Israel-Iran: Báwo ni ìjà tuntun ṣe bẹ̀rẹ̀, ibo sì ló le è já sí?

Oríṣun àwòrán, Reuters
- Author, Lana Lam, Sofia Ferreira Santos, Jaroslav Lukiv & Nathan Williams
- Role, BBC News
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Israeli ati Iran ti tẹsiwaju lati ma ṣe paṣipaarọ ado oloro ninu rogbodiyan tuntun ti wọn bẹrẹ, eyi ti o bẹrẹ ni ọjọ Ẹti to kọja.
Awọn igun mejeeji ni ibinu wa lọkan wọn, ati pe Aarẹ Amẹrika Donald Trump n gbero bayi boya lati darapọ mọ ikọlu Israeli lori awọn aaye iparun Iran.
Awọn ikọlu naa bẹrẹ bi awọn ijiroro US lori eto iparun Iran, eyiti o bẹrẹ ni Oṣu Kẹrin, dabi ẹni pe o ti da duro. Trump ti nireti lati ṣe adehun kan lati da Tehran duro ninu siṣe idagbasoke ohun ija iparun kan, ṣugbọn jiroro tuntun ti paarẹ.
Ni ọdun to kọja, Iran ati Israeli kọlu ara wọn pẹlu ikọlu afẹfẹ ni Oṣu Kẹrin ati Oṣu Kẹwa.
O le ni igba eeyan to padanu ẹmi wọn lati igba ti ikọlu naa ti bẹrẹ lorilẹede Iran, ti eeyan mẹrinlelogun si padanu ẹmi wọn ni Israel.
Israel ṣagbekalẹ Operation Rising Lion, ti Iran si fesi pada
Ni Ojobo, awọn ologun Aabo Israeli (IDF) sọ fun awọn eeyan ni agbegbe Tehran 18, eyi ti o pẹlu awọn ile ologun ati awọn agbegbe ibugbe, lati jade kuro.
Lẹyin ọpọ wakati, ado oloro akọkọ bu gbamu ni Tehran ni dede ago 03:30 (01:00 BST) ni ọjọ Ẹti, pẹlu awọn agbegbe ibugbe ni olu-ilu ni ikọlu ọhun ba, ileeṣẹ tẹlifisan Iran royin.
Akọroyin BBC ko le jabọ lati inu Iran nitori awọn ofin ti ijọba orilẹ-ede naa fi de iroyin, ti eyi si jẹ ki o nira lati ṣe iṣiro ibajẹ ti o ṣẹlẹ nipasẹ ibinu Israeli.
Olootu ijọba Israel Benjamin Netanyahu sọ pe ikọlu naa - ti wọn n pe ni Operation Rising Lion -wa fun ki doju kọ "ọkan" ti eto iparun Iran.
"Ti ko ba da duro, Iran le ṣe gbejade ohun ija iparun ni akoko kekere," Netanyahu sọ. Iran tẹnumọ pe eto iparun rẹ jẹ ohun alaafia.
Olori Iran Ayatollah Ali Khamenei sọ pe Israeli "pe ki ma reti ijiya nla kan", lakoko ti minisita ajeji rẹ pe awọn ikọlu naa ni "ikede ogun".
Igbẹsan Iran bẹrẹ lẹyin wakati, nigba ti awọn ikọlu ohun ija ballistic ti ṣe ifilọlẹ lori "awọn ibudo awọn ile-iṣẹ ologun ati afẹfẹ" ni Israeli, ninu iṣẹ kan ti o pe ni Promise 3.
IDF sọ pe o le ni ọgọrun-un missiles ti Iran fi ransẹ si Israeli, ati pe pupọ ninu wọn ni eto Iron Dome da duro.
Awọn paṣipaarọ wọnyi ti tẹsiwaju fun ọpọ ọjọ.

Ikọlu Israeli ti pa ọpọ ọga ologun Iran pẹlu Hossein Salami, alakoso ikọ ologun fun Iran (IRGC), awọn onimọ ijinlẹ to n se ado apanirun ati Fereydoon Abbasi, asaaju ileesẹ to n se ado iku nilẹ Iran
Awọn ikọlu Israeli ti pa ọpọlọpọ awọn ọmọ ogun Iran ti o ga julọ, pẹlu Hossein Salami, Alakoso Iran's Islamic Revolutionary Guard Corps (IRGC), ati ọpọlọpọ awọn onimọ-jinlẹ to n se ado iku apanirun, pẹlu Fereydoon Abbasi, ori iṣaaju ti Ajo Atomic Energy Atomic Iran.
Iran sọ pe awọn araalu, pẹlu awọn ọmọde, wa laarin awọn eeyan to ti padanu ẹmi wọn.
IDF sọ pe o ṣe ifilọlẹ ọpọlọpọ awọn ikọlu lori drone Iran ati awọn aaye misaili, ati pe wọn ti ṣe idaduro ọpọ ado oloro ti wọn fi ransẹ si Tel Aviv ati ariwa Israeli.
Awọn ologun Iran sọ pe awọn n gbajumọ kilọlu ẹrọ aabo Israeli ati pe wọn ti rọ awọn olugbe tiwọn w ani ilu Israeli to ṣe pataki lati lọ kuro.
Ni Tehran, olugbohunsafefe iroyin kan sa kuro ni agbedemeji igbohunsafefe nigba ti ikọlu kọlu ile ileeṣẹ naa. Iroyin sọ pe oṣiṣẹ mẹta lo farapa.
Ileeṣẹ ọmọ ogun Israeli kede ni ọjọ Isẹgun pe o ti ṣaṣeyọri lori Tehran, ati pe o ti pa ida mẹta awọn ifilọlẹ ohun ija misaili Iran run.
Eyi waye lẹyin awọn ohun ija ti Iran kọlu awọn agbegbe oriṣiriṣi mẹrin ni ariwa ati aarin Israeli, ti o pa o kere ju awọn araalu mẹjọ.
Ileeṣẹ ilera Iran sọ pe o kere ju eeyan 224 ni wọn padanu ẹmi wọn ni ọjọ Ẹti.
Israeli ti royin iku eeyan mẹrinlelogun ni akoko kanna.
Wọn wa ni Tel Aviv, Haifa, Tamra, Rishon LeZion ati Bat Yam, nibi ti wọn ti kọlu ile alaja mẹwa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Igbesẹ ijọba Amẹrika
Aarẹ Trump n gbero lati darapọ mọ ipolongo Israeli lati dojukọ awọn aaye iparun Iran, awọn orisun ti sọ fun alabaṣiṣẹpọ US ti BBC,iroyin CBS.
Trump ati Netanyahu sọrọ lori foonu ni ọjọ Isẹgun lẹyin ipade ti Igbimọ Aabo Orilẹ-ede Amẹrika.
Aarẹ Amẹrika ti bọ sori ayelujara tẹlẹ lati pe fun "ijuwọlẹ" Iran ati pe Amẹrika mọ ibi ti Olori Iran Ayatollah Ali Khamenei wa, ṣugbọnwọn ko ni pa a, "lọwọ bayii".
Fun apakan tirẹ, Khamenei kilọ fun Trump ti "ipalara ti ko ṣee ṣe" ti ologun US ba da si rogbodiyan naa.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Bawo ni a ṣe de ibi bayii?
Netanyahu sọ ni ọjọ Ẹti pe awọn ikọlu naa jẹ "iṣẹ ologun to fẹ ikọlu ibudo nuclear ti Iran".
O sọ pe ikọlu yoo "tẹsiwaju fun ọpọlọpọ ọjọ bi o ṣe gba lati yọ itankale Iran kuro".
Oṣiṣẹ ologun Israeli kan sọ fun BBC Iran ni awọn ohun elo iparun to lati ṣẹda awọn bombu iparun "laarin ọjọ repete". Iran ti sọ pe awọn ko ṣẹda awọn ohun ija yii fun wahala ṣugbọn fun alaafia.
Awọn ikọlu naa bẹrẹ bi awọn ijiroro US lori eto iparun Iran, eyi ti o bẹrẹ ni Oṣu Kẹrin, dabi ẹni pe o ti da duro. Trump ti ni reti lati ṣe adehun kan lati da Tehran duro ni idagbasoke tabi siṣẹda ohun ija iparun kan, ṣugbọn ijiroro ni ko waye.
Ni ọdun to kọja, Iran ati Israeli fi ọpọ ado oloro kọlu ara wọn ni Oṣu Kẹrin ati Oṣu Kẹwa - botilẹjẹpe awọn ikọlu Israeli ni ọdun to kọja ni a ko gbagbọ pe o ti jakejado bi iṣẹ lọwọlọwọ rẹ.
















