Iran kọlu ilé ìwòsàn àtàwọn iléègbé aráàlú ní Israel, ọ̀pọ̀ èèyàn dágbére fáyé

Oríṣun àwòrán, Reuters
Iléeṣẹ́ ológun Israel ti ní ọ̀pọ̀ àdó olóró "missile" ni orílẹ̀ èdè Iran ti fi ránṣẹ́ sáwọn agbègbè táwọn aráàlú ń gbé èyí tí wọ́n ní ó ṣokùnfà ìkọlù sí ilé ìwòsàn Soroka Hospital tó wà ní Beeresheba, ẹkùn gúùsù Israel.
Yàtọ̀ sí ilé ìwòsàn yìí, wọ́n ní agbègbè mẹ́ta tó jẹ́ pé àwọn aráàlú ń gbé ni Iran tún ṣe ìkọlù sí.
Wọ́n ní àwọn tún gbọ́ ìbúgbàmù ní Tel Aviv àti Jerusalem.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdó olóró "missile" ni Iran jù sí Israel àti pé òhun ní àdó olóró tó pọ̀ jùlọ tí Iran ti fi ránṣẹ́ sí Israel láti ìgbà tí ìkọlù ti bẹ̀rẹ̀ láàárín orílẹ̀ èdè méjéèjì láti ọ̀sẹ̀ tó kọjá.
Àwòrán ilé ìwòsàn Soroka Hospital tó gba orí ayélujára ṣàfihàn bí èéfí ṣe ń tu jáde láti ibi ilé ìwòsàn náà, táwọn fèrèsé rẹ̀ ń fọ́, táwọn èèyàn sì ń pariwo bí wọ́n ṣe ń sá àsálà fún ẹ̀mí ara wọn.
Adarí ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì Israel ní èèyàn márùndínláàádọ́rin (65) káàkiri orílẹ̀ èdè náà ló farapa níbi ikọlù ọ̀tún yìí
Agbẹnusọ kan sọ pé nǹkan bàjẹ́ gidi ní ilé ìwòsàn náa;a àti pé wọ́n ti ń sọ fáwọn èèyàn láti kúrò ní agbègbè náà nítorí àwọn kẹ́míkà olóró tó ṣeéṣe kó máa wọnú afẹ́fẹ́ báyìí.
Níṣe ni àwọn ọmọ ogun àtàwọn ọlọ́pàá, tó fi mọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ti kún ié ìwòsàn náà fọ́fọ́.
Ọ̀kan lára àọn ọmọ ogun tó ń ṣọ́ ilé ìwòsàn náà sọ pé nǹkan bàjẹ́ púpọ̀ àmọ́ kò sí ẹni tó farapa nínú ìkọlù sílé ìwòsàn náà.
Ẹ̀wẹ̀, adarí ètò nìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì Israel, Magen David Adom sọ pé èèyàn márùndínláàádọ́rin (65) káàkiri orílẹ̀ èdè náà ló farapa níbi ikọlù ọ̀tún yìí táwọn ń fún ní ìtọ́jú.
Ó ní bàbá àgbàlagbà kan tí ọjọ́ orí rẹ̀ ti lé ní ọgọ́rin ọdún, àwọn ìyá àgbàlagbà méjì míì ti ọjọ́ ori wọ́n ti lé ní àádọ́rin ni wọ́n wà ní ẹsẹ̀ kan ayé ẹsẹ̀ kan ọ̀run báyìí.
Adom ṣàlàyé pé àwọn yòókù ni ìfarapa kò tó ti àwọn yìí àmọ́ táwọn náà ti ń gba ìtọ́jú, tó sì jẹ́ pé lásìkò tí wọ́n ń gbèrò láti sá lọ síbi tí ààbò wà ni ìkọlù náà wáyé.
Olóòtú ìjọba Israel Benjamin Netanyahu kọ sójú òpó X rẹ̀ ní òwúrọ̀ yìí pé igbá tí Iran fi wọn ikà ni àwọn fi máa da padà sí Tehran lórí ìkọlù tí wọ́n ṣe sílé ìwòsàn àtàwọn ilé ìgbé àwọn aráàlú.
Bákan náà ni ààrẹ Israel, Isaac Herzog sọ pé Iran mọ̀ọ́mọ̀ ṣèkọlù sáwọn èèyàn tó wà nílé ìwòsàn, tó sì ń jẹ́ ìràntí ìdí táwọn ṣe bẹ̀rẹ̀ ìkọlù náà ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀.
Iléeṣẹ́ ológun tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé ìwòsàn la fẹ́ ṣèkọlù sí kìí ilé ìwòsàn gangan – Iran

Oríṣun àwòrán, Reuters
Iléeṣẹ́ ìròyìn Iran ti sọ̀rọ̀ pé kìí ṣe ilé ìwòsàn Soroka Hospital ni àfojúsùn àwọn lórí ìkọlù tuntun tó wáyé ní òwúrọ̀ òní sí Israel bíkòṣe iléeṣẹ́ ológun tó wà ní ẹ̀gbẹ́ ilé ìwòsàn náà.
Gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ ìròyìn IRNA ṣe sọ, àwọn iléeṣẹ́ ológun Israel "command and intelligence (IDF C4i) headquarters" àti "army intelligence camp" tó wà ní Gav-Yam Technology Park ni àfojúsùn wọn.
Wọ́n ní ìbúgbàmù tó wáyé láwọn iléeṣẹ́ ológun náà ló dé ilé ìwòsàn Soroka àti pé kò bá nǹkan jẹ́ púpọ̀ nílé ìwòsàn náà.
Israel ṣèkọlù sáwọn iléeṣẹ́ ìpèsè ohun ìjà ogun Iran
Ṣáájú ni iléeṣẹ́ ológun Israel ti kéde ní alẹ́ ọjọ́rú pé àwọn ti ṣèkọlù sí oríkò tí Iran ń kó nǹkan ìjà ogun tí wọ́n fi ń pèsè "nuclear weapons" tó wà ní Natanz, Iran sí.
Iléeṣẹ́ ológun Israel, Israel Defense Forces (IDF), sọ pé àwọn nǹkan tó lágbára láti fi le ṣe ohun ìjà olóró ni Iran kó sí inú ilé náà, tí wọ́n sì ti ń wá ọ̀nà láti pèsè àwón ohun ìjà olóró ọ̀hún kíákíá.
Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí Israel ń ṣe ìkọlù sí Natanz láti ọ̀sẹ̀ kan tí ìkọlù ti ń wáyé láàárín àwọn orílẹ̀ èdè méjéèjì.
Adarí àjọ tó ń mójútó àwọn ohun ìjà ní àgbáyé sọ fún BBC pé ó ṣeéṣe káwọn ohun ìjà tó wà ní Natanz ti bàjẹ́ lẹ́yìn ìkọlù Israel lọ́jọ́ Ẹtì tó kọjá.
Israel ti fẹ̀sùn kan pé Iran fẹ́ fi àwọn "uranium" tó ń kó jọ ṣe àwọn ohun ìjà olóró èyí tí wọ́n le fi pèsè àdó olóró "nuclear bombs".
Bákan náà ni IDF tún ní àwọn ṣe ìkọlù sí ibi tí Iran ti ń pèsè "plutonium" ní Arak.
Wọ́n ní àwọn ọkọ̀ òfurufú ogójì ni àwọn ń lò láti fi ṣe ìkọlù sí gbogbo ibi tí Iran ti ń pèsè àwọn ohun ìjà olóró, ibi tí wọ́n ti ń tò wọ́n papọ̀ àtàwọn ibi tí wọ́n ti ń pèsè àwọn ohun ìjà òfurufú.
Ṣùgbọ́n orílẹ̀ èdè Iran tún ṣe àtẹnumọ rẹ̀ pé àwọn ohun ìjà táwọn ń kó jọ kìí ṣe láti fi jà tí wọ́n sì ń ké pe àwọn orílẹ̀ èdè tó wà lábẹ́ àjọ IAEA láti bu ẹnu àtẹ́ lu ìkọlù Israel.
Bákan náà ni iléeṣẹ́ ìròyìn Iran, IRNA sọ pé Iran ti fẹjọ́ ìkọlù Israel náà sun IAEA pé Israel ń tẹ òfin tó de ṣíṣe ìkọlù sí sáwọn iléeṣẹ́ ìpèsè nuclear lójú mọ́lẹ̀.
Wọ́n ní kò sí ẹnikẹ́ni tó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sínú ìkọlù tí Israel ṣe sí iléeṣẹ́ ti Arak.
Ṣé Trump máa dá sí ogun Israel àti Iran?
Ààrẹ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ti sọ pé ọ ṣeéṣe kí òun kún Israel lọ́wọ́ lórí ogun tó ń gbé ti Iran tàbí kí òun má dá si.
Ó ní kò sí ẹnikẹ́ni tó mọ nǹkan tí òun yóò ṣe lórí ogun náà.
Èyí ni ìdáhùn Trump nígbà tí wọ́n bi í léèrè pé ṣé ó máa ṣèkọlù sáwọn iléeṣẹ́ ìpèsè ohun ìjà ogun Iran.
Ṣáájú ni ìròyìn sọ pé ó ti buwọ́lu èrò láti ṣèkọlù sí Iran àmọ́ tí kò ì tíì gbé ìgbésẹ̀ pẹ̀lú ìrètí pé Iran máa gbà láti jọ̀wọ́ àwọn iléeṣẹ́ ìpèsè ohun ìjà nuclear rẹ̀.
Ṣùgbọ́n ó ṣeéṣe kí èyí má wáyé nítorí Iran sọ pé òun kìí dúnàádúrà nígbà tí òhun bá wà lábẹ́ ìdúnkokò.
Olùbádámọ̀ràn fún Trump tẹ́lẹ̀ rí lórí ètò ààbò, KT McFarland sọ pé Trump máa dúró de ìgbà ìkẹyìn kó tó gbé ìgbésẹ̀ kankan.
Ẹ̀wẹ̀, igbákejì mínísítà fọ́rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè ní Iran, Kazem Gharibabadi ti ṣèkìlọ̀ fún Donald Trump láti rò ó dáadáa kó tó darapọ̀ mọ́ Israel láti ṣèkọlù sí Iran.
Ó ní tí Israel bá fi lè darapọ̀ mọ́ Israel, Iran kò ní ní ohun míì láti ṣe ju kí wọ́n ohun èlò rẹ̀ láti fi kọ́ wọn lọ́gbọ̀n.
Ó fi kun pé ìmọ̀ràn àwọn sí Amẹ́ríkà nip é kí wọ́n máa wò bí wọ́n ṣe ń wò tí wọn kò bá le dá Israel lẹ́kun.
Ó sọ pé gbogbo àwọn tó ń ṣe ìpinnu fún Iran ni wọ́n ti ń ro ohun tí wọ́n lè ṣe.















