'Mo rí ọmọ orogún tó pa ìyá mi, àmọ́ mi ò fura pé nnkan tó wa ṣe nìyẹn'
Ọkan lara awọn ọmọ oloogbe Titilayo Falilat, ẹni ti iroyin sọ pe, ọmọ orogun rẹ, Malik, pa niluu Ilorin, ti ṣalaye bi iṣẹlẹ naa ṣe waye.
Ọjọ kejila, oṣu Kẹfaa, ọdun 2025, ni iṣẹlẹ a gbọ bo mi loju lo ṣẹlẹ lana niluu Ilọrin, to jẹ olu ilu ipinlẹ Kwara nigba ti ọmọ ọdun mẹtadinlogun kan ti wọn pe orukọ rẹ ni malik gun orogún ìyá rẹ Falilat Yusuf lọbẹ pa.
Iṣẹlẹ naa waye ni nnkan bi ago kan ọsan ana, lagbegbe Danialu ni Gaa Akanbi niluu Ilọrin.
BBC Yoruba ṣabẹwo si ile oloogbe lati mọ bi iṣẹlẹ ṣe waye.
Ọgbẹni yusuf Tesilim to jẹ ọkan lara awọn ọmọ oloogbe naa sọ pe, nnkan bi ago kan ọsan lẹyin ti awọn kirun Jimọh tan ni iṣẹlẹ naa waye.
O fikun pe, Malik jẹ ọmọ iyawo baba oun, to si gba a tọ ṣugbọn obinrin naa ati ọmọ rẹ n gbe ile mii ti baba awọn gba fun wọn ladugbo kan naa.
"Ṣaaju iṣẹlẹ yii ni wọn ti sọ pe Malik ko gbọdọ wa si ile wa mọ nitori pe o ma n jale."

Oríṣun àwòrán, Yusuf Teslim
'Mo ri Malik ko to o pa iya mi, amọ mi o kọbi ara si i'
O tẹsiwaju pe lọjọ ti afurasi naa pa iya oun, oun ti kọkọ pade rẹ nitosi ile naa lasiko ti oun n lọ si irun Jimọ, amọ ti oun ko kọbi ara si.
"Mo ro o lọkan pe, boya ole lo tun wa ja, ibi irun Jimọ t imo n lọ si ni ọkan mi wa."
Teslim salaye pe bi oun se n ti ibi irun Jimọh bọ oun ri Teslim to n fọwọ ni ita, bi o ṣe ri oun lo sa lọ.
Igba ti oun wọ le ni oun ba iya oun ninu agbara ẹjẹ ti oun si pariwo sita .
Ibẹ ni oun ti pariwo pe oun lo pa mama oun, bi awọn se n bi lere ni awọn ri ẹjẹ lara bata rẹ.
Ti awọn si ti fa a le awọn ọlọpaa lọwọ nibi to ti jẹwọ pe lootọ loun pa mama oun.



