'Gbogbo ìlú wa ló ti dahoro nítorí ìkọlù àwọn agbébọn'

Àwọn agbébọn tó gbé ohun ìjà olóró dání

Oríṣun àwòrán, AFP

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Gbogbo àwọn èèyàn ìlú Tozai ní ìjọba ìbílẹ̀ Isa, ìpínlẹ̀ Sokoto ni wọ́n ti sá kúrò nínú ìlú wọn báyìí nítorí ìkọlù àwọn agbébọn tó ń wáyé níbẹ̀ ní gbogbo ìgbà.

Ìròyìn ní níṣe ni àwọn èèyàn ìlú náà ti sálọ sáwọn ìpínlẹ̀ mìíràn lójúnà àti móríbọ́ lọ́wọ́ àwọn agbébọn náà.

Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn, gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ṣe sọ, ló ti pàdánù ẹ̀mí wọn sọ́wọ́ àwọn agbébọn náà lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí, tí wọ́n sì tún jí àwọn míì gbé.

Aráàlú Tozai kan tí kò fẹ́ kí a dárúkọ òun sọ fún BBC pé láìpẹ́ yìí ni àwọn agbébọn náà jí èèyàn mẹ́wàá gbé ní ìlú àwọn, tí wọ́n sì tún pa àwọn méje míì.

Ó ní àwọn èèyàn kan ti sálọ sí ìlú Isa, àwọn míì ti sálọ sí ìpínlẹ̀ Zamfara, àwọn míì ti gba ìpínlẹ̀ Ondo lọ, táwọn míì sì tún mórílé ìlú Auchi ní ìpínlẹ̀ Ondo.

"A ní àwọn tó sá lọ sí Lokoja ní ìpínlẹ̀ Kogi, àwọn míì lọ sí Zaria ní ìpínlẹ̀ Kaduna nítorí wàhálà àwọn agbébọn tó ń wáyé ní ìlú wa lemọ́lemọ́."

Àwọn èèyàn ìlú náà wá rọ ìjọba ìpínlẹ̀ náà àtàwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò láti báwọn wá ojútùú sí ọ̀rọ̀ ààbò ìlú náà káwọn èèyàn le padà sí ibi ibùgbé wọn, kí wọ́n lè máa bá ìgbé ayé wọn lọ bó ṣe yẹ.

Ẹni náà sọ pé ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ló wà ní agbègbè àwọn àmọ́ tí kò sí ẹ̀ṣọ́ ààbò kankan ní Tozai èyí tó ń fún àwọn agbébọn náà ní ìgboyà láti máa ṣe ìkọlù sí wọn ní gbogbo ìgbà.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ó ní "ohun tó burú jù níbẹ̀ ni pé àsìkò òjò tí a wà yìí ló yé káwọn èèyà máa dáko ṣùgbọ́n gbogbo èèyàn ló tis á kúrò nínú ìlú. Báwo la ṣe fẹ́ dáko? Wàhálà ńlá ni èyí.

"Nígbà tí àwọn tálákà kò bá ríbi dáko, ebi ńlá ló máa dá sílẹ̀ fáwọn èèyàn nínú ìlú pàápàá lásìkò tí gbogbo nǹkan le báyìí ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà."

Bashir Altine Guyawa, ẹni tó jẹ́ olórí ẹ̀ka ètò ìdájọ́ ní ìpínlẹ̀ náà sọ fún BBC pé gbogbo àwọn ìlú tó wà ní ìlà oòrùn ìpínlẹ̀ Sokoto ni wọ́n ń kojú ìkọlù àwọn agbébọn, tí gbogbo wọn sì ń ṣọ̀fọ̀.

Ó ní kò sí àníàní pé ìkọlù ń wáyé ní ìlú Tozai tó sì jẹ́ pé ọwọ́ àwọn agbébọn ló ti ń wá, bó ṣe jẹ́ pé orúkọ àwọn tí wọ́n ṣe ìkọlù sí ni àwọn mọ̀ tó fi mọ́ àwọn àgbàlagbà.

Ó fi kun pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló wà nílé ìwòsàn tí wọ́n ti ń gba ìtọjù látàrí ìkọlù àwọn agbébọn náà.

Bashir Altine tún ṣàlàyé pé yàtọ̀ sí pé àwọn agbébọn náà ń pa àwọn aráàlú, ó ní níṣe ni wọ́n ń jí àwọn èèyàn gbé bò ṣe wù wọ́n tó fi mọ́ ìyàwó tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ kan.

"Nǹkan tójú àwọn èèyàn ìlà oòrùn Sokoto ń kojú kò kéré rárá tó fi mọ́ àwọn tó wà ní Shinkafi," ó sọ.

Ìlà oòrùn ìpínlẹ̀ Sokoto èyí tí ìjọba ìbílẹ̀ Isa àti Sabon Birni wà lábẹ́ rẹ̀ jẹ́ agbègbè kí ìkọlù àwọn agbébọn ti ń wáyé lemọ́lemọ́.

Yàtọ̀ sí ìpínlẹ̀ Sokoto, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpínlẹ̀ ní ẹkùn àríwá Nàìjíríà ni ètò ààbò ti mẹ́hẹ báyìí.

Ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni àwọn agbébọn yawọ ìlú Yelwata ní ìpínlẹ̀ Benue tí wọ́n sì pa èèyàn tó lé ní ọgọ́rùn-ún gẹ́gẹ́ bí àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní Nàìjíríà, NEMA ṣe sọ.