Kí ló n fa ìjà láàrin àwọn ọmọ Alao-Akala, débi i pé àwọ́n kan ní kí wọ́n hú òkú rẹ́?

Adebayo Alao-Akala

Oríṣun àwòrán, Other

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Lati ọjọ meloo kan sẹyin ni ọkanojọkan iroyin ati gbọyii-sọyii ti n jade lori itakun ayelujara nitori idile gomina tẹlẹri n'ipinlẹ Ọyọ, Oloogbe Ọtunba Adebayọ Alao-Akala.

Bi awọn kan ṣe n sọ wi pe aarin awọn ọmọ oloogbe ko gun , ni awọn ẹlomii n ṣe ariwisi wi pe ọrọ naa nii ṣe pẹlu awọn iyawo oloogbe.

BBC Yoruba ṣe iwadii lori ọrọ naa, awọn koko nnkan ti a ṣe awari re e.

Akọbi ọmọbinrin Akala sọ pe wọn ko pe oun sidi ogun

Oluwatoyin Alao-Aderinto to jẹ akọbi ọmọbinrin ti aỌtunba Adebayọ bi lo gbe ẹjọ lo si ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ lati pe fun ayẹwo ẹya ara ti a mọ si DNA, fun gbogbo awọn ọmọ Alao-Akala, ki wọn le fi idi awọn ojulowo ọmọ ọkọ mulẹ.

Bakan naa ni Oluwatoyin n beere fun aṣẹ ile ẹjọ lati wu oku baba wọn jade ki wọn le ni anfaani lati ṣe ayewo DNA naa.

Ninu ẹjọ ti arabinrin naa pe ni lo ti rọ ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ niluu Ibadan, lati ṣe ayẹwo DNA fun oun ati awọn ọbakan rẹ bii Ọlamijuwọnlọ Akala to jẹ ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin.

Bakan naa lo ni ki wọn ṣe ayẹwo naa fun Olamide, Adebukola, Olamipo, Tabitha ati Olamikunle.

Ọwọ ẹbẹ yii lo ra si ile ẹjọ naa nipasẹ agbẹjọro rẹ, Oladipo Olasope, SAN, ti wọn si ṣe akọsilẹ rẹ pẹlu nọmba yii: I/443/2024.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Iroyin fi idi rẹ mulẹ wi pe, lati igba ti Ọtunba Alao-Akala ti jade laye ni eefin awuyewuye lori bi awọn ọmọ oloogbe ṣe fẹ pin ogun baba wọn ti n ru soke diẹdiẹ, ki o to di pe Oluwatoyin gbe ọrọ naa lọ si ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ laipẹ yii.

Lara awọn nnkan to si ṣokunfa awuyewuye naa ni bi iyawo oloogbe, Kemi Alao-Akala ati Olamide Alabi to jẹ ọkan lara awọn ọmọ oloogbe ṣe gba lẹta iṣakoso kan lọwọ ẹka ijọba to n ri si amojutọ dukiya awọn oloogbe ninu oṣu Kẹwaa ọdun 2022 lai fi orukọ Oluwatoyin si i.

Ninu oṣu Kẹjọ ọdun 2023 ni agbẹjọro Oluwatoyin ti kọkọ fi ọrọ lede wi pe aisi orukọ akọbi ọmọbinrin Ọtunba Adebayọ Alao-Akala ninu akọsilẹ awọn ọmọ to lẹtọ si dukiya baba wọn jẹ igbesẹ to tapa sofin, ti o si le ta ẹrẹ si orukọ rere ti Alao-Akala fi silẹ.

Oluwatoyin Alao-Aderinto tun rawọ ẹbẹ sile ẹjọ wi pe wọn gbọdọ ṣe ayẹwo DNA ni ibudo ayẹwo ti ile ẹjọ naa ba fi ontẹ lu lati le fi idi otitọ mulẹ.

Alao-Aderinto rọ ile ẹjọ naa lati gba esi ayẹwo DNA ti wọn ba ṣe sinu apo iwe ti wọn lẹ pa ki wọn si fi ṣọwọ adajọ ti yoo gbe idajọ kalẹ nile ẹjọ.

Awọn ẹbi oloogbe Adebayo Alao-Akala re e nibi isinku rẹ lọdun 2022
Àkọlé àwòrán, Awọn ẹbi oloogbe Adebayo Alao-Akala re e nibi isinku rẹ lọdun 2022

Lara awọn dukiya to n da awuyewuye silẹ yii n bẹ niluu Ibadan, Eko, Abuja, orilẹede United Kingdom, America, to fi mọ ile itura nla kan lorilẹede Ghana.

Awọn oriṣiriṣi ọkọ, ọpọlọpọ apo asunwọn nile ifowopamọ to ni awọn Naira, Dollars ati Pounds Sterling naa ko gbẹyin.

Nnkan ti Oluwatoyin Alao-Aderinto fẹ ni ki awọn dukiya yii jẹ pinpin laarin awọn ọmọ ati alabṣiṣẹpọ baba wọn dipọ ọwọ awọn eeyan kereje ti o wa bayii.

Taa ni Adebayọ Alao-Akala?

Ọdun 1950 ni wọn bi Ọtunba Christopher Adebayo Alao-Akala ni ẹkun ariwa ijọba ibilẹ Ogbomoṣọ.

Alao-Akala lọ si ile ẹkọ ologun, 'Kamina Barracks Middle School, 5th Battalion of Infantry' ni Tamle lorilẹede Ghana.

O darapọ mọ ile ẹkọ nipa iṣẹ Ọlọpaa, 'Cadet Inspector of Police' ninu ọṣu kẹfa ọdun 1974, nile ẹkọ nipa iṣẹ Ọlọpaa to n bẹ ni Ikeja n'ipinlẹ Eko.

Lẹyin ọpọlọpọ ọdun lẹnu ṣẹ Ọlọpaa, Alao-Akala darapọ mọ eto oṣẹlu gẹgẹ bii ọkan lara ọmọ ẹgbẹ ti wọn pe ni 'New Dimension'.

O dije du ipo alaga ijọba ibilẹ Ariwa Ogbomọṣọ lbẹ asia ẹgbẹ APP l'ọdun 1998, o si wọle. O ṣe akoso ijọba ibilẹ yii laarin ọdun 1999 si 2002.

Alao-Akala ṣe igbakeji Gomina Rashidi Ladọja laarin ọdun 2003 si 2006. O ṣe adele Gomina ipinlẹ Ọyọ fun ọṣu mọkanla lẹyin ti awọn aṣofin yọ Rashidi Ladọja nipọ.

Alao Akala du ipo Gomina ipinlẹ Ọyọ lọdun 2007 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP, o si wọle gẹgẹ bii Gomina fun ọdun mẹrin.

O tun gbiyanju ipo Gomina labẹ asia ADP ninu eto idibo Gomina ipinlẹ Ọyọ lọdun 2019, ṣugbọn ko ja mọọ lọwọ, koto di pe o darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC ti o si yọwọ ninu idije du ipo Gomina.

Alao-Akala jade laye lọjọ kejile oṣu kinni ọdun 2022 lẹni ọdun mọkanlelaadọrin.