Iran lérí láti gbẹ̀san lára Amẹrika, Israel ní òun ti kọlu pápákọ̀ òfurufú mẹ́fà ní Iran

Oríṣun àwòrán, EPA
Lẹyin ọjo kan ti orilẹede Amẹrika ju ado oloro si ibudo iko nnkan ija oloro si mẹta otọọtọ ni Iran, awọn ọgagun ni Iran ti sọ pe awọn ṣetan lati gbẹsan nnkan ti Amẹrika ṣe.
Ileeṣẹ iroyin Iran ṣafihan fidio kan ninu eyi ti Olori ologun Iran, Amir Hatami, ti n bawọn ọmogun orilẹede naa sọrọ ninu yara agbara.
Ninu fidio ọhun ni o ti sọ pe ko si igba ti Amẹrika ṣe kọlu si Iran ti Iran naa ko da a pada fun wọn.
Ọgagun Hatami ni nnkan tawọn si maa ṣe lori ado oloro ti Amẹrika ju si ibudo iko nnkan ija oloro Iran si niyii.
Ninu ọrọ tiẹ, Ọgagun Abdolrahim Mousavi, sọ pe Amẹrika ti ṣi ọna fun ileeṣẹ ọmogun Iran lati ṣe ikọlu si awọn ọmogun Amẹrika.
Ọgagun Mousavi ni orilẹede Iran ko ni gba laelae fun Amẹrika.
Israel ṣe ìkọlù sí pápákọ̀ òfurufú mẹ́fà ní Iran, wọn ba ọkọ̀ òfurufú mẹ́ẹ̀dógún jẹ́
Ileeṣẹ ọmogun orilẹede Israel ti sọ pe awọn ti ṣe ikọlu si papakọ ofurufu Iran mẹfa.
Ileeṣẹ ọmogun naa sọ pe baalu mẹẹdogun lawọn bajẹ, bakan naa si lawọn tun ba oju ọna baalu jẹ lawọn papakọ ofurufu naa.
Ajọ ologun IDF Israel sọ loju opo ayelujara rẹ pe awọn papakọ ofurufu tawọn ṣe ikọlu si wa lẹkun guusu, ila oorun ati aarin gbungbun Iran.
Ajọ IDF sọ pe ado oloro tawọn ju sawọn papakọ ofurufu naa ba baalu ijagun F-15 ati F-5 jẹ.
Bakan naa tun ni ajọ IDF sọ pe ado oloro naa tun ba baalu to n gba epo kan jẹ ati ẹlikopita ijagun AH-1 kan pẹlu.
Ajọ naa tun fidi rẹ mulẹ pe awọn ọmogun Israel tun ba awọn ajaalẹ kan jẹ lawọn papakọ ofurufu naa.
Ko si ẹni to le sọ igba ti ikọlu yii waye, ati pe Iran gan an ko tii sọrọ lori ikọlu ọhun.
Ayipada le ba ijọba orilẹede Iran

Aarẹ Donald Trump ti sọ pe ayipada le ba ijọba orilẹede Iran bi awọn to n ṣakoso orilẹede naa ko ba le gbe e de ibi giga.
Trump sọrọ yii lẹyin ọjo kan ti Amẹrika ju ado oloro si ibudo iko nnkan ogun oloro si Iran.
Aarẹ Amẹrika ni gbogbo ibudo iko nkan ija oloro si Iran lawọn ọmogun Amẹrika ti bajẹ pata pata.
Amọ, ajọ iṣọkan agbaye UN sọ pe awọn ko le sọ pato iru ipa ti ado oloro Amẹrika ni lori ibudo iko nnkan ija oloro si Iran.
Ni bayii, Amẹrika ti sọ fun China pe ko gbọdọ faye gba Iran lati ti oju ọna ọkọ oju omi ''Strait of Hormuz'' pa.















