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea tawọn eeyan mọ si Aniyikaye yoo maa wa a ko pẹlu Crystal Palace ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ wọn ni saa bọọlu EPL 2025/2026.

Ẹgbẹ agbabọọlu Everton to jẹ orogun Liverpool yoo maa ta kangbọn pẹlu ikọ Leeds to ṣẹṣẹ pada wa si idije Premier League lẹyin ti wọn ti fidirẹmi lọ si ipele ''Championship'' tẹlẹ.

Sunderland tawọn naa ṣẹṣẹ pada si idije Premier League fun igba akọkọ lati ọdun 2017 ti wọn ti fidirẹmi wọ ipele ''Championship"'yoo gbalejo ikọ agbabọọlu West Ham.

Akọnimọọgba Tottenham tuntun, Thomas Frank, yoo dari ẹgbẹ agbabọọlu naa fun igba akọkọ ninu idije Premier League nigba ti wọn yoo maa na tan bi owo pẹlu Burnley to ṣẹṣẹ pada si idije Premier League.

Gbogbo ifẹsẹwọnsẹ ti yoo waye ni ibẹrẹ saa bọọlu tuntun Premier League loṣu Kẹjọ ree:

Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹjọ

Liverpool v Bournemouth

Ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹrindinlogun oṣu Kẹjọ

Aston Villa v Newcastle

Brighton v Fulham

Nottingham Forest v Brentford

Sunderland v West Ham

Tottenham v Burnley

Wolverhampton Wanderers v Manchester City

Ọjọ Aiku, ọjọ kẹtadinlogun oṣu Kẹjọ

Chelsea v Crystal Palace

Manchester United v Arsenal

Ọjọ Aje, ọjọ kejidinlogun

Leeds v Everton

Ifẹsẹwọnsẹ okoo din ni irinwo ni ogun ẹgbẹ agbabọọlu yoo gba fun ọsẹ mẹtalelọgbọn ni saa bọọlu yii.

Ọjọ kẹrinlelogun oṣu Karun un 2026 ni saa idije Premier League tuntun yii yoo pari.