APC àti PDP Osun bẹ̀rẹ̀ wàhálà míì lórí owó àwọn ìjọba ìbílẹ̀, ara kò rọ okùn, kò rọ adìẹ

Gomina Ademola Adeleke ti figbe ta pe ijọba apapọ ati banki apapọ ilẹ wa ti fẹ fi ọgbọn san owo awọn ijọba ibilẹ ọgbọn to wa nipinlẹ Osun si apo awọn oloselu aladani kan.
Bakan naa ni gomina Adeleke, ninu atẹjade ti Kọmisana fun ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ, Dosu Babatunde fisita, wa n naka aleebu si banki apapọ ilẹ wa ati ọọfisi olusiro owo agba nilẹ yii .
Ẹsun ti ijọba Osun fi kan ileesẹ mejeeji naa ni pe apo asunwọn awọn alaga ibilẹ labẹ ijọba gomina Oyetola to kogba wọle ni wọn fẹ dọgbọn san owo to tọ sawọn ijọba ibilẹ nipinlẹ Osun si.
Ariwisi yii lo mu ki ikọ iroyin BBC Yoruba morile ilu Osogbo lati se iwadii awuyewuye naa, ti a si kan si Kọmisana fun ọrọ ijọba ipinlẹ lori awuyewuye naa
A n kilọ fun banki apapọ apapọ ilẹ wa, CBN, lati mase san owo ijọba ibilẹ si àsùnwọ̀n awọn ti wọn jẹ gaba si kansu bayii - Ijọba Osun
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Dosu Babatunde salaye pe ile ẹjọ kotẹmilọrun ti fi ọwọ osi juwe ile fun awọn alaga ijọba Ibilẹ ti gomina ana, Gboyega Oyetola yan sipo, lati ọjọ Kẹwa osu Keji ọdun 2025 yii.
Babatunde ni awọn gbọ wi pe, banki ijọba apapọ fẹ san owo fun awọn alaga ti ile ẹjọ kotẹmilọrun ti fi ọwọ osi juwe ile fun ni owo awọn Kansu to wa ni Osun.
"A wa n kilọ fun banki apapọ apapọ ilẹ wa, CBN, lati mọ dan iru asise naa wo rara, pe ki wọn san owo ijọba si àsùnwọ̀n awọn ti wọn jẹ gaba si kansu bayii.
Ile ẹjọ kotẹmilọrun si ti gbe idajọ miran jade ni ọjọ Kẹtala osu Kẹfa ọdun yii wi pe, ẹgbẹ oselu APC ko ni anfani lati tun bẹrẹ ẹjọ́ ti ile ẹjọ kotẹmilọrun ti kọkọ danu tẹlẹ mọ rara labẹ ofin.
Ẹni to ba gba owo ijọba ibilẹ Oṣun lọna aitọ yoo fimu kata ofin - Olori ile asofin
Olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọṣun, Hon. Adewale Ẹgbẹdun naa ti kilọ fun awọn alakoso banki apapọ ilẹ wa lati maṣe ko owo to tọ sijọba ibilẹ Osun fun awọn alaga Kansu tẹlẹ to ni wọn jẹ gaba si ofiisi ijọba ibilẹ bayii.
"Ninu ipinnu ti awa ọmọ ile igbimọ aṣofin ni Osun ṣe ni ọjọ Kọkandinlogun osu Kẹfa ọdun 2025, ti Olori ile si ka jade nibi ijọko ile, ni a ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ naa.
A koro oju si bi awọn alaga ti ajọ eleto idibo ijọba ibilẹ nipinlẹ Ọṣun bura fun lọdun 2022, ṣugbọn ti idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun ti le kuro nibẹ, ṣe tun n lọ kaakiri bayii, ti wọn n pe ara wọn ni alaga kansu.
Awọn aṣofin Osun si ti kede pe awọn alaga atawọn kasilọ ti awọn araalu dibo yan lọjọ kejilelogun oṣu keji ọdun yii nikan ni wọn jẹ ojulowo alaga labẹ ipin kinni, abala keje iwe ofin ọdun 1999.
Tori eyi, ofuutu-fẹẹtẹ lasan ni ariwo ti awọn alaga idibo ọjọ kẹẹdogun oṣu kẹwa ọdun 2022 n pa kaakiri pe ile ẹjọ kotẹmilọrun da awọn pada, ko lẹsẹ nilẹ, bẹẹ ni ko ridi joko labẹ ofin."

Egbedun fikun pe yiyan ẹnikẹni lati maa ṣakoso awọn ijọba ibilẹ lodi si ofin. Ile igbimọ aṣofin yii si bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ti banki apapọ ilẹ wa fẹẹ gbe lati san owo ijọba ibilẹ si asunwọn awọn ti wọn n pe ara wọn ni alaga ati kasilọ lẹyin ti ile ẹjọ ti yọ wọn.
O tẹsiwaju pe awọn oludari fun eto iṣuna ati ti akoso nikan ni wọn lẹtọọ labẹ ofin lati bu ọwọ lu sọwedowo to jẹ tijọba ibilẹ nibamu pẹlu abala kẹrinla akọsilẹ ilana iṣakoso ijọba ibilẹ l'Ọṣun.
"Ohun to n ṣẹlẹ nipinlẹ Ọṣun bayii jẹ ẹdun ọkan fun wa, a si n pe oluṣiro owo agba lorileede yii ati kọmiṣanna fun eto iṣuna lati tete yọnda owo to jẹ ti awọn ijọba ibilẹ l'Ọsun kiakia.''
Awọn aṣofin naa waa ṣeleri lati lo ilana ofin lati fiya jẹ ẹnikẹni to ba ṣe lodi si awọn ipinnu wọn yii eleyii to wa labẹ ilana ofin lati daabo bo iṣejọba lẹsẹkuku.
Ko si idajọ ile ẹjọ kankan to fagile idibo ijọba ibilẹ to waye labẹ gomina Oyetola, ṣe làwọn agbejoro ẹgbẹ oṣelu PDP mọ-on mọ n ṣi awọn ara ilu lọna ni - APC
Ọna lati gbọ ti ẹnu igun keji, tii se ẹgbẹ oselu APC ti wọn fi ẹsun kan ninu isẹlẹ yii, lo gbe BBC Yoruba de ọdọ agbenusọ ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ ọsun, Kola Olabisi.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Kola Olabisi, ni idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun to da awọn alaga ijọba Ibilẹ ati kasilọ pada ni ọjọ Kẹwa osu Keji ọdun yii si wa sibẹ.
Olabisi, fi kun ọrọ rẹ wi pe, ko si idajọ ile ẹjọ kankan to fagile idibo ijọba ibilẹ to waye losu Kẹwa Ọdun 2022, ṣe làwọn agbejoro ẹgbẹ oṣelu PDP mọ-on mọ n ṣi awọn ara ilu lọna ni.
Olabisi, wa rọ awọn olugbe ipinlẹ ọsun lapapọ lati lọ fi ọkan balẹ tori pe, otitọ yoo fi ara han laipẹ yii.
Ki lo fa aawọ ijọba ibilẹ ni Osun?
Gomina tẹlẹ nipinlẹ Osun labẹ asia ẹgbẹ oselu APC lo seto idibo sawọn ijọba ibilẹ nigba to ku diẹ ki saa rẹ kogba wọle.
Ẹgbẹ oselu PDP si gba ile ẹjọ lọ lati tako igbesẹ naa, bi Gomina Ademola Adeleke to gba ipo lọwọ Oyetola, tii se asoju ẹgbẹ oselu PDP se wọle sipo naa, lo juwe ọna ile fun awọn alaga Kansu labẹ APC.
Bakan naa, ni ile ẹjọ kotẹmilọrun gbe idajọ rẹ kalẹ lori ẹjọ ti ẹgbẹ PDP pe tako awọn alaga ijọba ibilẹ ti Oyetola dibo yan.
Ileẹjọ kotẹmilọrun naa ni igbesẹ lati dibo yan awọn alaga kansu ọhun ko tọna labẹ ofin.
Gomina Ademola Adeleke naa wa seto idibo miran lati yan awọn alaga kansu tuntun sipo.
Ẹgbẹ oselu APC naa tun gba ileẹjọ kotẹmilọrun mii lọ, ti idajọ si waye ni ọjọ Kẹwa osu Keji ọdun 2025 yii.
Idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun naa si lo da awọn alaga ijọba ibilẹ ti gomina ana, Oyetola seto idibo fun labẹ ẹgbẹ oselu APC.
Lati igba ni wahala ati rogbodiyan ti ba ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP nipinlẹ Osun tori ọrọ ijọba ibilẹ yii, ti wọn si gbe ilẹkun awọn kansu ọgbọn to wa nipinlẹ naa ti pa.
Awọn osisẹ lawọn ijọba ibilẹ ọhun ko le lọ sibi isẹ, ti ijọba apapọ naa sig be ẹsẹ le awọn owo osoosu to tọ si awọn kansu yii.















