World Sickle Cell Day: Wo ìdààmú méje tí aláìsàn SS ń là kọjá àmọ́ tí kò le sọ

Ni igba akọkọ ti wọn yoo ṣe ayajọ ọjọ aisan foniku-fọlande ti a mọ si Sickle Cell, ajọ isọkan agbaye lo kọkọ ṣe agbekalẹ ayajọ naa lọdun 2008.
Wọn ṣe agbekalẹ ayajọ naa lati akiyesi awọn eeyan si aisan foniku fọladide ati idojukọ tawọn to n ṣaisan yii nla kọja yika agbaye.
Lẹyin ayajọ yii ni ajọ isọkan agbaye wa ya gbogbo ọjọ Kọkandinlogun, oṣu kẹfa ọddun sọtọ lati maa ṣe ayajọ ipolongo aisan foniku fọla dide lagbaye.
Ẹwẹ, oju awọn alaisan yii lasan ni ọpọ eeyan n wo ṣugbọn gẹgẹ bi iwadi ṣe fi han, ọ̀pọ̀ nnkan ni ẹ ko mọ tabi ti ẹ ko tii gbọ ri nipa awọn to n ṣaisan foniku fọla dide pọ.
Gẹgẹ bi Dokita ọmọ Naijiria kan, to tun wa ni ilu London fun imọ ẹkọ, Ogunboye Igbekele ṣe sọ fun BBC Yoruba, ọpọ nnkan ni awọn eeyan ti mọ tẹlẹ nipa awọn alaisan foniku fọla dide bii ki egungun maa ro wọn.
Bakan naa ni dokita Igbekele tun mẹnuba aya didun, inu rirun, ki oju wọn maa ni awọ yẹlo rẹsurẹsu, ati ki wọn maa padanu ẹjẹ pupọ.
Sugbọn o wa mẹnuba ohun meje pataki to jẹ idaamu to n ba ọkan awọn eeyan to ni aisan foniku-fọlande finra eyi ti ẹ ko mọ tabi to nira fun wọn lati sọ sita.

Wo ohun meje ti o ko mọ nipa idaamu awọn eeyan to ni aisan foniku-fọladide
Ibẹru Iku ati idamu inu ọpọlọ:
Ibẹru Iku ati idamu inu ọpọlọ ni aisan foniku- fọlande nitori pe ọpọlọpọ wọn lo n bẹru iku ṣugbọn ti wọn ko le sọ ọ jade.
Nilẹ Afirika paapaa ju lọ ni Naijiria, bi wọn ba sọ ọ sita, awọn eeyan a ni wọn o nigbagbọ.
Awọn eeyan yii kan naa ni wọn wa ni nilẹ Yoruba, ti igbagbọ si wa pe bi wọn ba ti le kọja ọgbọn ọdun laye, wọn ti ye aisan naa niyẹn.
Tori eyi, awọn agba a maa gba awọn alaisan foniku-fọladide nimọran ki wọn tete fẹ ọkọ tabi iyawo ki wọn le tete bi ọmọ saye tori ti wọn o ba ku.
Ibẹru ta ni yoo fẹ mi lọkọ abi laya?
Nigba miran, wọn ko ki n fẹ sọ ẹya ẹjẹ (genotype) wọn tori bi ẹlomii to ti yo ifẹ wọn. tẹlẹ ba gbọ eyi, o ṣeeṣe ko fẹsẹ fẹẹ ki ifẹ naa ka kuro loju rẹ
Eyi ko ṣẹyin lilọ họsibitu lonii, họsibitu lọla, daku lonii, ji lọla, wọn ko ki n le sọ fun ẹnikẹni ju ki wọn bo o mọra wọn lọkan lọ.
Nini iriri wahala lile lasiko nnkan osu obinrin:
Ọpọlọpọ awọn obinrin to jẹ alaisan foniku fọlande lo maa n wọ inu ironu tori inira ti wọn yoo la kọja lasiko nnkan osu wọn.
Irufẹ awọn obinrin bẹẹ ni yoo maa lọ inu mọlẹ, tabi la inira nla kọja lasiko ti wọn ba n se nnkan osu lọwọ.
Ọpọ wọn si lo maa n nira fun lati sọ eyi sita tabi sọ fun awọn ololufẹ wọn, ti wọn yoo si se isẹlẹ naa ni iso inu ẹku, amumọra.
Sugbọn fun awọn obinrin to ni aisan naa, amọ ti irora pọ fun l;asiko ti wn n se nnkan osu, ile iwosan lo maa n gba iru awọn eeyan wọnyi silẹ.
Aisan ojoojumọ lo maa n jẹ ki ọpọ obi mọ pe ọmọ oun ni aisan foniku-fọlande
Nigba mii, obi le ma tete ri apẹrẹ aisan yii lara ọmọ ti wọn ba ṣẹṣẹ bi titi yoo fi pe oṣu mẹfa tabi ọdun kan.
Koda, o di igba ti ọmọ naa ba bẹrẹ si ni ṣe aisan tabi to n padanu ẹjẹ.
Lati ipasẹ eyi ni dokita tabi nọọsi fi le mọ pe irufẹ ọmọ to n se aisan leralera yii ni aisan foniku-fọlande
Njẹ ẹya ẹjẹ foniku-fọlande le e yipada?
Ibeere to tun maa n da ọkan awọn obi to ba bi ọmọ to ni aisan foniku-fọlande ni pe se o seese ki ẹjẹ arun se paarọ tabi ko yipada lọjọ iwaju?
Amọ Dokita Igbekele jẹ ko di mimọ pe ni ilana iṣegun oyinbo, ko ṣee ṣe rara ki ẹya ẹjẹ eeyan yii pada.
O ni o ri bẹẹ nitori pe awọn onimọ iṣegun oyinbo ko gbagbọ ninu eyi rara lodi si bi awọn kan ṣe maa n ti ẹsin bọ ọ pe adura maa n yi ẹya ẹjẹ pada.
Awọn wonyii a maa rọ igbagbọ wọn mọ ọ, ti yoo si ri bẹẹ bi wọn ba tun ayẹwo ṣe.
Ẹwẹ, dokita ṣalaye pe bi wọn ba gbe eroja inu egungun (Bone Marrow) ẹni to jẹ AA, fun apẹrẹ, sinu ara ẹni to jẹ SS lati parọ rẹ, eyi ṣeeṣe, o si wa lati wo o san ni.
Sugbọn eyi ko yi SS to ti wa ninu gbogbo ẹya ara to ku pada.
Idaamu nipa iru eeyan ti alaisan foniku-fọlande le e fẹ:
Lara idaamu to tun maa n gba ọkan awọn eeyan to ni aisan foniku-fọlande ni iru eeyan ti wọn le fẹ bii ọkọ tabi aya.
Eyi si jẹ koko ohun ti wọn fẹ mọ ati iru eeyan ti wọn ko gbudọ fẹ laelae.
Dokita Igbekele sọ pe SS ko gbudọ daba rara lati fẹ ẹni to ni ẹjẹ AS, o ni "agbako gba a ni eleyii".
"Awọn ẹjẹ eeyan mii to tun wa ti alaisan foniku-fọlande ko gbọdọ fẹ ni ẹni to ni ẹjẹ AC SC ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Idi ni pe ọmọ iya kan naa ni awọn ẹjẹ yii pẹlu ẹjẹ SS".
Ẹni to ni ẹjẹ AA nikan ni alaisan foniku-fọlande le fẹ:
Dokita Igbekele wa sisọ loju rẹ pe ireti si wa fun awọn alaisan foniku fọlande lati fẹ ọkọ tabi aya lai naa pe gbedeke wa lori iru ẹni ti wọn le fẹ.
"Awọn eeyan to ni ẹjẹ AA nikan ṣoṣo ni ẹni to ni ẹjẹ SS le fẹ.
Bi awọn eeyan to ni ẹjẹ SS ba gbiyanju lati fẹ awọn ẹlẹjẹ miran yatọ si AA, idaamu nla lọjọ ọla ni fun wọn.
Tori naa, o yẹ kawọn eeyan to ni ẹjẹ foniku fọlande ni idanilẹkọ to kun nipa irufẹ eeyan ti wọn le fẹ lati ipasẹ ẹya ẹjẹ ti onitọun ni.















