Kí ni Stun Gun àti pé kí ni òfin sọ nípa lílò rẹ̀ ní Naijiria?

Oríṣun àwòrán, Others
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko kede sita pe ohun ti wọn gba lọwọ gbajugbaja pasitọ ijọ House on the Rock Church, Paul Adefarasin ni ko ki n ṣe ibọn ṣugbọn o fara jọ ibọn.
Ibọn Stun Gun ni wọn gba lọwọ Pasitọ ọhun, eyi ti wọn ni ko ni agbara lati gba ẹmi eeyan ṣugbọn o le kapa eeyan to ba ṣe ijamba fun eeyan.
Bẹẹ ba gbagbe, nibi ọsẹ diẹ sẹyin ni fọnran kan lu sita lori ayelujara, eyi to ṣafihan Pasitọ Aadefarasin ninu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ, to yọ nnkan to jọ ibọn si ọkunrin kan to n ka fọnran bi o ṣe n wa ọkọ.
Ki ni Stun Gun ati iwulo rẹ?
BBC Yoruba kan si akọsẹmọsẹ nipa eto aabo, Akin Adeyi, ẹni to jẹ oṣiṣẹ fẹyinti fun ajọ DSS lati tan imọlẹ si ohun ti a n pe ni 'Stun Gun'.
Adeyi ni ohun to jọ ibọn yii lo wa fun aabo ṣugbọn ti ko ni irufẹ agbara ti ibọn ni.
O tẹsiwaju pe bo ti lẹ jẹ pe awọn Stun Gun kan wa to le gba ẹmi eeyan tabi ko ṣe eeyan le ṣe ni ọpọ ọna.
"Ni akoko iṣoro, Stun Gun wa fun aabo fun ara eeyan, ki ṣe pe yoo pa ẹnikẹni ṣugbọn yoo fa ina si ara eeyan ti wọn ba yinlu, ti yoo da bi pe ina gbe eeyan
Ki ofin sọ nipa lilo Ibọn Stun Gun?
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ninu atẹjade wọn ni lilo Ibọn Stun Gun jẹ ohun ti ofin ko faye gba rara.
Ṣugbọn ninu alaye rẹ, Akin Adeyi ni pẹlu bi ilu ṣe ri lasiko yii, ti eto aabo mẹhẹ, o yẹ ki onikaluku ni ohun aabo fun ara wọn.
"Bi Naijiria ṣe gba bayii, o ti o de ju ẹ ki onikaluku ma da aabo bo ara wọn.
"Bo jẹ ibon lo yọ tabi ki I ṣe ibọn, ijọba apapọ ni ẹbi to pọ ninu eyi nitori ohun gboogi to yẹ ki ijọba mojuto ni didola ẹmi ati dukia araalu.
"Ijọba ti sọ gbogbo wa di eeyan to n ko ake ati ada si ẹyin ọkọ.
"Ti aabo ba to ni, ki ni ojisẹ Ọlọrun n fi Stun Gun ṣe ?"
Adeyi ni Stun Gun ko ki n ṣe ara ohun ija ti eeyan ko le ni daa fun aabo.
"To ba jẹ pe Stun Gun ni Ileeṣẹ ọlọpaa gba lọwọ Pasitọ Paul Adefarasin, ko ki n ṣe nnkan ti eeyan ko le ni, ti Pasitọ ko dẹ ti lu ofin rara.
"Ṣugbọn ibeere le wa boya Pasitọ ra Stun Gun naa ni ọna to tọ ati nnkan to fi ṣe lasiko naa. Boya o fi ibọn ṣe ẹnikẹni le ṣe ati pe awọn Stun Gun mii, ti eeyan ba lo ju, o le gba ẹmi lara ẹnikeji."















