Wo nǹkan mẹ́wàá tí obìnrin lè ṣe dáadáa ju ọkùnrin lọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bo tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan ni igbagbọ pe awọn ọkunrin lagbara ju obinrin lọ, iwadii ti fi han pe awọn nnkan kan wa t'awọn obinrin le ṣe dáadáa ju awọn ọkunrin lọ.
Fun àpẹẹrẹ, awọn obinrin máa n fara balẹ ju awọn ọkunrin lọ, wọn si tun maa n ni ifarada ju awọn ọkunrin lọ.
Bakan naa, awọn obinrin maa n ṣe itọju awọn ẹbi wọn ju awọn ọkunrin lọ.
Amọ, eyi ko tumọ sí pe awọn ọkunrin naa ko ni awọn abuda yìí, iyatọ to wa níbẹ ni pe awon obinrin ni awọn abuda yìí ju ọkùnrin lọ.
Wọnyii ni nnkan mẹwaa t'awọn obinrin le ṣe daadaa ju awọn ọkunrin lọ:
1. Ṣíṣe oniruuru iṣẹ pọ lẹẹkan naa

Oríṣun àwòrán, Women/UN
Awọn obinrin le ṣe oriṣiiriṣii iṣẹ pọ lẹẹkan naa gẹgẹ bi wọn ti maa n ṣiṣẹ ile.
Fun àpẹẹrẹ, obinrin kan le maa dana lọwọ, kí o tun maa fun ọmọ lọyan.
Obinrin yii kan naa tun le maa nu ilẹ ti yoo si tun maa ṣe nnkan mii.
Ile ẹkọ gíga fasiti ilu Glasgow lorilẹede Scotland gbe abọ iṣẹ iwadii kan jade to fidi rẹ mulẹ pe awọn obinrin ni abuda ki eeyan le ṣe oriṣiiriṣii nnkan lẹẹkan naa ju awọn ọkunrin lọ.
Awọn akọṣẹmọṣẹ ni Eledumare lo da awọn obinrin bẹẹ.
2. Kikọ ọgbọn

Oríṣun àwòrán, Women/
O ṣee ṣe k'awọn obinrin ma ja fafa bi awọn ọkunrin, ṣugbọn iwadii ti fi han pe obinrin maa n yara kọ nnkan tuntun ju ọkunrin lọ.
Ile ẹkọ giga fasiti Georgia & Columbia sọ ninu iwadii kan to ṣe wí pe awọn obinrin maa n fara balẹ lati kẹkọọ ju awọn ọkunrin lọ.
Iwadii mii tun fidi rẹ mulẹ pe obinrin le tọju nnkan ju ọkùnrin lọ.
Eyi lo jẹ ki wọn maa le ranti nnkan ju ọkùnrin lọ.
Iwadii naa sọ pe awọn abuda yìí lo le jẹ k'awọn obinrin kawe ju awọn ọkunrin lọ.
3. Titete pari ile ẹkọ
Eyi maa n ṣẹlẹ fun oriṣiiriṣii ìdí, akọkọ ni pe awon obinrin le ṣe oriṣiiriṣii nnkan lẹẹkan naa, wọn si tun ni ẹkọ biba eeyan sọrọ ju ọkunrin lọ.
Eyi le ran won lọwọ lẹnu ẹkọ wọn nile ẹkọ.
Awọn obinrin tun ni eroja ara to maa n fun iṣan ara ni okun, eyi yoo ṣe anfaani fun wọn lẹnu ẹkọ wọn.
Bo tilẹ jẹ pe awọn obinrin maa n koju oniruuru ìṣòro bi idẹyẹsi lẹnu iṣẹ at'awọn ìṣòro mii, iwadii fi idi rẹ mulẹ pe awọn obinrin ni abuda lati ṣaaju awọn ọkunrin pari eto ẹkọ wọn.
4. Ifarada
Abuda ṣiṣe orisiirisii nnkan pọ lẹẹkan naa fún àwọn obìnrin lanfaani lati ni ifarada ju awọn ọkunrin lọ.
Bakan naa, awọn obinrin tete maa n ṣe akiyesi kan ju awọn ọkunrin lọ
Iwadii tun fi idi rẹ mulẹ pe ọpọlọ awọn obinrin yatọ si ti ọkunrin, eyi lo si jẹ ki wọn ni ifarada ju awọn ọkunrin lọ.
Iwadii naa ko ṣai fi idi rẹ mulẹ pe loootọ lawọn obinrin ni ifarada ju ọkunrin lọ, amọ, abuda yìí ko ni ki won ma ṣe aarẹ.
5. Okun ara
Ko tii han gbangba idi ti ara awọn obinrin fi le dena aisan ju ọkunrin lọ, amọ, iwadii kan ti ṣalaye diẹ nipa idi ti o fi ri bẹẹ.
Ọkan lára àwọn idi yii ni pe awon obinrin máa n ṣe nnkan oṣu, wọn si maa n bimọ.
Eyi lo maa n jẹ ki ara le gbogun ti aisan tabi arun to ba fẹ wọ ara wọn.
Bakan naa ni iwadii tun fi idi rẹ mulẹ pe ara obinrin maa n pese kẹmika to n gbogun ti aisan ju ara ọkunrin lọ.
6. Awọn obinrin mọ iṣẹ jẹ ju ọkunrin lọ
Ko si ani-ani wi pe awọn obinrin lẹbun iba eeyan sọrọ ju awọn ọkunrin lọ.
Eyi ko tumọ si wi pe awọn ọkunrin naa ko mọ bi wọn ṣe n bawọn eeyan sọrọ, ṣugbọn awọn obinrin kan lẹbun naa ju awọn ọkunrin lọ ni.
Eleyii le ri bẹẹ tori pe awọn obinrin tete maa n mọ nnkan tawọn eeyan n la kọja.
Nitori naa, awọn obinrin ni abuda lati lo ẹya ara wọn fi ba eeyan sọrọ ja awọn ọkunrin lọ.
7. Ẹmi gigun

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iwadii ti fi han pe o kere tan, awọn obinrin maa n lo ọdun marun un laye ju awọn ọkunrin lọ.
Eyi ri bẹẹ nitori awọn kẹmika to wa lara awọn obinrin atawọn abuda kan ti Eledua da mọ wọn.
Igbe aye eeyan naa wa lara idi ti obinrin fi n pẹ laye ju ọkunrin lọ.
Fun apẹẹrẹ, awọn obinrin maa n lọ fun ayẹwo ara wọn nile iwosan ju awọn ọkunrin lọ.
Ara nnkan bayii lo n ṣokunfa bi awọn obinrin ṣe n maa n dagba ju ọkunrin lọ.
Onimọ nipa awọn arugbo ni fasiti Alabama l'Amẹrika, Steven Austard, naa sọ pe awọn obinrin maa n dagba ju awọn ọkunrin lọ.
8. Fifi eti silẹ gbọ ọrọ
Awọn obinrin maa n feti silẹ gbọrọ ju awọn ọkunrin lọ tori wọn maa n ni suuru.
Bakan naa ni awọn obinrin tun maa n jẹ ki ẹni to ba n sọrọ ṣetan ki wọn to sọrọ le nnkan ti ẹni naa ba n sọ, eyi tawọn ọkunrin maa n saba ṣe.
Abuda yii lo maa n jẹ kawọn obinrin gbọ nnkan ti ẹni to n sọrọ n sọ daadaa, eyi si maa n jẹ ki wọn loye ju awọn ọkunrin lọ.
Iṣẹ iwadii kan ni ile ẹkọ giga fasiti Maryland l'Amẹrika sọ pe awọn obinrin maa n gbọrọ daadaa ju ọkunrin lọ.
Iwadii naa ṣalaye pe awọn obinrin maa n ranti kulẹ kulẹ ọrọ ju awọn ọkunrin lọ.
Iṣẹ iwadii naa tun sọ pe apa mejeeji ọpọlọ lawọn obinrin maa n lo nigba tawọn ọkunrin maa n lo apa osi ọpọlọ wọn nikan lati gbọrọ.
9. Wiwa ojutuu si iṣoro
Iwadii ti fi han pe awọn obinrin lẹbun ki wọn maa wa ojutuu si iṣoro ju awọn ọkunrin lọ.
Awọn obinrin ni abuda lati ronu jinlẹ lori iṣoro ju awọn ọkunrin lọ.
Ile ẹkọ giga fasiti ilu Michigan fi idi rẹ mulẹ pe awọn obinrin lẹbun wiwa ọna abayọ si iṣoro ju awọn ọkunrin lọ.
Eyi tumo si wi pe awọn obinrin lẹbun lati gbe igbesẹ to le ṣe ileeṣẹ lanfaani ju awọn ọkunrin lọ.
10. Didari eeyan
Ọpọ afijọ lo wa laarin awọn obinrin atawọn ọkunrin nibi iṣẹ, amọ, awọn obinrin maa n laanu loju ju ọkunrin lọ,
Eyi si lo maa n fun wọn lanfaani lati wa ọna abayọ si iṣoro ju awọn ọkunrin lọ.
Awọn obinrin ni abuda lati gbe oriṣiiriṣii igbesẹ eyi si ṣe pataki fun idari.
Bakan naa lawọn obinrin tun mọ eeyan ba sọrọ ju ọkunrin lọ, eyi yoo si ṣe iranwọ fun wọn lati paṣẹ fawọn eeyan,
Awọn abuda yii lo jẹ kawọn obinrin lẹbun idari, idi si niyii ti ọpọ ileeṣẹ ṣe n fun awọn obinrin ni ipo adari.















