Àbọ̀ ìwádìí BBC lórí àwọn ẹgbẹ́ jàndùkú tó n ṣekú pa tọmọdé-tàgbà ní Cape Town

Aworan ọmọdekunrin ti wọn yinbọn pa loṣu mẹrin sẹyin ni Cape Flats

Oríṣun àwòrán, Africa family

Àkọlé àwòrán, Oṣu mẹrin sẹyin ni yinbọn pa Davin lagbegbe Cape Flats niluu Cape Town
    • Author, Nick Ericsson
    • Role, BBC Africa Eye
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Ibanujẹ dori agba kodo, ni ṣe ni baba ọmọdekunrin ti wọn yinbọn pa dubulẹ lori ibusun nibi to ti n na ika si iho ibọn lara ogiri ile rẹ.

Loṣu Keji ọdun 2025 ni ibọn ba Davin lẹyin tawọn janduku agbebọn fija pẹta.

Ọmọdekunrin Davin fara kaasa awọn janduku agbebọn to n ṣọṣẹ lagbegbe Cape Flats nibi tawọn eeyan dudu lorilẹede South Africa pọ si.

Ọpọ eeyan to n gbe agbegbe Cape Flats ni ko lowo lati gba ile ni Cape Town, eyi si ni ṣe pẹlu ijọba ẹlẹyamẹya ''apartheid'' to ti waye tẹlẹ ni South Africa.

''Iho ti ibọn gba wọle ree, nibi ti ọmọkunrin wa sun si ree.''

Ninu ibanujẹ nla ni ẹbi ọmọdekunrin yii wa nitori ẹgbọn rẹ obinrin Kelly Amber padanu ẹmi rẹ lọdun meji sẹyin lẹyin tawọn janduku kọju ija sira wọn.

Ọmọ ọdun mejila ni ọmọdebinrin naa wa nigba ti wọn pa a.

Ni bayii, abikẹyin obinrin lo ku fun Devon ati iyawo rẹ, Undean.

Undean sọ pe nigba ti ọmọ naa beere pe ẹgbọn oun n kọ, oun sọ fun un pe o ti wa lọdọ Jesu.

Aworan awọn ọmọde meji ti wọn n wo kamẹra
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Agbegbe Wesbank lawọn iṣẹlẹ ipaniyan yii ti waye, inu ibẹru-bojo lawọn olugbe Cape Flats naa wa bo tilẹ jẹ pe, ileeṣẹ ọlọpaa fi dawọn loju pe awọn yoo pese eto abo to peye fun wọn.

Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe iṣẹlẹ ipaniyan lati ọwọ awọn janduku agbebọn ti pọ si niluu Cape Town nibi ti Cape Flats wa.

Aarẹ Cyril Ramaphosa gbe igbimọ eleto abo kan dide lọdun 2018 lati gbogun ti awọn janduku to n ṣọṣẹ ọhun.

Koda, aarẹ South Africa tun ko awọn ologun lọ si agbegbe naa lọdun 2019, amọ, kaka ki ewe agbọn dẹ niṣe o n le koko si.

Gareth Newham to jẹ adari eto kan to n ri si idajọ ododo ati gbigbogun ti iwa ipa ni Johannesburg sọ pe iṣẹlẹ ipaniyan ni Cape Flats ni i ṣe pẹlu itan agbegbe naa.

''Awọn janduku agbebọn yii maa n gbilẹ lawọn agbegbe ti ko ba si idagbasoke nibẹ.

Awọn janduku yii maa n ṣe oriṣiiriṣii nnkan ti ijọba ko ṣe fawọn awujọ kan.

Wọn maa n fun ọpọ ẹbi lounjẹ, sanwo ina mọnamọna, koda, wọn tun maa n fawọn eeyan lowo ọkọ lọ sibi isinku.

Awọn janduku agbebọn yii tun maa n sanwo ile iwe awọn eeyan,'' Newham lo sọ bẹẹ.

Newham ni awọn janduku yii ti darapọ mawọn eeyan, idi niyii to fi nira fun awọn ọlọpaa lati ṣẹgun wọn.

O ni eyi tumọ si pe wọn le lo ile awọn eeyan ti kii ṣe ara wọn lati ko ogun oloro ati nnkan ija pamọ si.

Aworan Pasitọ Craven Engel to wọ aṣọ dudu pẹlu awo loju rẹ.
Àkọlé àwòrán, Pasitọ Craven Engel ṣetan lati ṣe ipade alaafia laarin awọn eeyan ni Cape Flats

Awọn eeyan kan n gbiyanju lati wa ojutuu si iṣoro awọn janduku agbebọn yii.

Pasitọ Craven Engel to n gbe ni Hanover Park ti ko jina si Wesbank nibi to ti n gbiyanju lati ri pe alaafia jọba ni Cape Flats.

Ohun kan gboogi to n ṣe ni lati ba awọn janduku yii sọrọ ki wọn le fopin si iwa ipa ati ipaniyan.

Pasitọ Engel ni ''ko si ọrọ aje gidi kan ni Hanover Park, oogun oloro ni iṣẹ to wọpọ nibẹ.''

Pasitọ Engel ni ipa ijọba ẹlẹyamẹya to ti waye sẹyin ni South Africa si n ṣakoba fawọn eeyan ni Cape Flats ati Hanover Park.

''Oogun oloro n pese iṣẹ fawọn eeyan, oun lo jẹ ki iṣẹlẹ idigunjale wa ati ija laarin awọn janduku agbebọn.

Oogun oloro yii lo wa nidi ọpọ iwa ipa ati ipaniyan to n ṣẹlẹ, ko din ni ida 70% awọn ọmọde ti oogun oloro ti di bara ku fun,'' Pasitọ Engel ṣalaye.

Aworan iwe iroyin pẹlu akọle to sọ pe ''wọn sẹku pa ọdaran.''
Àkọlé àwòrán, Iwe iroyin pẹlu akọle to sọ pe ''wọn sẹku pa ọdaran'' to wa lara ogiri ofiisi Pasitọ Engel.

Ọgbẹni Newman sọ pe ''apa ọlọpaa nikan ko kawọn janduku agbebọn yii, wọn le fọwọ ofin mawọn ọdaran yii wi pe wọn n gbe ibọn, wọn si pa eeyan.

Wọn maa lo sẹwọ n loootọ ṣugbọn awọn ọdọ wa nilẹ ti yoo rọpo wọn.''

Pasitọ Engel ni ''bawo ni ibọn ṣe n ba ọmọde lori nigba meje ati nigba mẹta lẹyin?

ti pe bawo ni aṣita ibọn ṣe n pa ọmọde?''

Pasitọ Engel n gbiyanju lati pẹtu si aawọ laarin ẹgbẹ awọn ọdaran meji nigba ti BBC Africa Eye ṣe abẹwo si i.

O pada lanfaani lati ba olori awọn ọdaran kan to wa lẹwọn sọrọ.

''Nnkan ti mo ba fẹ ko ṣẹlẹ si maa ṣẹlẹ, ṣe o ye yin pasitọ?

Nnkan ti mo fẹ sọ fun yin ni pe mo maa gbẹsan ti ẹnikeni ba ṣe ikọlu si mi.''

Olori awọn ọdaran naa sọrọ lori foonu pẹlu pasitọ Engel.

Pasitọ Engel ko kaarẹ lori igbiyanju rẹ lati ri pe alaafia jọba lawujọ naa.

O ni nnkan to buru nipa ọrọ naa ni pe awọn ọmọde ti n darapọ mawọn janduku yii.

Pasitọ Engel sọ pe awọn ọmọde ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹjọ si ọdun mẹẹdogun lọ lawọn ọdaran n kọ niṣẹ buruku naa.

O maa n ṣepade pọ pẹlu awọn tawọn ọdaran ba ti ṣe ikọlu si atawọn janduku to ba nidi iṣẹlẹ naa.

O tun maa n lo awọn ọdaran ti wọn ba ti ronui piwa pa lati bawọn ẹgbẹ ọdaran mii ti wọn ba n ja sọrọ.

Ọkan lara iru awọn eeyan bayii ni Ọgbẹni Glenn Hans jẹ, o n ṣe ipade pẹlu awọn ẹgbẹ ọdaran meji lati ri pe alaafia jọba laarin wọn.

Ọkan lara awọn ọdaran naa sọ pe ''bi a ba ṣe pe eeyan si ni a maa gbalẹ si.

Nitori naa, kii ṣe ojuṣe mi lati maa wa bi alaafia yoo ṣe jọba.''

Aworan ọkunrin to wa aṣọ pupa
Àkọlé àwòrán, Nando Johnston sọ pe oun n wa ọna lati fi ẹgbẹ awọn ọdaran silẹ

Fernando Johnson ti wọn n pe ni Mongrels n wa bi yoo ti fi ẹgbẹ awọn ọdaran silẹ pẹlu iranlọwọ Pasito Engel.

Johnson ni nnkan meji lo le ṣẹlẹ - ninu ki eeyan ku tabi ki o lọ si ẹwọn.

Idi niyii ti Johnson fi tọ Pasitọ Engel lọ lati le yipada.

Pasitọ Engel sọ fun un pe ''o lanfaani lati bẹrẹ igbe aye ọtun, wa ri iṣẹ mii ti o le maa mu owo wọle fun ọ.''

Awọn ti wọn sun mọ Johnson naa gbadura fun un bi o ti fẹ bẹrẹ igbe aye ọtun.

Angeline April to jẹ iya Johnson pẹlu omije dunnu si igbesẹ ti ọmọ rẹ fẹ gbe.

Mama rẹ ni janduku naa ni baba baba Johnson, eyi lo si jẹ kawọn ọmọ rẹ naa di ọdaran.

''Ko rọrun fun mi rara lati tọ ọmọkunrin mẹrin dagba, mo maa n rọ wọn lati jẹ ọmọ daadaa nitori mo nifẹ wọn,'' iya Johnson lo sọ bẹẹ.

Pasitọ Engel ni Johnson maa to bẹrẹ eto ayipada rẹ, o ni Johnson si n ri awọn ẹbi rẹ bayii atawọn ọmọ rẹ bayii.

Ko si ireti fawọn olugbe agbegbe Cape Flats niluu Cape Town.

Iṣẹlẹ ipaniyan to n waye nibẹ pọju fawọn olugbe agbegbe ọhun.

Awọn eeyan ti wọn wa nidi iṣẹlẹ ipaniyan yii ko ṣetan lati dẹkun iwa ibajẹ ọhun.

Ọgbẹnu Newham sọ pe awọn olugbe agbegbe naa gan an ko fọwọ sowọ pọ pẹlu awọn ọlọpaa.

Idi akọkọ ni pe ko si idaniloju fun wọn pe ọlọpaa yoo jẹ awọn ti wọn ba pe.

Bakan naa, wọn o mọ bo ya awọn ọlọpaa yoo huwa ibajẹ ti wọn ba pe wọn.

Pasitọ Engel sọ pe ''ko si ẹni to le wa gba wa lati ita tabi lati ilẹ okeere.

Ko si ẹni to le wa ojutuu si iṣoro to n koju wa ni Cape Flats.

Gẹgẹ bii ẹnikọọkan, a ni lati pinnu lati fawọn eeyan wa ni ireti tori eto iṣejọba ti ja wa kulẹ.''