"Ó dàbí pé ìjọba ti gbàgbé wa ni àwọn agbébọn ṣe ń kọlù wá lọ́pọ̀ ìgbá, ẹ̀mí mọ́kàǹlá ló bọ́ lọ́tẹ̀ yìí"

Aworan

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Eha-Amufu jẹ agbegbe kan ni ijọba ibilẹ Isiuzo nipinlẹ Enugu, ti ilu naa si n sọfọ bayii lẹyin ti awọn agbebọn kọlu agbegbe ọhun, ti wọn si ṣekupa eeyan mọkanla.

Iṣẹlẹ yii waye lọjọ Aje, ọjọ Kẹrinledinlogun oṣu kẹfa ọdun 2025, lasiko ti awọn araalu n sun lọwọ.

Asiko yii ni awọn agbebọn yawọ agbegbe naa, ti ki si ṣe igba akọkọ ti irufẹ iṣẹlẹ naa yoo waye.

Ọpọ araalu lo pejọ si agbadede ilu lẹyin ti wọn gbọ iroyin ikọlu naa.

Olugbe agbegbe naa, Ifeanyi Ogenyi, sọ fun BBC bi iṣẹlẹ naa ṣe waye, to si jẹ ko di mimọ pe awọn daradaran ti kuro ninu igbo ti wọn wa tẹlẹ, ti wọn si n wa sinu ilu lati ṣekupa awọn araalu.

"Agbebọn pa ọpọ eeyan ni Mgbuji, wọn tun pa eeyan mọkanla mii ni Aguamaede, a ko ni ounjẹ mọ ni Eha-Amufu tori ko si ẹnikẹni to fẹ lọ si oko mọ"

Ogenyi ṣalaye pe o da bi pe ijọba ti gbagbe awọn araalu naa bi wọn ko ṣe ti i gbe igbesẹ kankan lori iṣẹlẹ naa.

O ni awọn araalu ko ni ohun ija kankan lati da bobo ara wọn.

"Awọn ẹsọ alabo ibilẹ ko le da ṣe nikan, ijọba ni lati ran wa lọwọ lori ọrọ awọn ọdaran yii.."

"Ọsẹ to kọja, wọn ṣekupa ọpọ eeyan ni Ilu Mgbuji, ni ọsẹ yii wọn ti ṣekupa eeyan mọkanla mii ni Aguamaede."

"A ko ni ounjẹ mọ ni Eha-Amufu. Ko si ẹnikẹni to fẹ lọ si oko mọ, nnkan to jẹ ohun idanimọ wa."

Awọn araalu kan ni awọn ri ọkọ ofurufu to n kọlu awọn agbegbe naa ṣugbọn awọn kan ni awọn ko ri nnkan to jọmọ bẹ.

BBC ko si le e fidi eyi mulẹ.

Nigba ti BBC kan si ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Enugu nipa iṣẹlẹ, wọn ko dahun si ipe ati atẹjisẹ wa lori foonu ṣaaju ti a to gbe iroyin yii sita.

Iṣekupani awọn eeyan Eha-Amufu ni lati dopin - Peter Obi

Peter Obi, oludije sipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu Labour Party ni ọdun 2023 ti bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ ipaniyan to waye niluu Eha-Amufu.

O ransẹ ibanikẹdun si awọn idile ti iṣẹlẹ naa kan pẹlu atẹjisẹ to fi sori opo ayelujare X rẹ.

"Ikọlu to n waye ni Eha-Amufu ti n waye ti pẹ. Ikọlu yii ni lati dopin ki awọn eeyan le ni alaafia.

"A ko ni duro lasan ka ma wo, ki wọn ma ṣekupa awọn agbẹ , ti ọpọ ninu wọn ko si le lọ si oko mọ lati lọ ko ere oko wọn wale."

Aworan Gomina ipinlẹ Enugu, Peter Mbah

Oríṣun àwòrán, Others

Enugu ni ìpínlẹ̀ tí ààbò ti péye jù ní Naijiria

Gomina Peter Mbah wa kede pe kawọn ọmọ Naijiria mase tẹti si awọn atanijẹ nipa eto aabo ni ipinlẹ Enugu, o ni ipinlẹ naa ni aabo ti peye ju lọ lorilẹede Naijiria.

Mbah sọ eyi lasiko to n gba alejo ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa, AIG, Abayomi Oladipo ni ọjọru, ọjọ Kọkandinlogun oṣu kẹfa ọdun 2025.

Eyi waye lẹyin ti awọn agbebọn ṣekupa awọn eeyan ilu Eha Amufu.

Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ni Isi-Uzo ti mu eeyan meji ti wọn fẹsun kan pe awọn lo gbe iroyin fun awọn agbebọn to ṣekọlu si agbegbe naa.

Ijọba ipinlẹ Enugu ko ti sọ ohunkohun nipa iṣẹlẹ to waye lọjọ Aje naa.

Ṣugbọn oṣiṣẹ ijọba to ba BBC sọrọ jẹ ko di mimọ pe, ọwọ ti tẹ awọn eeyan to n ran awọn agbebọn naa lọwọ.

O ni ijọba n siṣẹ lori bi alaafia yoo ṣe jọba ni ilu naa ati ni ipinlẹ Enugu.

O tun tẹsiwaju pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo fi atẹjade sita lori iṣẹlẹ naa ni aipẹ.

Wo iye igba ti awọn agbebọn ti kọlu Eha-Amufu

Ikọlu yii ki n ṣe akọkọ tabi ẹẹkeji ni agbegbe Eha-Amufu nijọba ibilẹ Isiuzo nipinlẹ Enugu.

Awọn abule ti awọn agbebọn naa kọlu ni Mgbuji, Aguamaede, Okpokwu, Ogboete, Afo Isiala, Amaeze ati bẹ bẹ lọ.

Gẹgẹ bi awọn eeyan abule ṣe sọ, ikọlu yii ma n waye loorekoore.

Ni oṣu karun un ọdun 2022, awọn agbebọn ṣekupa ọdọ kan, Ejike Odo, ti wọn si tun ṣe ẹgbọn rẹ leṣe nigba ti wọn fẹ dola ẹmi aburo wọn obinrin ti awọn agbebọn kọlu ninu igbo.

Ni oṣu kọkanla ọdun 2022, ni ilu Aguamaede, awọn agbebọn kọlu awọn araalu ti wọn si ṣekupa ọpọ lasiko ti wọn n ṣe ijọsin lọwọ.

O le ni obinrin 500 lati abule Mgbuji, Abo ati Aguamaede ti wọn ṣe ifẹhonuhan lọjọ karun un oṣu kẹta ọdun 2025 lori ọrọ ikọlu yii.