Ta a ló wá nídìí ìṣekúpani tó ń ṣẹlẹ̀ ní Benue, báwo ló ṣe lágbára sí, kí sì ni ọ̀nà àbáyọ?

Aworan awọn ero biba niwaju ile wọn

Oríṣun àwòrán, Nema

Àkọlé àwòrán, Awọn ero biba niwaju ile wọn
    • Author, Mansur Abubakar
    • Role, BBC News, Kano
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Aarẹ Bola Tinubu ti paṣẹ pe kawọn ẹṣọ eleto abo wa ojutuu si iṣekupani to n ṣẹlẹ lera lera nipinlẹ Benue.

Iroyin fidi rẹ mulẹ pe o le ni igba eeyan to ti ku ninu oriṣiiriṣii iṣẹlẹ iṣekupani to waye laarin ọjọ bii meloo kan sẹyin kaakiri ipinlẹ Benue.

Tinubu ṣapujuwe iṣẹlẹ iṣekupani ni Benue gẹgẹ bii nnkan to buru jai ti o si tako ilọsiwaju orilẹede Naijiria.

Aarẹ sọrọ yii lẹyin ti ọpọ eeyan ṣe iwọde tako iṣẹlẹ iṣekupani naa niluu Makurdi ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Benue.

Ohun ti a gbọ ni pe ẹgbẹẹgbẹrun eeyan lo ti sa kuro nile wọn bayii nipinlẹ Benue fun ibẹru wi pe kawọn agbebọn ma lọ kawọn mọle.

Bawo ni ikọlu Benue ṣe lagbara si?

Awọn darandaran ti wọn ṣaba jẹ Fulani maa n da ẹran wọn jẹko kiri eyi to maa n fa ikọlu pẹlu awọn agbẹ.

Awọn agbẹ maa n sọ pe awọn darandaran yii maa n fi ẹran jẹ oko wọn, wọn si tun maa n ba awọn odo jẹ.

Ọpọ ninu awọn darandaran yii lo maa n gbe ibọn dani eyi ti wọn maa n sọ pe awọn fi n daabo bo ara wọn atawọn ẹran lọwọ awọn ole aji ẹran gbe.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bo tilẹ jẹ pe awọn Fulani lawọn agbẹ maa n da lẹbi ni gbogbo igba fun iṣekupani to maa n waye, ọkan lara awọn adari ileto ni Benue, Baba Othman Ngelzarma sọ fun BBC pe awọn eeyan oun kọ lo n ṣeku pawọn eeyan ni Benue.

Kii ṣe igba akọkọ ree ti iṣekupani yoo waye nipinlẹ Benue.

Onimọ nipa ọrọ eto abo to jẹ adari ileeṣẹ Beacon Security & Intelligence ltd, Kabir Adamu, sọ fun BBC pe akọsilẹ fi han pe eeyan 1,043 lo ku nipinlẹ Benue laarin oṣu Karun un ọdun 2023 si si oṣu Karun un ọdun 2025 yii.

Ọpọ iṣẹlẹ iṣekupani lo ti waye lẹkun aarin gbungbun Naijiria ti ipinlẹ Benue wa latari ija to ti n waye laarin awọn agbẹ atawọn darandaran.

Ẹgbẹẹgbẹrun araalu atawọn ẹṣọ eleto abo lo si ti padanu ẹmi wọn bakan naa ninu awọn ikọlu yii.

Awọn darandaran ti wọn ṣaba jẹ Fulani maa n da ẹran wọn jẹko kiri eyi to maa n fa ikọlu pẹlu awọn agbẹ.

Awọn agbẹ maa n sọ pe awọn darandaran yii maa n fi ẹran jẹ oko wọn, wọn si tun maa n ba awọn odo jẹ.

Ọpọ ninu awọn darandaran yii lo maa n gbe ibọn dani eyi ti wọn maa n sọ pe awọn fi n daabo bo ara wọn atawọn ẹran lọwọ awọn ole aji ẹran gbe.

Bo tilẹ jẹ pe awọn Fulani lawọn agbẹ maa n da lẹbi ni gbogbo igba fun iṣekupani to maa n waye, ọkan lara awọn adari ileto, Baba Othman Ngelzarma sọ fun BBC pe awọn eeyan oun kọ lo n ṣeku pawọn eeyan ni Benue.

Baba Ngelzarma ni loootọ ni ede-ai-yede wa laarin awọn Fulani atawọn agbẹ, amọ, awọn eeyan wa kọ lo ṣeku pa eeyan ni Benue.

Ijọba ko tii sọ ni pato awọn to wa nidii iṣẹlẹ iṣekupani to n waye lera lera ni Benue, ṣugbọn ohun to daju ni pe igun mejeeji lo n fara gba nigba kugba ti ikọlu ba waye laarin awọn darandaran atawọn agbẹ.

Ọgbẹni Adamu woye pe ayipada oju ọjọ ati airọ ojo daadaa naa wa lara nnkan to n ṣokunfa ikọlu laarin awọn darandaran atawọn agbẹ.

''Airọ ojo daadaa yii lo maa n jẹ kawọn darandaran maa da ẹran lọ si apa guusu Naijiria to fi mọ Benue to wa laarin gbungbun orilẹede yii.

Ati pe bi awọn eeyan ṣe n sare pọ lagbegbe yii jẹ ki onikaluku maa wa omi ati ilẹ kiri, eyi si n ṣokunfa ikọlu to n waye loorekoore,'' Ọgbẹni Adamu lo sọ bẹẹ.

Ẹsin tun jẹ nnkan mii to n fa ikọlu yii tori musulumi lo pọ ninu awọn Fulani darandaran nigba tawọn agbẹ ni Benue jẹ ọmọlẹyin Kristi.

Ọpọ eeyan tun da ijọba lẹbi wi pe ko pese eto abo to peye fawọn olugbe agbegbe ti ikọlu ti n waye.

Ki ni ijọba n ṣe lori ikọlu Benue?

Ijọba apapọ ti ti ipinlẹ ti gbiyanju lati wa ojutuu si ikọlu laarin awọn agbẹ atawọn darandaran fun ọpọlọpọ ọdun, amọ, ko kẹsẹ jari.

Ọgbẹni Adamu ni ijọba apapọ ṣe ifilọlẹ awọn ẹṣọ ti yoo maa ṣiṣẹ pọ daabo bawọn araalu lọdun 2018, bakan naa ni ijọba tun ṣe ifilọlẹ awọn ẹṣọ aṣogbo loṣu to lọ lati koju ija sawọn ọdaran atawọn agbesunmọmi to n ṣeku pa awọn eeyan.

Onimọ nipa ọrọ to n lọ, Sam Philip to n gbe niluu Makurdi sọ pe ijọba ko karamọ ọrọ iṣekupani to n ṣẹlẹ ni Benue.

Ọgbẹni Philip ni ọrọ Boko Haram to n ṣọṣẹ ni ẹkun ila oorun ariwa, awọn ajinigbe to dawọn eeyan guusu ariwa laamu ati ọrọ awọn ajijagbara to fẹ yapa kuro lara Naijiria lẹkun ila oorun guusu ni ijọba karamọ.

O ni idi niyii ti iṣẹlẹ iṣekupani ni Benue fi n buru sii lojoojumọ.

Ki ni ọna abayọ si ikọlu Benue?

Ọgbẹni Adamu sọ pe ọna abayọ ni ṣe pẹlu ọrọ eto abo ati ọrọ aje.

O ni ijọba ni lati ko awọn akọṣẹ-mọṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ti wọn to gbangba sun lọyẹ lọ si Benue.

Bakan naa ni o sọ pe ijọba gbọdọ pese sare oko tawọn darandaran le maa da ẹran wọn lọ jẹko fun wọn ki adinku le ba ikọlu laarin wọn atawọn agbẹ.

Ijọba gbọdọ pese ibomiran tawọn darandaran yoo ti maa da ẹran wọn jẹko fun wọn lati din ikọlu to n ṣẹlẹ laarin wọn atawọn agbẹ ku.

Ti ẹ o ba gbagbe, aarẹ Naijiria tẹlẹ, Muhammadu Buhari ṣe agbekalẹ iru eto yii, ṣugbọn awọn ipinlẹ lapa guusu Naijiria ko tẹwọ gba a.

Wọn ri igbesẹ yii gẹgẹ bi ọna lati jẹ ki awọn Fulani ba wọn pin ilẹ wọn.