Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Pasitọ ijọ House on the Rock Church, Paul Adefarasin ti fa ara le ọlọpaa lọwọ fun iwadii
Leyin ti wọn fiwe pe e lati wa sọ tẹnu rẹ lori fidio to ṣafihan pe o mu nnkan to jọ ibọn lọwọ ninu niluu Eko
Ẹwẹ, onimọ nipa eto abo kan, Akin Adeyi ti sọrọ lori iha ti ofin kọ si irufẹ nnkan bẹẹ
Lọ soju opo BBC Yoruba fun ẹkunrẹrẹ
_________________________________
Ogun lo le wa kuro lorilẹede Congo lọ si Israel, ṣugbọn ogun ti n a koju ni Israel lagbara ju eyii to le wa kuro nile lọ
Tonton Laupa, to n ṣatipo ni Israle lati odun mẹsan sẹyin lo sọ bẹẹ fun BBC
O ni ohun ko mọ pe mariwo ni ogun to n waye Congo, ohun ti ri egungun bayii laarin Israel ati Iran
________________________________
Lonii ni Aarẹ Bola Tinubu yoo ṣabẹwo sipinlẹ Benue lati ba awọn eeyan ipinlẹ naa ṣe ipade lẹyin ikọlu to waye nibẹ
Ṣaaju ni ileeṣẹ Aarẹ ti kọkọ wọgile irinajo rẹ si Kaduna lati yọju si Benue
Lati mọ ẹkurẹrẹ abẹwo naa