Ohun tó yé kí o mọ̀ nípa ìjìyà tuntun tí ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo kéde fún ìjínigbé

Oríṣun àwòrán, fairplanet
Ijọba ipinlẹ Ondo ti kede pe niṣe ni oun yoo maa yẹ igi fun ẹnikẹni to ba jẹbi ẹsun ijinigbe nipinlẹ naa lati akoko yii lọ.
Adajọ ipinlẹ ọhun to tun jẹ kọmiṣọna fun eto idajọ, Kayode Ajulo (SAN), lo sọ bẹẹ nibi ipade aawọn akoroyin kan lẹyin ipade igbimọ ijọba to waye niluu Akure.
Ajulo fi kun pe ijọba yoo tun wo ile awọn ti awọn ajinigbe naa ba n lo lati ṣọṣẹ tabi eyii ti wọn n gbe lẹyin ti wọn ba ti kọkọ yanju igbesẹ naa tan nile ẹjọ.
O fi kun pe ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo yoo ṣe atungbeyẹwo ofin to tako ijinigbe ni ipnlẹ ọhun, eyii to ni ki wọn maa yẹ igi fun ajinigbe.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, ijọba tun n kọminu lori bi awọn ọmọ ẹlegbẹ okunkun ṣe n ṣoṣẹ nipinlẹ Ondo lẹnu ọjọ mẹta yii, ijọba yoo si ṣe gbogbo ohun to yẹ ni ikapa rẹ lati ri daju pe akitiyan awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun di ohun igbagbe nibẹ.
O ni "gomina ipinlẹ Ondo jẹ ẹnikan to fẹran lati maa tẹle ofin pupọ, a ko ni ṣe bi wọn ṣe n ṣe lawọn ipinlẹ mii lai kọkọ tẹle ilana ofin.
"A ni lati mọ pe awọn olokowo n bọ nipinlẹ Ondo, a si gbọdọ ṣe ojuṣe wa lati ri daju pe awọn ati owo wọn wa labe abo to peye."
Awọn ipinlẹ to ti kede idajọ iku fun awọn ajinigbe nipinlẹ wọn
Edo: Ipinlẹ Edo ni ipinlẹ akọkọ ti yoo kede idajọ iku fun awọn ajinigbe ninu ọdun yii. Inu oṣu kẹrin ọdun 2025 ni gomina Monday Okpebholo kede pe niṣe ji wọn yoo maa yẹgi fun awọn ajinigbe ti ọwọ ba tẹ ni ipinlẹ naa.
Nasarawa: Lọdun 2020 ni ijọba Nasara kede pe ṣe ni awọn yoo maa yẹ igi fun ẹnikẹni ti iwadii ba fidi rẹ mulẹ pe wọn ji eeyan gbe. Gomina Abdullahi Sule sọ lodun naa pe ko si aye fun ijinigbe mọ nipinlẹ oun.
Taraba: Lọdun 2019 ni Taraba ṣe ofin to kede ẹwọn gbere tabi idajọ fun awọn ajinigbe.
Rivers: Ni 2015 ni ijọba Rivers buwọlu ofin to lodi si ijinigbe tirẹ.
Oyo: Lọdun 2016, ijọba Oyo buwọlu ẹwọn gbere fun awọn ajinigbe amọ o fi kun pe idajọ iku ni ajinigbe yoo gba ti ẹni ti wọn jigbe ba ku si akata wọn.
Ipinlẹ Eko: Bii ti ipinlẹ Oyo, idajọ iku ni ajinigbe yoo gba ti ẹni ti wọn jigbe ba ku si akata wọn nigba ti ajinigbe ọhun yoo gba idajo ẹwọn gbere ti ẹni naa ko ba ku.
Awọn ipinlẹ mii to nifẹ si idajọ iku fun ajinigbe ni Imo, Abia, Enugu, Anambra, Bayelsa, Cross River, Delta, Kogi, Akwa Ibom ati Kebbi wa.
Amọ ṣa, bo tilẹ jẹ pe awọn idajọ wọnyin wa fun ajinigbe lawọn ipinlẹ wọnyii, ọpọ lo gbagbọ pe pupọ ajinigbe ni kii ri idajọ iku gba gẹgẹ bii ofin ṣe sọ.
Wayi o, igbagbọ wa pe ijọba awọn ipinlẹ naa yoo ji giri si ojuṣe wọn ni bayii ti ijinigbe ti di ohun to n waye lemọlemọ ni Naijiria, paapaa lagbegbe iwọ oorun ti irufẹ nnkan bẹẹ jẹ ajoji tẹlẹ.















