Awọn afurasí agbésùnmọ̀mí pa èèyàn mẹ́wàá ní Borno

Oríṣun àwòrán, @ZagazOlaMakama
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kano ti fidirẹ mulẹ pe, lootọ ni awọn afurasi agbesunmọmi kọlu ọja kan niluu Konduga, ipinlẹ Borno, ti wọn si pa eeyan mẹwaa.
Awọn iroyin kan ti a ko le fidirẹmulẹ sọ pe ogun eeyan lo ki, lara eyi ti awọn to n ṣe iranlọwọ fun awọn ologun to n gbogun ti igbesunmọmi, wa.
Alẹ ọjọ Ẹti, ogunjọ, oṣu Kẹfa, ni iroyin sọ pe obinrin kan to so ado oloro mọra, kọlu agọ ọlọpaa to wa ni Konduga, ilu kan ti ko jina si Maiduguri, tii ṣe olu-ilu fun ipinlẹ Borno.
Nigba to n sọrọ lori ikọlu naa, Igbakeji Aarẹ Naijiria, Kashim Shettima, bu ẹnu atẹ lu ikọlu ọhun, to si ke si awọn oṣiṣẹ alaabo lati gbe igbesẹ lori rẹ ni kiakia.

Oríṣun àwòrán, Boko Haram
Awọn aworan kan to wa lori ayelujara ṣafihan oku awọn eeyan ti wọn tẹ silẹ, lasiko ti wọn n ṣeto isinku wọn lọjọ Abamẹta.
Eyi n waye lẹyin ọjọ diẹ ti awọn afurasi daradaran kọlu awọn abule kan nipinlẹ Benue, ti wọn si pa eeyan to to igba niye.
Lati oṣu diẹ sẹyin ni ikọ agbesunmọmi Boko Haram, ti n kọlu ọpọ abule nipinlẹ Borno. Bi wọn ṣe n pa awọn ara abule naa, ni wọn n ji awọn eeyan miran gbe, ti wọn si n pa ọpọ lara.
Awọn ikọlu yii ti mu ki ọpọ sa fi ile wọn silẹ.
Fun ọpọlọpọ ọdun ni ikọ Boko Haram gbakoso awọn agbegbe kan nipinlẹ Borno, ti wọn si n ṣe ijọba nibẹ. Amọ ileeṣẹ ologun Naijiria pada gba awọn agbegbe naa, eyi to mu ki awọn araalu pada sile wọn.
Ṣugbọn ṣa, awọn ikọlu ọtun to n waye lasiko yii ti mu ki ẹru ma a ba awọn eeyan pe o tun ṣe e ṣe ki awọn tun di alainilelori.
Awọn ohun to n ṣẹlẹ yii lo mu ki ijọba ipinlẹ Borno kọwe beere fun ọpọlọpọ ọmọ ogun lọwọ ijọba apapọ.












